Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ìkùnsínú nínú Aginjù
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fi ara hàn nínú àwọn ìyọnu tí ó kọlu Íjíbítì tí ó sì tú ìdè ìsìnrú wọn ká, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde kúrò ní Íjíbítì kò ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run bíi ti Mósè. Nítorí náà, ní ìgbà tí nǹkan nira fún wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kùn. Wọ́n sọ pé, “Ì bá sàn kí a wà ní Íjíbítì!” (wo Eksodu 14:11-12; 16:3; 17:3).
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dà bíi aláìlágbára àti aláìmoore, síbẹ̀ a lè mọ ohun tí ó fà á tí wọ́n fi kùn. Ní igbà tí ayé bá le, ẹ̀mí wa yóò sọ nǹkan bíi "Ọlọ́run, bí o kò bá gbà mí sílẹ̀ nínú èyí, èmi fúnra mi ni mo màá gbà ara mi sílẹ̀". Àkókò yìí gan-an ni a ti máa ń kọ etí ikún sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí a sì máa ń gbé ara lé òye ara wa. Ní ìgbà tí ìkùnsínú bá wá di ìgbésẹ̀, a yóò di ẹni tí kò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí á sì mú kí a di ẹni tí ó ń gbé ara lé àwọn ènìyàn àti àwọn nǹkan míràn.
Ó rọrùn láti ṣe ọ̀tẹ̀ ju pé kí a gbà pé Ọlọ́run wà, ó rọrùn láti máa bínú àti láti máa ṣe iyèméjì ju pé kí a yí ojú sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o lè ṣe òwò mímọ́ kan ní òní. O lè yí ìkùnsínú náà sí ìbádọ́ọ̀rẹ́.
Máa ṣe àṣàrò l'órí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí bío ṣe ń gbé ogun ti ìkùnsínú:
1.Ó wà pẹ̀lú rẹ. “Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ? Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.” (Sáàmù 139:7-8)
2.Ó mọ ohun tí ó ń ṣe. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ.” (Aisaya 55:9)
Kí o tó tún lo ìdajì wákàtí míràn láti máa ronú l'órí ìbínú tí ó wà nínú ọkàn rẹ, tàbí kí o máa ṣe àníyàn nípa ohun tí ó máa ti ẹ̀yìn rẹ̀ yọ, tàbí kí o máa fi àìronújinlẹ̀ lọ sí orí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kí o lè bọ́ l'ọ́wọ́ àwọn ìṣòro rẹ, gb'ìyànjú láti ka ẹsẹ Bíbélì méjì yìí kí o sì ronú l'órí àwọn òtítọ́ yìí fún ìgbà díẹ̀. Ṣíṣe àṣàrò l'órí òtítọ́ Ọlọ́run ń mú kí èrò inú rẹ, ara rẹ, àti ẹ̀mí rẹ wà ní ìṣọ̀kan, ó sì ń jẹ́ kí gbogbo ọkàn rẹ wà ní ọ̀dọ̀ Jésù ní kíkún.
Kí ni o ti ń kùn nípa rẹ̀ l'ẹ́nu àìpẹ́ yìí? Báwo ni fífi àfiyèsí sí wíwà ní iwájú Ọlọ́run ṣe yí èrò rẹ nípa àwọn ìṣòro wọ̀nyí padà?
Nípa Ìpèsè yìí

Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí https://www.faitheurycho.com/