Ìlépa Ọkàn Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ẹ̀ṢẸ̀ ÀTI ÌRÒNÚPÌWÀDÀ
Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ńkọ́ bí wọ́n ti ń wa ọkọ̀, màmá mi sọ fún mi wípé kí n mú ìdí ọkọ̀ wọn jáde nínú ibi ìgbọ́kọ̀sí kí a tó jọ lọ sí àwọn ibi mélòó kan. Mo mú kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ náà mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀yìn wàá jáde, ṣùgbọ́n bí mo ti ń ṣe èyí, mo fi iwájú ọkọ̀ mama mi ha ògiri. Mo lérò wípé wọ́n ma bínú gan, fún ìdí èyí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ro onírúurú ọ̀nà tí mo lè gbà bó ohun tí mo ṣe mọ́lẹ̀. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, wípé lẹ́yìn tí mo mí kanlẹ̀, dípò bẹ́ẹ̀ mo pinnu láti sọ òtítọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an. Mo fi opẹ́ fún Ọlọ́run, wípé lójú ẹsẹ̀ ni mama mi dárí jì mí! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì nílò láti tún ọkọ̀ náà ṣe, àmọ́ gbogbo ẹ̀rù àti ìfòyà mi ni a mú kúrò lọ́gán tí mo pinu láti jẹ́wọ́ ohun tí mo ṣe.
Òtítọ́ kan tí a kò lè sá fún ní èyí: ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. Gbogbo wa, ní àkókò kan tàbí òmíràn, tí ṣe ǹkan tí kò yẹ kí a ṣe. Ó ṣeé ṣe, kí ẹnìkọ̀ọ́kan wa ti ní ìrírí àkókò ìpinnu tó tẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀. Pẹ̀lú ìfòyà ni a ma ń bèrè lọ́wọ́ ara wa “ṣé kí n jẹ́wọ́ ǹkan tí mo ṣe, àbí kí n gbìyànjú láti bò ó mọ́lẹ̀?” Ní ìsàlẹ̀ ikùn wa, gbogbo wa ló máa ń rètí wípé kí ẹ̀ṣẹ̀ wa wà ní ìpamọ́, ṣùgbọ́n kìí fi ìgbà kankan rí bẹ́ẹ̀.
Nínú Sámúẹ́lì Kejì 11-12, Dáfídì kọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ní ọ̀nà tó le. Ìyípo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ yí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu láti má lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. Dípò èyí, ó dúró sí Jerúsálẹ́mù níbi tí ó ti bá Bathsheba, aya ọmọ-ogun rẹ Ùráyà, ṣe àgbèrè. Nígbà tí a fi tó o létí wípé Bathseba ti lóyún, ó sá gbogbo ipá rẹ̀ láti bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀, ìgbẹ̀yìngbẹ́yín rẹ̀ ó ṣe okùnfà ikú Ùráyà lójú ogun. Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì lérò wípé òhun tí mú ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ, ṣùgbọ́n kò sí ǹkan tó bò lọdọ Ọlọ́run. Ọlọ́run wá rán Nátánì láti lọ kojú Dáfídì nípa ǹkan tó ṣẹlẹ̀, Dáfídì sì padà jẹ́wọ́. Bí ó ti jẹ wípé ìjìyà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ń dúró dè é, síbẹ̀ ó mọ rírí iṣẹ́ Ọlọ́run ó sì pinu láti yìn-ín àti láti jọ́sìn síi.
Ó rọrùn láti wo ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì àti láti rò ó lọ́kàn wa wípé “Èmi ò ṣáà ṣe ǹkan tó burú tó ìyẹn.” Ṣùgbọ́n a mọ̀ wípé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni ó lè mú ìparun wá, yálà ó kéré ni tàbí ó tóbi. A máa ń fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wa wà ní ìpa mọ́, ṣùgbọ́n kò sí ohunkóhun tí a ṣe, sọ, tàbí tí a gbà lérò tí ó bò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, pẹ̀lú pẹ̀lú bí Ó ti mọ gbogbo àṣìṣe tí a ti ṣe, Ọlọ́run ṣì ṣetán láti fi ojú fó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wá. Nígbà tí a bá dẹ́ṣẹ̀ àṣàyàn méjì ni a ní: a lè bò ó mọ́lẹ̀ kí ìtìjú àti ìdálẹ́bi rẹ̀ sì máa yọ wá lẹ́nu títí di ìgbà tí àṣírí náà bá tú, tàbí kí a jẹ́wọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run, ẹni tó mọ ohun gbogbo tí a ṣe tó sì ti dárí jì wá. Ta ló mọ irúfẹ́ ayọ̀ àti òmìnira tí gbogbo wa ìbá ní ìrírí rẹ̀, pàápàá lónìí, tí a bá yàn láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀.
BI ARA À Rẹ Léèrè: Kíni àwọn ǹkan tí o fi pamọ́ tí o jẹ ìpayà fún ọ? Báwo ni àjàgà rẹ yóò ti fúyẹ́ tó tí o bá sọ fún ẹnì kan? Ǹjẹ́ o ti gbàdúrà láti jẹ́wọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run? Tani ẹní náà nínú ìgbésí ayé rẹ tí o lè jẹ́wọ́ fún lóòrè-kóòrè tí o sì lè rìn pẹ̀lú nínú ìmọ́lẹ̀?
