Ìlépa Ọkàn Ọlọ́runÀpẹrẹ

After God's Own Heart

Ọjọ́ 3 nínú 5

ÌTẸ́LỌ́RÙN ÀTI SÙÚRÙ

Mo rántí ìgbà kan tí ó kú díẹ̀ kí ń parí ẹ̀kọ́ mi ní ilé ìwé gíga tí mo bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara mi pé“Kínni ìfẹ́ Ọlọ́run fún ayé mi?” pàápàá julọ iṣẹ́ wo ni kí n bẹ̀rẹ̀, irú ènìyàn wo ni màá fẹ́, àti pé ibo ni ó kàn tí ń ó máa gbé. Àwọn ìrònú àti ìbéèrè nípa ọjọ́ iwájú mi bẹ̀rẹ̀ sí mú àníyàn àti ìkáyàsókè wá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nnkan tí n kò mọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe tí mo lè ṣe ni mo ní láti máa ronú sí. Mo kan fẹ́ fí ìgbésí ayé mi jì fún Ọlọ́run, èmi kò kàn mọ nnkan tí Ọlọ́run fẹ́ kí n ṣe ní lọ́wọ́-lọ́wọ́ yi. Kíló dé tí Ọlọ́run kò kàn sọ fún mí kí ó sì tọ́ mi sọ́nà lórí ìgbésẹ̀ tí ó kàn tààrà? Àti pé kíló dé tí ó fi fi àyè gba àwọn ìdàrúdàpọ̀ àti ìṣòro nínú ayé mi?

Nígbà tí mò ń ka ìtàn Dáfídì, mo rí àrídájú pé bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbé ayé Dáfídì yàtọ̀ sí tèmi pátápátá, òtítọ́ kan wà tí ó so àwọn ìrírí wa pọ̀: ìfẹ́ Ọlọ́run fún ìgbé ayé wa kò lọ geere gé bí a ṣe fẹ́ kí ó rí. Nínú Sámúẹ́lì kini, Ọlọ́run yan Dáfídì pé yóò jẹ ọba ní Ísrẹ́lì ní ọjọ́ iwájú, ṣùgbọ́n ó tó ọdún mẹ́ẹ̀dógún kí Dáfídì tó gun orí ìtẹ́. Ní àsìkò yí, Dáfídì ṣe àṣeyọrí nínú gbogbo nnkan tí ó ń ṣe nítorí pé Ọlọ́run bùkún àwọn ìlàkàkà rẹ̀. Síbẹ̀, àṣeyọrí Dáfídì yí jẹ́ kí Ọba Sọ́ọ̀lù jowú rẹ, owú yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí jinlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ títí tí ó fi gbòòrò dé ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí lépa ẹ̀mí Dáfídì. Bí ó ṣe ń gbìyànjú láti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù, Dáfídì fi ara da ìpòrúru yíyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ísrẹ́lì ni ọjọ́ iwájú àti fífi gbogbo ìgbà màa sá fún ìdojúkọ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ó wà lórí ìtẹ́.

Nígbà tí mo kọ́kọ́ ka nípa èyí, ó jọ mí lojuy pé ọ̀nà làti di ọba fún Dáfídì nira tó yẹn. A ní ìmọ̀lára ìpè láti ṣe àwọn nnkan ńlá fún Olúwa, ṣùgbọ́n nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a máa ń dojú kọ àwọn ìdíwọ́ lójú ọ̀nà ìlàkàkà wa. A ní ìrètí láti gbé gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ̀, ṣùgbọ́n kò yé wa irú ìbámu wo ni ó ní pẹ̀lu ìnira, ìsòro, àti gbogbo àwọn nnkan míràn tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé wa.

