Dìde kí o tan ìmọ́lẹ̀Àpẹrẹ

Bí A Ṣe Ń Sún Mọ́ Ọlọ́run
Àdúrà jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti súnmọ́ Ọlọ́run, bí a ṣe ń di ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tí ó ń tàn. Nínú Bíbélì ò sọ pé, "Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa; Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà". (Jòhánù kini 5:14-15). A lè kó gbogbo ìpalára wa, àníyàn wa, àti ìpòǹgbẹ́ wa lé Ọlọ́run lọ́wọ́.
Àdúrà gbígbà nípasẹ̀ ìwé Sáàmú jẹ ọ̀nà kan gbógí láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nígbàtí ó bá ń tiraka láti yí àwọn ìrònú rẹ sì àwọn ọ̀rọ̀. Púpọ̀ jùlọ́ nínú àwọn Sáàmú, gẹ́gẹ́ bí í Sáàmú 139, ní ó jẹ́ àdúrà tí àwọn míràn kọ̀. Mó rí wípé ohun tí ó ní ìtumọ̀ gidi ni làti ṣe irú ìkéde àti ìbéèrè kan náà tí ènìyàn bí í Dáfídì Ọba fi gbàdúrà sí Ọlọ́run. Níwọ̀n bí àwọn Sáàmú ṣe jẹ apá kan ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ní agbára nígbàtí a bá yàn láti fi wọ́n gbàdúrà, —tàbí èyíkéyìí ẹsẹ Bíbélì —lórí ayé wa. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i ní ọjọ́ tí ana, Bíbélì ṣì wà láàyè, ó ń ṣiṣẹ́, ó sì wá ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn Olúwa
Bí a ṣe ń súnmọ́ Ọlọ́run sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni a ó ṣe túbọ̀ máà gbé ara lé tó.Ìtàn Mósè ti ó wà nínú Bíbélì jẹ́ kí èyí rán wa létí. Nínú ìwé Ékísódù 3:1-12, Ọlọ́run fi ara han Mósè láti inú igbó tí ó ń jó. (Ṣe àkíyèsí wípé Ọlọ́run fi ara hàn fún Mósè bí íìmọ́lẹ̀!)Ó wá pe Mósè láti kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì -èyí jẹ iṣẹ́ ńlá kan láti ṣe. Ìdáhùn Mósè ni ìbéèrè pé, "Ta ni èmí? Ó seè ṣe pé ó lè ní irú ìdáhùn yẹn sí ìpè tí ó wà nígbèésí ayé rẹ: Ṣùgbọ́n, Olúwa, ta ni èmi?
Ìdáhùn tí Ọlọ́run fún Mósè ni pé: "Èmi yíò wà pẹ̀lú rẹ". Ọ̀rẹ́ mi, nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe, Olúwa wà pẹ̀lú rẹ. Ó ṣeé ṣe kí o máà ṣiyèméjì nípa ìpé rẹ. Ó ṣeé ṣe kó ni ìmọ̀lára pé ìwọ kò tó tan láti lọ di ìmọ́lẹ̀ fún Kristi. O tiẹ̀ lè máà fẹ́ ṣe é rárá. Ṣùgbọ́n Olúwa wípé Òun yíò wà pẹ̀lú rẹ. Ìyẹn jẹ ìlérí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. A kò pè ẹ̀yín nìkan láti ṣe èyíkéyìí nínú iṣẹ́ mímọ́ yìí, bí kò ṣe ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú Baba. Nígbàtí tí o bá súnmọ́ Olúwa, ìtànṣán rẹ̀ yíò mọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ wà.
Olúwa, mo wá síwájú Rẹ lónìí pẹ̀lú ọkàn tí ó ń lákáká láti sún mọ́ Ọ. Èmi kò lè nìkan ṣe eléyìí. Mo nílò agbára àti oore-ọ̀fẹ́ Rẹ. Dáàbò bò mí, tọ́ mi sọ́nà, kí ó sì kọ́ mi ní ohun púpọ̀ sí i nípa Ara rẹ. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ènìyàn maá ń sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé, "Kó gbogbo àníyàn rẹ tọ Ọlọ́run." Ṣé o tilẹ̀ ròó rí pé: Báwo ni mo ṣe lè ṣe èyí? Ìdíbàjẹ́ inú ayé ka 'ni l'áyà. Bí ó sì ti lè wù ọ́ tó láti tan ìmọ́lẹ̀ Jésù, ìwọ yíó máa wo òyé bí èyí yíó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ìwọ alára ń tiraka láti rí ìmọ́lẹ̀ yìí fún ara rẹ. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Jésù nígbàtí ayé tiwa gan-an dàbí pé ó wà ní òkúnkùn.
More