Dìde kí o tan ìmọ́lẹ̀Àpẹrẹ

Ìmọ́lẹ̀ nínú Òkùnkùn
Mi ò lè sọ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n mo fẹ́ jẹ́ ẹni tí ń mú ìrètí wá fún àwọn ẹlòmíràn. Mo fẹ́ kún fún ayọ̀, kí n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn fún Jésù. Ṣùgbọ́n àwọn ojọ́ kan wà tí ó jẹ́ pé ó ṣòro láti rí ìmọ́lẹ̀ láàrin òkùnkùn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àyíká. Bí ó ti jẹ́ pé mo mọ̀ pé Ọlọ́run pè mí láti kó gbogbo ẹ̀rù, àníyàn, àti ìbéèrè mi lé Òun lóri, tí Ó sì ṣe ìlérí pé Òun yíó fún mi ní ìsinmi, mo ṣì ń bá òkùnkùn ọkàn àti ẹ̀mí mi já ìjàkadì.
Jòhánù 1:4–5 sọ èyí fún wa nípa Jésù: “Nínú Rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé. Ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkún, òkùnkùn náà kò sì borí Rẹ̀.” Ní ẹnu kan ṣá, Jésú ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ó lè dàbíi pé òkúnkùn bò wá m'ọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kò lè b'orí wa láí nítorípé ìmọ́lẹ̀ Jésú wà nínú wa, ó sì wà yí wa ká.
Gbogbo ohun tí kò dára tí ó jẹ́ ohun ibi tí ó lòdì tí ò ń rí lórí ẹ̀rọ alágbèká rẹ kò ní agbára lórí rẹ. Gbogbo ìṣelòdì tí ó lè yí ọ ká ní ibi iṣẹ́ kò lè dí ọ̀nà ètò Ọlọ́run fún ayé rẹ. Òkùnkùn tí ò ń rí bí o ṣe ń bá ọ̀nà rẹ lọ kò ní borí rẹ nítori agbára tí ó wà nínú orúkọ Jésù.
Ó ní bí òkùnkùn ṣe máa ń sọ fún wa pé a kò ní ibi lọ. Ó fẹ́ kí ó dàbí i pé òun ni ó ń darí wa, ṣùgbọ́n òtítọ́ ibẹ̀ ni pé kò rí bẹ́ẹ̀. A ní agbára láti yàn kí òkúnkùn darí wa tábí kí àwa gan-an darí ayé wa pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Ọ̀tá fẹ́ kí á gba irọ́ yìí gbọ́ pé kò lè sí ìmọ́lẹ̀ láàrín òkùnkùn. Sàtánì kò fẹ́ kí a ní ìrètí tí Jésù mú wá fún wa.
Ṣíṣe àwárí bí a ṣe lè jẹ́ ìmọ́lè Krístì ní ìgbésẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ìgbésẹ̀ tí a lè gbé ni wọ́n. Ibi tí ó yẹ kí o wà ní àkókò yìí gan-an ni o wà yẹn. Òun sì wà pẹ̀lú rẹ.
Olúwa, mo fẹ́ mọ̀ Ọ́ sí i. Mo fẹ́ ní òye ọkàn Rẹ fún mi, fún àwọn ẹlòmíràn, àti fún ayé yìí. Níbo nínú ayé mi ni O ti ń pè mí láti wá Ọ sí i? Ràn mí lọ́wọ́ láti kọ ojú ìjà sí ẹ̀tàn ọ̀tá tí ń fẹ́ láti fà mí kúrò lọ́dọ̀ Rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọ kí ìmọ́lẹ̀ Rẹ lè tàn jáde láti inú mi. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ènìyàn maá ń sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé, "Kó gbogbo àníyàn rẹ tọ Ọlọ́run." Ṣé o tilẹ̀ ròó rí pé: Báwo ni mo ṣe lè ṣe èyí? Ìdíbàjẹ́ inú ayé ka 'ni l'áyà. Bí ó sì ti lè wù ọ́ tó láti tan ìmọ́lẹ̀ Jésù, ìwọ yíó máa wo òyé bí èyí yíó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ìwọ alára ń tiraka láti rí ìmọ́lẹ̀ yìí fún ara rẹ. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Jésù nígbàtí ayé tiwa gan-an dàbí pé ó wà ní òkúnkùn.
More