Ìlépa Ọkàn Ọlọ́runÀpẹrẹ

ẸBỌ ÒTÍTỌ́
Bàbá tí ó bí bàbá mi máà ń pe èdè kan báyìí pé: "Tí ǹkan bá tọ́ láti ṣe ó yẹ kí a ṣe é ní ọ̀nà tí ó tọ́." A ó máa ko àwọn nǹkan ìṣeré túntún jọ, èmi yíò sì fẹ́ kọ́ ọ kíákíá láì ká ìtọ́ni bí wọ́n ṣe ń tò ó kí èmi lè fi ṣeré. Ní àwọn àkókò yẹn ni bàbá nlá mi yíò bo ojú wò mí tí yíò sì sọ pé "Tí ǹkan bá tọ́ láti ṣe ó yẹ kí a ṣe é ní ọ̀nà tí ó tọ́." Ní àkókò náà, èmi kò ní òye láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n bí ọdún ṣe ń gun orí ọdún ni mo tó ní òye pé ohun tí ó tọ̀nà pátápátá ni ó sọ. Ohunkóhun tí a bá rò wí pé ó tọ́ láti ṣe ní láti jẹ́ ohun tí a lè rúbọ àkókò, ìgbìyànjú, agbára, owó wá fún kí a sì da ojú kọ ọ́ láti ṣe ní ọ̀nà tí ó tọ́. Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó gbàgbọ́, a mọ̀ wí pé ọ̀kan nínú àwọn ìpè wa tí ó ga jù lọ ní láti jọsìn fún Ọlọ́run kí a sì kéde títóbi Rẹ̀. Fún wa, ìjọsìn jẹ́ gbòógì nínú àwọn nǹkan tí ó tọ̀nà láti ṣe. Nítorí náà báwo ni a ṣe lè ṣe é ní ọ̀nà tí ó tọ̀nà?
Ní Sámúẹ́lì kejì 24, a kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa ìjọsìn nínú ìgbésí ayé Ọba Dáfídì. Ìtàn náà bẹ̀rẹ̀ bí Dáfídì ṣe yàn láti ṣe àìgbọràn sì Ọlọ́run nípa kíkà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí Ọlọ́run dì-ídì fi òfin dè fún orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì. Ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì fa àwọn àtubọ̀tán fún orílẹ̀ èdè náà, Ọlọ́run sì sọ fún Dáfídì láti mú ọkàn nínú àwọn ìjìyà mẹta: ìyàn ọdún mẹta, kí ọ̀tá máà lépa rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, tàbí àjàkálẹ̀-àrùn ọjọ́ mẹta. Dáfídì yàn àjàkálẹ̀-àrùn ọjọ́ mẹ́ta, ìgbẹ̀hìn-gbẹ̀hìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin parun. Nípa ìsapá láti fi òpin sí àjàkálẹ̀ àrùn, Dáfídì lọ kọ́ pẹpẹ sì orí ilẹ̀ ìpakà ọkùnrin tí orúkọ rẹ ńjẹ́ Araunah. Araunah fún Ọba ní ilẹ́ ìpakà rẹ láti ló ní ọ̀fẹ́, ṣùgbọ́n Dáfídì fún-un ní èsì pé "Rárá, èmi yíò rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ. Èmi kì yíò fi èyí tí èmi kò náwó fún rú ẹbọ sísun sí Olúwa Ọlọ́run mi" (ẹsẹ 24). Nítorí náà Dáfídì ra ilẹ̀ ìpakà náà, ó kọ́ pẹpẹ náà, ó sì jọ́sìn ní iwájú Olúwa, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dá kúrò ní Ísírẹ́lì.
Nínú àyọkà yí, a kọ́ ẹ̀kọ́ òdodo tí ó ṣe kókó nípa ìjọsìn: ìjọsìn nílò ìrúbọ. Dáfídì kọ̀ láti ṣe ìrúbọ tí kò ná a ní ǹkankan sí Olúwa. Ó mọ̀ wí pé ìjọsìn òun ṣe pàtàkì, ó sì mọ̀ wí pé èyí tí ó dára jù lọ ni ó yẹ Ọlọ́run láti ọwọ́ òun. Gẹ́gẹ́ bí àwa tí ó gbàgbọ́, ìdíyelé tí a gbé sí orí ìjọsìn wa ni yíò ṣe okùnfà ohun tí a fẹ́ fi ṣe.
Nítorí náà, kíni eléyìí túmọ̀ sí fún wa? Bóyá eléyìí kàn jẹ́ ìrántí fún wa wí pé ohun tí ó dára jù lọ nínú ohun tí a ní ni ó yẹ kí á fún Ọlọ́run. Tàbí bóyá ṣe ni a ní ààyè láti ronú bí ó ṣe yẹ kí á bu ọlá fún Olúwa pẹ̀lú àkókò wá, owó wá, agbára wá, àti ìyìn wá pẹ̀lú. Ní ọ̀sẹ̀ yìí, ẹ jẹ́ kí a wá àwọn ọ̀nà láti rú ẹbọ ìjọsìn fún Olúwa, kí a fún-Un ní ohun tí ó dára jù lọ nínú àwọn ohun ìní wá.
BÉÈRÈ NÍ ỌWỌ́ ARA RẸ: Àwọn oríṣiríṣi ọ̀nà wo ni a lè gbà láti jọ́sìn fún Ọlọ́run? Báwo ni o ṣe lè ṣe ìrúbọ ìjọsìn ni ọ̀sẹ̀ yí?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ṣe àpèjúwe Ọba Dáfídì nínú Májẹ̀mú Tuntun gẹ́gẹ́ bíi ẹni bí ọkàn Ọlọ́run, tí ó túmọ̀ sí pé ọkàn rẹ ṣe déédé pẹ̀lú ti Ọlọ́run. Bí a ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ̀ nípa ìgbésí ayé Dáfídì, ìlépa wa fún àpilẹ̀kọ yìí ni láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun tí Dáfídì ṣe nínú 1 & 2 Samueli láti lè mú ọkàn wa dà bíi ti Ọlọ́run kí a sì jọ Dáfídì ní ìfarajìn àti ẹ̀mí tí ó fihàn ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.
More