Ẹ̀ṢẸ̀ ÀTI ÌRÒNÚPÌWÀDÀ
Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ bí wọ́n ti ń wa ọkọ̀, màmá mi sọ fún mi wípé kí n mú ìdí ọkọ̀ wọn jáde nínú ibi ìgbọ́kọ̀sí kí a tó jọ lọ sí àwọn ibi mélòó kan. Mo mú kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ náà mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀yìn wàá jáde, àmọ́ bí mo ti ń ṣe èyí, mo fi iwájú ọkọ̀ mama mi ha ògiri. Mo lérò wípé wọ́n ma bínú gan, fún ìdí èyí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ro onírúurú ọ̀nà tí mo lè gbà bọ́ nínú wàhálà tí mo kó ara mi sí. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, wípé lẹ́yìn tí mo mí kanlẹ̀, mo pa ọkàn pọ̀ láti sọ òtítọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan. Ọpẹ́ sì ni fún Ọlọ́run, wípé lójú ẹsẹ̀ ni mama mi dárí jì mí! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì nílò láti tún ọkọ̀ náà ṣe, àmọ́ gbogbo ẹ̀rù àti ìfòyà mi ni a mú kúrò lọ́gán tí mo pinu láti jẹ́wọ́ ohun tí mo ṣe.
Òtítọ́ kan tí a kò lè sá fún ní èyí: ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. Gbogbo wa, ní àkókò kan tàbí òmíràn, tí ṣe ǹkan tí kò yẹ kí a ṣe. Ó ṣeé ṣe, kí ẹnìkàankan wa ti ní ìrírí àkókò ìpinnu tó tẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀. Pẹ̀lú ìfòyà ni a ma ń bèrè lọ́wọ́ ara wa “ṣé kí n jẹ́wọ́ ǹkan tí mo ṣe, àbí kí n gbìyànjú láti bò ó mọ́lẹ̀?” Ní ìsàlẹ̀ ikùn wa, gbogbo wa ló máa ń rètí wípé kí ẹ̀ṣẹ̀ wa wà ní ìpamọ́, àmọ́ kìí fi ìgbà kankan rí bẹ́ẹ̀.
Nínú Sámúẹ́lì Kejì 11-12, a kọ́ Dáfídì ní ẹ̀kọ́ yìí ní ọ̀nà tó le. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ọlọ́wọọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu láti má lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. Dípò èyí, ó dúró sí Jerúsálẹ́mù níbi tí ó ti bá Bathsheba, aya ọmọ-ogun rẹ Ùráyà, ṣe àgbèrè. Nígbà tí a fi tó o létí wípé Bathseba ti lóyún, ó sá gbogbo ipá rẹ̀ láti bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀, gbẹ̀yìngbẹ́yín rẹ̀ ó ṣokùnfà ikú Ùráyà lójú ogun. Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì lérò wípé òhun tí mú ẹ̀ṣẹ̀ náà jẹ, ṣùgbọ́n kò sí ǹkan tó bò fún Ọlọ́run. Ọlọ́run wá rán Nátánì láti lọ kojú Dáfídì nípa ǹkan tó ṣẹlẹ̀, Dáfídì sì padà jẹ́wọ́. Pẹ̀lú pẹ̀lú wípé ìjìyà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ń dúró dè é, síbẹ̀ ó mọ rírí iṣẹ́ Ọlọ́run ó sì pinu láti yìn-ín àti láti jọ́sìn síi.
Ó rọrùn láti wo ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì àti láti rò ó lọ́kàn wa wípé “Èmi ò ṣáà ṣe ǹkan tó burú tó ìyẹn.” Àmọ́ a mọ̀ wípé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni ó lè mú ìparun wá, ó kéré àbí ó tóbi. A máa ń fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wa wà ní ìpamọ́, àmọ́ kò sí ohunkóhun tí a ṣe, sọ, tàbí tí a gbà lérò tí ó bò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, pẹ̀lú pẹ̀lú bí Ó ti mọ gbogbo àṣìṣe tí a ti ṣe, Ọlọ́run ṣì ṣetán láti rọ òjò ìdáríjì lé wa lórí. Nígbà tí a bá dẹ́ṣẹ̀ àṣàyàn méjì ni a ní: a lè bò ó mọ́lẹ̀ kí ìtìjú àti ìdálẹ́bi rẹ̀ sì máa yọ wá lẹ́nu títí di ìgbà tí àṣírí náà bá tú, tàbí kí a jẹ́wọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run, ẹni tó mọ ohun gbogbo tí a ṣe tó sì ti dárí jì wá. Ta ló mọ irúfẹ́ ayọ̀ àti òmìnira tí gbogbo wa ma ní ìrírí rẹ̀, pàápàá lónìí, tí a bá yàn láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀.
BI ARA À RẸ: Kíni àwọn ǹkan tí o fi pamọ́ tí o ń rìn ọ́ mọ́lẹ̀? Báwo ni àjàgà rẹ yóò ti fúyẹ́ tó tí o bá sọ fún ẹnì kan? Ǹjẹ́ o ti gbàdúrà láti jẹ́wọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run? Tani ẹní náà nínú ìgbésí ayé rẹ tí o lè jẹ́wọ́ fún lóòrè-kóòrè tí o sì lè rìn pẹ̀lú nínú ìmọ́lẹ̀?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

A ṣe àpèjúwe Ọba Dáfídì nínú Májẹ̀mú Tuntun gẹ́gẹ́ bíi ẹni bí ọkàn Ọlọ́run, tí ó túmọ̀ sí pé ọkàn rẹ ṣe déédé pẹ̀lú ti Ọlọ́run. Bí a ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ̀ nípa ìgbésí ayé Dáfídì, ìlépa wa fún àpilẹ̀kọ yìí ni láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun tí Dáfídì ṣe nínú 1 & 2 Samueli láti lè mú ọkàn wa dà bíi ti Ọlọ́run kí a sì jọ Dáfídì ní ìfarajìn àti ẹ̀mí tí ó fihàn ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.
More