Ìlépa Ọkàn Ọlọ́runÀpẹrẹ

After God's Own Heart

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ẹni Bí Ọkàn Òun Ọlọ́run

Nígbàtí o wà ní ọmọdé, ó ṣeéṣe kí o ti tẹ̀lé àwọn òbí rẹ lọ sí ọjà kí o sì rí wọn bí wọ́n ṣe ń ṣa èso, bí wọ́n ṣe ń mú èyí tí ó dára jù. Mo rántí bí bàbá mi ṣe gbé èso bàrà kan tí wọ́n sì gba lábàrá bí ì méló kan láti ṣe àyẹ̀wò rẹ. Bí wọ́n bá ti gbọ́ bí ó ti dún, wọ́n yóò sọ pé, “Ìyen dára gan-an ni!” Bí èmi náà sì ti ń dàgbà tí mo sì ń lọ sí ọjà fúnra mi, mo kọ̀ àṣà kí á máa gbá èso bàrà lábàrá kí ń tó ra. Síbẹ̀, mo ṣe àrídájú pé ká fi ojú òde wo nǹkan kò tó láti fi mọ bi èso bàrà náà tí dára tó ní inu. Bákannáà, láti fi ojú rí ènìyàn nìkan ni ìdúró kò lè ṣe àfihàn ìwà tí ó ní. Ọkàn wọn ni ó lè fí ìjìnlẹ̀ òtítọ́ àwọn ìwà tí ó pegedé hàn.

Ọlọ́run mọ̀ Ó sì ní òye bí ọkàn wa ṣé jìn to èyí sì jẹyọ nínú ìgbésí ayé Dáfídì, ọkùnrin tí “ẹni bí ọkàn Òun Ọlọ́run.” Ní àṣà òde òní, a máa ń ṣe ìdíyelé wá nípa ibi tí a ń gbé, ìrínisí wá, àti ohun tí a lè pèsè. Ní ìgbà míràn ẹ̀wẹ̀ ó rọrùn láti sọ nípa ènìyàn ní kété tí a bá fi ojú rí láì wá ọ̀nà láti mọ irú ẹni tí ó jẹ́ gan-an. Bí a ṣe rí kà nínú ìwé 1 Sámúẹ́lì 16, a rí bàbá Dáfídì tí í ṣe Jésè, ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ àgbà tí wọn ní agbára wá sí iwájú Samuel kí ó lè fi àmì òróró yàn ọkàn nínú wọ́n gẹ́gẹ́ bíi ọba ọjọ́ iwájú fún Ísráẹ́lì. Sámúẹ́lì pàápàá, tí ó jẹ́ àlùfáà Olúwa, kọ́kọ́ fi ojú ara yàn, nitori ó rò pé Ọlọ́run fẹ́ se àmì òróró sì orí ẹni tí ó ní agbára, tí ó sì rẹwà l'ọ́kùnrin. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe àtúnṣe fún Sámúẹ́lì, Ó rán létí pé Òun A máa yàn nípa wíwo ọkàn ènìyàn dípò ìrínisí. Ó mú Dáfídì gẹ́gẹ́ bíi ọba lọ́la.

A rán wa létí pé Ọlọ́run Kò yan àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Rẹ̀ nítorí ìrísí wọn, bí wọ́n ṣe ní agbára tó, iye ènìyàn tí wọ́n mọ̀, tàbí iye owó tí wọ́n ní. Ọlọ́run yàn wá nítorí ìfẹ́ tó ní sí wa àti bí Ó ṣe ń pòǹgbẹ́ pé kí àwa náà lè ní òye ọkàn Rẹ̀ síi. Ìfẹ́ Rẹ̀ sì wá fún wá ní ìgbàlà ọ̀fẹ́ tí a kò ṣiṣẹ́ fún ṣùgbọ́n tí ẹ̀jẹ̀ Krístì tí sanwó Rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máa ń fẹ́ wá yálà ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí ti ayé yìí nípa bí a ti ṣe ń gbé ìgbé ayé wa. Ọkàn, àkókò, àti òkun wá ń ṣe àfihàn ohun tí a fi tọkàn-tọkàn fẹ́ ní tòótọ́ tí a sì ń lépa.

Nítorínáà bí a ti ṣe ń ka ìtàn Dáfídì àti bí a ṣe ńkọ́ ẹ̀kọ́ bí Krístì ṣe fẹ́ wá to, a ó bẹ̀rẹ̀ síí ní òye bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé wa ní ọ̀nà tí yóò fi ìfẹ́ Krístì hàn sí àwọn míràn láì ní í ṣe pẹ̀lú bí wọ́n se rí, ṣùgbọ́n bíkòṣe pé a dá wọn ní àwòrán Ọlọ́run.

BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ARA RẸ: Ǹjẹ́ o rí àrísá pé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ bi o ti lè wù kí ó ri? Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni ó fẹ́ gbé láti jẹ ki ọkàn rẹ wà ní ìbámu sì ì láti lépa àfijọ pẹ̀lú ọkàn Ọlọ́run?

