Dìde kí o tan ìmọ́lẹ̀Àpẹrẹ

Ayọ̀ Tí Ó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
A lè máà ronú pé "ìmọ́lẹ̀ titan" túmọ̀ sí wípé kí a jẹ́kí àwọn ènìyàn ní ìrètí tàbí kí a dùnnú ni àkókò àjọyọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo gbà gbọ́ pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ni, mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ pé ìgbà tí nǹkan bá wà ní ipò tí ó lè ni ìmọ́lẹ̀ máa ń tàn yòò jùlọ. Gẹ́gẹ́ bí ìtànṣán oòrùn ṣe máa ń la àfọ́kù gíláàsì fèrèsé tí ó fọ́ tí ó sì ní àbàwọ́n kọjá, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe máa ń la àfọ́kù ayé wa ti o ṣókùnkùn kọjá, tí ó sì máà jẹ ki o tàn yòò fún gbogbo ayé láti rí.
Nígbà tí a bá tẹ̀ sì ìlànà Ọlọ́run ní àkókò òkùnkùn ayé wa a ó ró wá ní agbára, àti okun láti tan ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Ọ̀nà kan tí a lè fi súnmọ́ Ìmọ́lẹ̀ ayé ni pé kí á máà ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Bóyá o ti rí ara rẹ tí ó ń ronú pé: Bíbélì máà ń súni ni kíkà, èmi kò ni óye rẹ̀, àti Èmi kò ní àkókò fún un.Ṣùgbọ́n mo fẹ́ bi ọ́ ní ìbéèrè yìí: Ní tòótọ́, kí ló yẹ kí o mú ní òkúnkúndùn jù nínú ìgbésí ayé rẹ ju kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó "yè, tí ó sì ni agbára" lọ (Hébérù 4:12)? Èmi kò rò pé ó yẹ kí a tún máà se atótónu nípa èyí rárá: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máà ń yí ohun gbogbo padà.
Kò yẹ kí Bíbélì kíkà dà bí iṣẹ́ àṣekúdórógbó. Ibẹ̀ ni a ti máà ń rí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó ni agbára ó sì jẹ́ ọ̀nà kan ni ara ọ̀nà tí Ọlọ́run fi ń bá wa sọ̀rọ̀. Nítorí náà, kí nì ìdí tí a kò fi ní fẹ́ láti máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo, kí a sì jẹ́kí kí ó máa gbé wa dúró kó sì sọ wa di ọ̀tun? Ìdáhùn kan náà: ni Sátánì. Ohun tí ọ̀tá náà kò fẹ́ ni pé ká fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run síwájú nínú ìgbésí ayé wa. Nítorí náà, ó "ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù"(Pétérù kini 5:8), ó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti dá wa láàmú, láti purọ́ fún wa, kó sì mú kí a rò pé kò sí óhun tí ó burú nínú kí ènìyàn máà yan Bíbélì ni ààyò
Gẹ́gẹ́ bí gbogbo wa ṣe mọ̀ pé, fóònù wa lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ń dá wa láàmú jùlọ ní ìgbésí ayé wa! Ṣùgbọ́n ọ̀nà kan tí o lè gbà lo fóònù rẹ fún rere ni pé kí ó máa rán ẹ létí lóòrekóòre pé, "Ṣé o ti ka ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni áyé yìí lónìí?"
Bíbélì kíkà jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa ní gbogbo ọ̀nà fún ìgbésí ayé wa, nítorí náà, bí a bá béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ pé kí ó fún wa ní okun láti máà kà á ní ójoojúmọ́, a lè ní ìgboyà pé ó ń gbọ́ wa.
Olúwa, mo fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Rẹ kíkà jẹ́ ohun kan tí ó ń fún mi ní ìdùnnú, ohun kan tí ó ń mú mi súnmọ́ Ọ ní ójoojúmọ́. A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín pé ẹ ń bá wa sọ̀rọ̀ láti inú Bíbélì. Ran mi lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Ọ sì. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ènìyàn maá ń sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé, "Kó gbogbo àníyàn rẹ tọ Ọlọ́run." Ṣé o tilẹ̀ ròó rí pé: Báwo ni mo ṣe lè ṣe èyí? Ìdíbàjẹ́ inú ayé ka 'ni l'áyà. Bí ó sì ti lè wù ọ́ tó láti tan ìmọ́lẹ̀ Jésù, ìwọ yíó máa wo òyé bí èyí yíó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ìwọ alára ń tiraka láti rí ìmọ́lẹ̀ yìí fún ara rẹ. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Jésù nígbàtí ayé tiwa gan-an dàbí pé ó wà ní òkúnkùn.
More