Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Experiencing Friendship With God

Ọjọ́ 2 nínú 5

Àǹfààní Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ní Ẹ̀ẹ̀kan si i

A dá wa láti ṣiṣẹ́ láti inú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé wọn, a fún Ádámù àti Éfà ni iṣẹ́ kan láti ṣe. Ọlọ́run pa àṣẹ fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa rẹ̀, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀; kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun, àti lórí ẹyẹ ojú-ọ̀run, àti lórí ohun alààyè gbogbo tí ń rákò lórí ilẹ̀.” (Gẹ́nẹ́sísì 1:28). Èyí kì í ṣe iṣẹ́ kékeré fún ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé orí ìlẹ̀ ayé!

Síbẹ̀ Ádámù àti Éfà ní àǹfààní tààrà sí Ọlọ́run ní ọ̀nà kedere tí ó jẹ́ pé rírí Ọlọ́run tí Ó ń rìn ní àárín ọgbà ní ìmóooru ọjọ́ kò ṣe àjèjì sí wọn (Gẹ́nẹ́sísì 3:8). Àǹfààní tààrà sí Ọlọ́run yìí jẹ́ ibú tí Ádámù àti Éfà ti rí ìmísí àti okun láti mú kí ọgbà náà gbòòrò tí wọ́n sì ǹ d'àgbà sí í nínú ṣíṣe ìkáwọ́ rẹ̀.

Ó ba ẹni ní ọkàn jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ba àjọṣe pípé tí wọ́n ní pẹ̀lú Baba jẹ́. Láti ìgbà náa ni a ti ń gbé nínú ayé tí ó kùnà ní ibi tí ẹ̀dá ènìyàn ti ń gbìyànjú láti mú ọgbà wọn gbòòrò sí i— ṣùgbọ́n láì sí Ìwàláàyè Ọlọ́run.

A dúpẹ́ pé a kò ì tíì pàdánù àǹfààní tí a ní láti ṣe àwọn ohun ńláǹlà nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run pátápátá. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún l'ẹ́yìn ọgbà Édẹ́nì, Jésù tún gbé iṣẹ́ mìíràn lé àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀ l'ọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Ẹ lọ, ẹ máa kọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo, kí ẹ sì máa baptisí wọn ní orúkọ Baba, àti ní ti Ọmọ, àti ní ti Ẹ̀mí Mímọ́. Kí ẹ máa kọ́ wọn láti máa kíyèsí ohun gbogbo, ohunkóhun tí mo ti pa ní àṣẹ fún yin: ẹ sì kíyèsí i, Èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo, títí tí ó fi dé òpin ayé.” (Mátíù 28:19-20).

Ìpè mìíràn nìyìí láti bí sí i, àṣẹ mìíràn láti tan ìfẹ́ àti ògo Rẹ̀ ká'lẹ̀ l'órí ilẹ̀ ayé! Ó jẹ́ àǹfààní láti mú ọgbà náà gbòòrò ní ẹ̀ẹ̀kan si i, ṣùgbọ́n ní báyìí, pẹ̀lú àjọṣe pẹ̀lú Rẹ̀ tí kò lè kùnà nítorí àìlera àti àṣìṣe wa.

Ó fún wa ní ìdánilójú kan ṣoṣo tí ó ṣe pàtàkì: Òun yíò wà pẹ̀lú wa.

Ó fún wa ní Ìwàlàáyè Rẹ̀.

Ìgbà wo ni o ti rí Ìwàlàáyè Ọlọ́run pẹ̀lú rẹ? Ipa wo ni ó ní ní orí rẹ?

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Experiencing Friendship With God

Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí https://www.faitheurycho.com/