Lí Lépa Ọkàn Ọlọ́run

Nígbàtí o wà ní ọmọdé, ó ṣeéṣe kí o ti tẹ̀lé àwọn òbí rẹ lọ sí ọjà kí o sì rí wọn bí wọ́n ṣe ń ṣa èso, bí wọ́n ṣe ń mú èyí tí ó dára jù. Mo rántí bí bàbá mi ṣe gbé èso bàrà kan tí wọ́n sì gba lábàrá mélòó kan láti yẹ̀ẹ́wò. Bí wọ́n bá ti gbọ́ bí ó ti dún, wọ́n yóò sọ pé, “Eléyìí dára gan-an ni!” Bí èmi náà sì ti ń dàgbà tí mo sì ń lọ sí ọjà ara mi, mọ bẹ̀rẹ̀ sí ń tẹ̀ síwájú nínú àṣà kí á máa gbá èso bàrà lábàrá. Síbẹ̀, mọ ríi pé ìwò òde yìí kò tó láti fi mọ gbòógì quality èso bàrà tí ó dára. Bákannáà, ṣíṣe àtẹjúmọ́ òde ara ènìyàn fúnní àǹfààní kékeré láti mọ àrídájú àbùdá tàbí ìwà ẹnikẹ́ni. Ọkàn wọn ni ó fí ọ̀gbun òtítọ́ àwọn àbùdá tí ó mú wọn tayọ hàn.

Ọlọ́run mọ̀ Ó sì ní òye ọ̀gbun ọkàn wa, èyí hàn dájú nínú ìgbé ayé Dáfídì, ọkùnrin tí “ó wu Ọlọ́run ní ọkàn Rẹ̀.” Ní à ṣà òde òní, a máa ń ṣe ìdíyelé ènìyàn nípa ibi tí wọ́n ń gbé, ìrísí wọn, àti ohun tí wọ́n lè fún ni. Ní ìgbà míràn ó ma ń rọrùn láti sọ pàtó nípa ènìyàn ní gáún láì ṣe ẹ̀tọ́ láti mọ̀ wọ́n délé délé. Bí a ti ṣe kà nínú 1 Sámúẹ́lì 16, a rí bàbá Dáfídì tí ń ṣe Jésè, ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ àgbà alágbára wá sí iwájú Samuel kí ó lè baà fi àmì òróró yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bíi ọba ọjọ́ iwájú fún Ísráẹ́lì Sámúẹ́lì pàápàá, àlùfáà of Olúwa, kọ́kọ́ fi ojú lásán yàn, nitori ó rò pé Ọlọ́run fẹ́ da àmì òróró sórí eni tí ó ní agbára, tí ó sì rẹwà lọ́kùnrin. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bá Sámúẹ́lì wí, Ó rán létí pé Òun A máa yàn nípa wíwo ọkàn dípò ìrísí. Ó yàn Dáfídì gẹ́gẹ́ bíi ọba lọ́la.

A rán wa létí pé Ọlọ́run Kò yan àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin Rẹ̀ nítorí ìrísí wọn, bí wọ́n ṣe ní agbára tó, iye ènìyàn tí wọ́n mọ̀, tàbí iye owó tí wọ́n ń ń pa. Ọlọ́run yàn wá nítorí ìfẹ́ tó ní sí wa àti ìfàsí-ọkàn Rẹ̀ fún wa láti leè ní òye Rẹ̀ síi. Ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa ní ìgbàlà tí a kò ṣiṣẹ́ fún ṣùgbọ́n tí a fún wa ní ọ̀fẹ́ lẹ́yìn tí fi ẹ̀jẹ̀ Krístì sanwó Rẹ̀. Àmọ́ ní ọ̀pọ̀ ìgbà a máa ń fẹ́ ṣiṣẹ́ gba èrè yálà ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí ti ayé yìí nípa bí a ti ṣe ń gbé ìgbé ayé wa. Ọkàn wa, àkókò, àti okun ń ṣe àfihàn ohun tí a fẹ́ ní tòótọ́ tí a sì ń lépa.

Ǹjẹ́ bí a ti ń ka ìtàn of Dáfídì àti bí Krístì ṣe fẹ́ wa, a ó bẹ̀rẹ̀ síí ní òye bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé wa ní ọ̀nà tí yóò fi ìfẹ́ Krístì hàn sí àwọn míràn láì ní í ṣe pẹ̀lú bí wọ́n ti rí, ṣùgbọ́n bíkòṣe pé a dá wọn ní àwòrán Ọlọ́run.

BI ARA RẸ: Ǹjẹ́ o rí àrísá pé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ ohun yòówù kó dé? Kíni àwọn ìgbésẹ̀ tí ó gbé láti darí ọkàn kí ó lè ní àfijọ bíi ọkàn Ọlọ́run síi?

Nípa Ìpèsè yìí

After God's Own Heart

A ṣe àpèjúwe Ọba Dáfídì nínú Májẹ̀mú Tuntun gẹ́gẹ́ bíi ẹni bí ọkàn Ọlọ́run, tí ó túmọ̀ sí pé ọkàn rẹ ṣe déédé pẹ̀lú ti Ọlọ́run. Bí a ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ̀ nípa ìgbésí ayé Dáfídì, ìlépa wa fún àpilẹ̀kọ yìí ni láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun tí Dáfídì ṣe nínú 1 & 2 Samueli láti lè mú ọkàn wa dà bíi ti Ọlọ́run kí a sì jọ Dáfídì ní ìfarajìn àti ẹ̀mí tí ó fihàn ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Grace Bible Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.grace-bible.org/college