Ní àwọn àkókò ìdàrúdàpọ̀ wọ̀nyí, ó ṣe pàtàkì láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run mọ ohun tí Ó ń ṣe. Ọ̀pọ̀ àwọn ìṣòro tí à ń bá pàdé jẹ́ àkókò láti fi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Rẹ̀ hàn. Ó lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tàbí ọdún kí ohun tí Ọlọ́run ń ṣe nínú ayé rẹ tó yé ọ. Dípò kí o máa ṣe àníyàn pé kí ló tún kàn, pa ọkàn rẹ pọ̀ sí wíwá ìtẹ́lọ́rùn nínú Ọlọ́run àti ibi tí Ó fi ọ́ sí lọ́wọ́lọ́wọ́. Pípa ọkàn pọ̀ sí ibi tí a wà lọ́wọ́lọ́wọ́ máa ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa nípa pé á jẹ́ kí á fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú gbígbé ìgbésí ayé ìhìnrere àti fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀nà tí ó dára. Lẹ́hìn náà, sán ọ̀nà ìwà ìgbẹ́kẹ̀lè tí ó ń fí sùúrú lépa ohun tí Ọlọ́run ń pè ọ́ láti ṣe nísinsìnyí àti ní ọjọ́ iwájú, kí o sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ó ní èètò kan fún ọ. Nígbà tí a bá ṣe èyí, yóò jẹ́ kí á lè fi ara da àwọn àkókò ìṣòro á sì tún tọ́ka wa sí ìrètí tí ó lọ́ọ̀rìn.

BÈÈRÈ LỌ́WỌ́ ARA RẸ: Nígbà tí ìṣòro bá dójú kọ mí, ṣé mo lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti ètò Rẹ̀ fún ayé mi nítòótọ́? Ṣé mò ń rí ìtẹ́lọ́rùn mi nínú Rẹ̀, àbí ṣé ni mò ń wá ayọ̀ àti ìdùnnù kiri nínú àwọn nnkan mìíràn?

ÌTẸ́LỌ́RÙN ÀTI SÙÚRÙ

Mo rántí ìgbà kan tí mò ń lọ sí òpin ẹ̀kọ́ mi ní ilé ìwé gíga tí mo bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara mi pé“Kínni ìfẹ́ Ọlọ́run fún ayé mi?” ní pàápàá iṣẹ́ wo ni kí n bẹ̀rẹ̀, irú ènìyàn wo ni màá fẹ́, àti pé ibo ni ó kàn tí ń ó máa gbé. Àwọn ìrònú àti ìbéèrè nípa ọjọ́ iwájú bẹ̀rẹ̀ sí mú àníyàn àti ìkáyàsókè wá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nnkan tí n kò mọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe tí mo lè ṣe ni mo ní láti máa ronú sí. Mo fẹ́ kí ìgbésí ayé mi wà fún Ọlọ́run nìkan. Mo fẹ́ kí ìgbésí ayé mi wà fún Ọlọ́run, n kò kàn mọ nnkan tí Ọlọ́run fẹ́ kí n ṣe ní báyìbáyi ni. Kíló dé tí Ọlọ́run kò kàn sọ ọ́ fún mí kí ó sì tọ́ mi tààrà? Àti pé kíló dé tí ó fi fi àyè gba àwọn ìlọ́lù àti ìṣòro nínú ayé wa?

Nígbà tí mò ń ka ìtàn Dáfídì, mo rí pé bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ayé Dáfídì yàtọ̀ sí tèmi, òtítọ́ kan wà tí ó so àwọn ìrírí wa pọ̀: ìfẹ́ Ọlọ́run fún ayé wa kìí ṣe tààrà bí kì bá ṣe wù wá kí ó rí. Ní 1 Samueli, Ọlọ́run yan Dáfídì pé yóò jẹ ọba ní Ísrẹ́lì ní ọjọ́ iwájú, ṣùgbọ́n ó tó ọdún mẹ́ẹ̀dógún kí Dáfídì tó gun orí ìtẹ́. Ní àsìkò yí, Dáfídì ṣe àṣeyọrí nínú gbogbo nnkan tí ó ń ṣe nítorí pé Ọlọ́run bùkún àwọn ìlàkàkà rẹ̀. Àmọ́, àṣeyọrí Dáfídì jẹ́ kí Ọba Sọ́ọ̀lù jowú, owú yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí jinlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ títí tí ó fi gbogò dé ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí lépa ẹ̀mí Dáfídì. Bí ó ṣe ń gbìyànjú láti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù, Dáfídì fi ara da ìpòrúru yíyàn án rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Ísrẹ́lì lọ́la àti fífi gbogbo ìgbà màa sá fún ìdojúkọ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ó wà lórí ìtẹ́.

