Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Experiencing Friendship With God

Ọjọ́ 5 nínú 5

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Tí ó S'ọrí Ìwàálàyè Ọlọ́run

Ìgbésí ayé tí ó dá l'órí Ìwàálàyè Ọlọ́run kì í ṣe ìgbésí ayé tí kò ní láárí. Kì í ṣe ìgbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà òwúrọ̀ bá tẹ́ wa l'ọ́rùn ní ó máa ń dára jù lọ. Dípò ìyẹn, ó ń sún wa láti máa ṣe ohun tí ó ní kí a ṣe l'órí ilẹ̀ ayé.

Ìbárẹ̀ tí ó tọ́ pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ yóò yí ọkàn wa padà láti máa lù bíi ti Kristi. Òun ni ìfẹ́, mímọ̀-Ọ́n á mú kí a ní ìfẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn. Bí 1 Jòhánù 4:19-20 ti sọ, “ Àwa fẹ́ràn rẹ̀ nítorí òun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa. Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, “Èmi fẹ́ràn Ọlọ́run,” tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀, èké ni: nítorí ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ tí ó rí, báwo ni yóò tí ṣe lè fẹ́ràn Ọlọ́run tí òun kò rí?.”

Bí ìgbésí ayé Kristẹni tí à ń gbé kò bá dá l'órí Ìwàálàyè Ọlọ́run, ó máa di ẹni tí ó ń ro ti ara rẹ̀ nìkan. Iṣẹ́ tí Kristẹni tí ó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan ń ṣe ni láti gbé ìgbésí ayé tí ó dá l'órí ilẹ̀ ayé. Àmọ́, Jésù fún wa ní ìrètí tí ó dára ju ìyẹn lọ. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tí ó s'ọrí Ìwàálàyè Ọlọ́run ni láti máa gbádùn Ọlọ́run ní ìgbà tí ó sì ń mú àwọn ẹlòmíràn wá sí inú àjọṣe náà pẹ̀lú.

Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń gba iṣẹ́ mímọ́ láti ṣe èyí tí ó kọjá agbára wọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó máa ń kó ìdààmú bá'ni, kí ó ṣòro látí ṣe, tàbí kí ó tilẹ̀ jẹ́ ohun tí kò ṣeé ṣe.

L'ẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti gbé iṣẹ́ náà fún wa, Ọlọ́run yóò fún wa ní ẹ̀bùn ara rẹ̀. Kì í fi àkókò ṣ'òfò láti máa fi wá ṣe fọ́ńté, tàbí pé ó ń fi àwọn ẹ̀bùn tí á ní yangàn tàbí pé ó ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ó fi wá ní ọkàn balẹ̀ pé òun á jẹ́ ọ̀rẹ́ wa. Ìbárẹ́ tí à ń bá ara wa ṣe yìí máa ń fún wa ní okun láti ṣe iṣẹ́ tí á yàn fún wa.

Jésù yóò fẹ́ láti lo ìgbésí ayé rẹ tí ó dára láti bùkún òpópónà rẹ, àdúgbò rẹ, àní ayé pàápàá. Gbígbé ní Ìwàálàyè Ọlọ́run kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀nà tí ènìyàn lè gbà fi hàn pé òun ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Ó ń tú agbára ìràpadà Ọlọ́run jáde nípasẹ̀ rẹ àti sí àwọn ẹlòmíràn. Ó ní iṣẹ́ l'órí ilẹ̀ ayé yìí láti kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ kí wọ́n lè mọ̀-Ọ́n, a sì pè ọ́ láti bá A ṣe iṣẹ́ náà.

Ṣé o ti bẹ̀rẹ̀ sí í mọ irú iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní fún ọ? Báwo ni ó ṣe rí? Báwo ni jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ṣe jẹ́ apá kan l'ára rẹ̀?

A ní irètí pé ètò yìí ti fún ọ ní ìṣírí. Kọ́ ẹ́kọ́ sí i nípa Experiencing Friendship with God láti ọwọ́ Faith Eury Cho ní ibí.

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Experiencing Friendship With God

Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí https://www.faitheurycho.com/