Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Aginjù Ọkàn
Láti àkókò yìí títí dé ọrùn, àwọn ìrìkèridò ayé máa gbé iná wo ojú àwọn ìdí tí o fi ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. O máa lulẹ̀, ní ìgbà míràn àwọn ènìyàn ni ó máa já ọ kulẹ̀. Àwọn ètò tí o ṣe lè máa yọ'rí sí rere. Àwọn ilẹ̀kùn lè tì, láì sí ìrètí ṣíṣí mọ́. Ǹkan lè má ṣe ẹnu rere fún ọ, àwọn ẹlòmíràn sì lè má yí padà láéláé. O lè wà ní àkókò mo-dúró-de-Olúwa, tàbí ní àkókò tí ó nira gidi. Bí èyí bá jẹ́ ìpín rẹ fún ọjọ́ pípẹ́, ó ṣeé ṣe kí ǹkan da ojú rú fún ọ, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí ó ti mẹ́he.
Èyí ni aginjù ọkàn.
Fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde kúrò ní Íjíbítì, aginjù Sínáì kì í ṣe ibi ìrìn ìgbafẹ́ pẹ̀lú àwọn ewébẹ̀ tí ó jẹ́ ojú ní gbèsè, tàbí pẹ̀lú ìran tí a lè yà fi ṣ'ọwọ́ sí Instagram. Rárá o, ṣe ni aginjù yí rí bíi ilẹ̀ ẹ̀gbin tí ó lè gba ẹ̀mí ẹni. Ó jẹ́ ilẹ̀ tí kò ṣeé gbé pẹ̀lú oru tí ń ba ẹni lẹ́rù àti ilẹ̀ aṣálẹ̀. Yóò ṣòro láti ní ìlépa níbẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò nira láti ní ìwúrí àti èrè ìdí fún ayéìgbé.
Aginjù ọkàn tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ kò fi ǹkankan yàtọ̀. Nínú rẹ̀, pẹ̀lú ìkárísọ ni o máa fi rin ìrìn àjò rẹ. Ní igbà tí o bá bá ara rẹ ní ipò arìnrìn-àjò, àwọn ènìyàn kéréje ni ìrìn àjò ayé rẹ máa yé. Ìnira máa wá mọ́ ọ l'ára ju ìtẹ̀síwájú lọ, àti ìpòrúru ọkàn ju àfojúsùn lọ.
Àwọn kàn sọ wípé ìnira a máa fún ni ní agbára síi, àmọ́ èyí jẹ́ àrọwà lásán fún ènìyàn tí ipá rẹ̀ ti pin ní ibi tí ó ti ń rìn kiri. O lè jẹ́ ènìyàn tí ó ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, àmọ́ nínú aginjù o lè ko ojú ìbẹ̀rù ńlá. Èyí tí ó tún wá burú níbẹ̀ ni pé o lè má mọ pàtó àkókò tí yóò dáwọ́ dúró.
Arìnrìn-àjò Àyànfẹ́, tí ète àti èrèdí aginjù tí ó jà jù kò bá jẹ́ láti sọ ọ́ di ènìyàn tí ó dára síi tàbí láti mú ọ dé ibì kan ńkọ́? Ní òtítọ́ ni ìkọlà-àyà lè jẹ́ ọ̀kan l'ára àwọn àmúyẹ líla ìgbà aṣálẹ̀ kọjá, ìrora inú ìrìn-àjò náà kì í ṣe ọ̀nà ọ̀dájú láti rí ǹkan gbé ṣe tàbí gbà. Dípò èyí, èrè idí aginjù ni láti mọ Ìwàláàyè Ọlọ́run —àti láti ní ìbárẹ́ tí ó jinlẹ̀, tí ó jẹ́ ojúlówó, àti èyí tí ó rinlẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ ni èrè náà.
Ìwe Ẹ́kísódù sọ wípé, “Olúwa ma bá Mósè sọ̀rọ̀ l'ójúkojú, bí ènìyàn ti ń bá ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀” (33:11). Báwo ni yóò ti rí láti ní ìmọ̀lára wípé Ọlọ́run jẹ́ Ọ̀rẹ́ rẹ?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí https://www.faitheurycho.com/