Nígbà tí mo kọ́kọ́ ka èyí, ó yà mí lẹ́nu pé ọ̀nà àti di ọba fún Dáfídì nira bẹ́ẹ̀yẹn. A máa ń wò ó pé a pè wá láti ṣe àwọn nnkan ńlá fún Olúwa, ṣùgbọ́n bí a ṣe ń lọ, a máa ń dojú kọ àwọn ìdíwọ́ lójú ọ̀nà ìlàkàkà wa. A ní ìrètí láti gbé gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ̀, ṣùgbọ́n kò yé wa irú ìbámu wo ni ó ní pẹ̀lu ìnira, ìsòro, àti gbogbo àwọn nnkan míràn tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé wa.

Ní àwọn àkókò ìdàrúdàpọ̀ wọ̀nyí, ó ṣe pàtàkì láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run mọ ohun tí Ó ń ṣe. Ọ̀pọ̀ àwọn ìṣòro tí à ń bá pàdé jẹ́ àkókò láti fi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Rẹ̀ hàn. Ó lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tàbí ọdún kí ohun tí Ọlọ́run ń ṣe nínú ayé rẹ tó yé ọ. Dípò kí o máa ṣe àníyàn pé kí ló tún kàn, pa ọkàn rẹ pọ̀ sí wíwá ìtẹ́lọ́rùn nínú Ọlọ́run àti ibi tí Ó fi ọ́ sí lọ́wọ́lọ́wọ́. Pípa ọkàn pọ̀ sí ibi tí a wà lọ́wọ́lọ́wọ́ máa ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa nípa pé á jẹ́ kí á fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú gbígbé ìgbésí ayé ìhìnrere àti fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀nà tí ó dára. Lẹ́hìn náà, sán ọ̀nà ìwà ìgbẹ́kẹ̀lè tí ó ń fí sùúrú lépa ohun tí Ọlọ́run ń pè ọ́ láti ṣe nísinsìnyí àti ní ọjọ́ iwájú, kí o sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ó ní èètò kan. Nígbà tí a bá ṣe èyí, yóò jẹ́ kí á lè fi ara da àwọn àkókò ìṣòro á sì tún tọ́ka wa sí ìrètí tí ó lóòrìn.

BÈÈRÈ LỌ́WỌ́ ARAÀ RE: Nígbà tí ìṣòro bá dójú kọ mí, ṣé mo lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti ètò Rẹ̀ fún ayé mi nítòótọ́? Ṣé mò ń rí ìtẹ́lọ́rùn mi nínú Rẹ̀, àbí ṣé ni mò ń wá ayọ̀ àti ìdùnnù kiri nínú àwọn nnkan mìíràn?

Nípa Ìpèsè yìí

After God's Own Heart

A ṣe àpèjúwe Ọba Dáfídì nínú Májẹ̀mú Tuntun gẹ́gẹ́ bíi ẹni bí ọkàn Ọlọ́run, tí ó túmọ̀ sí pé ọkàn rẹ ṣe déédé pẹ̀lú ti Ọlọ́run. Bí a ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ̀ nípa ìgbésí ayé Dáfídì, ìlépa wa fún àpilẹ̀kọ yìí ni láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun tí Dáfídì ṣe nínú 1 & 2 Samueli láti lè mú ọkàn wa dà bíi ti Ọlọ́run kí a sì jọ Dáfídì ní ìfarajìn àti ẹ̀mí tí ó fihàn ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Grace Bible Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.grace-bible.org/college