Dìde kí o tan ìmọ́lẹ̀Àpẹrẹ

Ìtú-Sílẹ
Àfẹ́sódì, hílàhílo, àìnídánilójú, àti àwọn àṣìṣe. Nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ìfẹ́ ọkàn wa láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn fún Kristi, ó rọrùn láti máa rò pé a kò kún ojú òṣùwọ̀n nítorí a ní àṣírí tí ó jinlẹ̀ tí ó sì ṣókùnkùn tí ó ń dí ọkàn àti èrò inú wa lọ́wọ́, tí ó si ń rán wa létí nígbà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa.
A máa ń gbìyànjú láti kó àwọn ìṣe òkùnkùn wọ̀nyí sínú àpótí níbi tí ẹnikẹ́ni kò ti ní rí wọn. A máa ń bẹ̀rù pé tí a bá mú wọn wá sínú ìmọ́lẹ̀, ìgbésí ayé wa yóò yí padà sí búburú. A máa ń ṣàníyàn nípa ohun táwọn ènìyàn máa rò nípa wa tí wọ́n bá "mọ̀." Ìdí ni pé ọ̀tá fẹ́ ká wà nínú ìdẹkùn ẹ̀ṣẹ̀ síbẹ̀. Ó fẹ́ ká gbà pé ohun tí áwọn ènìyàn rò nípa wa ṣe pàtàkì ju ohun tí Ọlọ́run sọ fún wa lọ.
Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ ohun tí ó lè mú kí o má lè máa tan ìmọ́lẹ̀ Kristi? Kò sí! Bó ti wù kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ burú tó, tàbí bó o ṣe rò pé o ti bà ọ́ jẹ́ tó, Ìfẹ́ tí Jésù ní sí ọ tóbi, ó sì jinlẹ̀ kódà nínú ìdààmú ọkàn rẹ, Ó fẹ́ lò ọ́ láti tan ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ fún sí orí àwọn míràn.
Mú ohun tí ó ń fi pa mọ́ wá sójú ìmọ́lẹ̀, kí sì jẹ́ kí Olúwa dá ọ nídè. Nítorí pé ohun yòówù tí ó ń kó ìtìjú bá ọ, kì í ṣe ẹrú fún ọ láti dá gbé.
Ọlọ́run yàn ọ́, Ó mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ńdá. Ó yàn ọ́, Ó mọ̀ pé o ni irobinujẹ ọkàn. Ó yàn ọ́, Ó mọ gbogbo nǹkan nípa rẹ. Kò sì sí ohunkóhun, àní ohunkóhun rárá, tí ó lè ṣe àtakò àrídájú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ àti pé Ó pè ọ láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Un.
Ọlọ́run ṣe ìlérí láti fún wa ní "ẹwà fún eérú" (Aísáyà 61:3). Ìṣe àtẹ̀yìnwá kò fi ọ́ sì ípò àìṣeélò níwájú Ọlọ́run. Pẹ̀lú Rẹ̀, àti nípasẹ̀ Rẹ̀, o lágbára láti tan ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀.
Olúwa, a dúpẹ́ fún oore-ọ̀fẹ́ Rẹ tí kò lópin. Mo bèèrè pé kí gbogbo irọ́ ọ̀tá jìnnà sí mi, lórúkọ Jésù. Mo bèèrè ìdáríjì fún àwọn ọ̀nà tí mo ti dẹ́ṣẹ̀ sí Ọ. Mo yìn Ọ nítorí pé Ìwọ ni olùràpadà mi. Mo dúpẹ́ pé O dáríjì mí, O mọ irú ẹni tí mo jẹ́, O sì nífẹ̀ẹ́ mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Ọ. Mú ọkàn mi dọ́gba pẹ̀lú tìrẹ. Gbin sínú ìfẹ́ ọkàn mi láti jẹ́ àwòrán Rẹ tó dára jù lọ tí mo lè jẹ́. Mú ohunkóhun tí ó ún dí mi lọ́wọ́ láti máa ṣojú Rẹ kúrò nínú ìgbésí ayé mi. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ènìyàn maá ń sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé, "Kó gbogbo àníyàn rẹ tọ Ọlọ́run." Ṣé o tilẹ̀ ròó rí pé: Báwo ni mo ṣe lè ṣe èyí? Ìdíbàjẹ́ inú ayé ka 'ni l'áyà. Bí ó sì ti lè wù ọ́ tó láti tan ìmọ́lẹ̀ Jésù, ìwọ yíó máa wo òyé bí èyí yíó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ìwọ alára ń tiraka láti rí ìmọ́lẹ̀ yìí fún ara rẹ. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Jésù nígbàtí ayé tiwa gan-an dàbí pé ó wà ní òkúnkùn.
More