Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ọ̀rẹ́ dípò Ìwà Pípé
Ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà ọ̀làwọ́, ìdúróṣinṣin, ìwà tútù àti ìkó-ara-ẹni-ní-ìjánu - àwọn èso Ẹ̀mí - ni gbogbo wa ń sa apá láti ní. A máa ń gb'ìyànjú láti mú kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ w'áyé nípasẹ̀ iṣẹ́ rere àti ìkó-ara-ẹni-ní-ìjánu wa. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Gálátíà 5:22-23 ṣe sọ, iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni láti mú èso yìí jáde, iṣẹ́ wa sì ni láti máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́. "Bí àwa bá wà láààyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí."(Galatia 5:25).
Ìyípadà ti ẹ̀mí ní òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ òdodo. Kì í ṣe pé nípa dída nǹkan ṣíṣe nǹkan. Ó ní í ṣe pẹ̀lú dídúró ti Ẹ̀mí Mímọ́.
Bí àjọṣe náà ṣe ń ní agbára sí i, ìwọ á túbọ̀ mọ Ọlọ́run ju àwọn bẹ́ẹ̀ni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ Rẹ̀. Ìwọ á bẹ̀rẹ̀ sí í ní òye ọkàn Rẹ̀. Ìwọ á mọ ohun tí ó ń kó ìdààmú ọkàn bá A àti ohun tí ó ń pa iná Rẹ̀. Ìwọ á bẹ̀rẹ̀ sí í ní òye ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan, ìwọ á sì máa rí ohun tí Ó ń ṣe. Ìfẹ́ rẹ láti yí padà kò so mọ́ èso ti ọ̀ranyàn tàbi ìtìjú bí kò ṣe ìfẹ́.
Kò dì ìgbà tí o bá ń sa ipá láti ní èrò tí ó tọ́ nípa ìwà pípé. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè pa ọkàn pọ̀ sí orí bí ìwọ á ṣe máa lo àkókò yìí pẹ̀lú Ọlọ́run. L'ẹ́yìn tí àkókò yìí bá ti kọjá, ìwọ á máa ro'nú ní'pa ohun tí ó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.
Ní ìgbà tí o bá ń ṣe ìpinnu, o máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀. Ní ìgbà tí gbogbo nǹkan bá ti sú ẹ, o máa ń ṣe ọ̀fọ̀ pẹ̀lú Olùrànlọ́wọ́ tí ó wà ní itòsí. Tí o bá kùnà, o máa ro'nú p'ìwà dà, o sì máa fi ọkàn tán Alárinà. Gbogbo ìgbà ni ó jẹ́ àǹfààní láti bá A ní ìbáṣepọ̀ nítorí pé Ó sún mọ́ itòsí, ó sì jẹ́ aláàánú.
O kò gbọ́dọ̀ ro'nú nípa gbogbo ohun tí o ní láti ṣe, kàkà bẹ́ẹ̀, fi ọkàn sí ohun tí ó ń mú kí o ṣe nísinsìnyí.. Kódà ní ìgbà tí iṣẹ́ kan bá dà bíi pé kò ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe, o máa mí, o sì máa bẹ Ọlọ́run pé kí Ó fún ọ ní okun tí ó kọjá agbára àbùdá. Àkójọpọ̀ àwọn àkókò wọ̀nyìí ni ó ń mú èso ti ẹ̀mí jáde! Bí o ṣe ń ṣe n lọ ní ẹsẹẹsẹ àti ní àkókò sí àkókò, yóò tún ìwà rẹ sẹ, yóò sì mọ ọkàn-àyà rẹ.
Àwọn ọ̀nà wo ni o ti n gbà wo ìgbésí ayé Kristẹni gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà láti mú ọ ṣe àṣeyọrí? Báwo ni o ṣe máa yí ohun gbogbo padà tí a bá rí ìyípadà ti ẹ̀mí gẹ́gẹ́ bíi àbájáde gbígbé nínú àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí https://www.faitheurycho.com/