Ìlépa Ọkàn Ọlọ́runÀpẹrẹ

After God's Own Heart

Ọjọ́ 2 nínú 5

ÌGBÁRALÉ ÌGBÀGBOGBO

Mo rántí àkókò kan tí mo wà ní kílásì kékeré ní ilé-ìwé gíga, ìgbésí ayé jẹ́ àpọ́n ní ìgbà náà. Àwọn ìdánwò tí n bò, a ti n kọ àwọn ìwé sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó sì dà bíi wí pé gbogbo ènìyàn tí ó wà ní àyíká mi n ṣe jù mí lọ. Ìdààmú àti ìrèwèsì okàn bá mi, mi ò sì mọ ohun tí mi ò bá ṣe. Mo rántí pé mo bi ara mí pé, "Kí ni ìdí tí ìdààmú se bá mi?" àti pé "Kí ni ìdí tí ó fi rí bíi pé gbogbo nǹkan lòdì sí mi?"Jésù kò ṣe ìlérí ìgbésí ayé ìgbádùn àti ìdùnnú ní ìgbà gbogbo. Kódà, Ó fi yé wa pé a máa là ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro kọjá. Ní ìgbà náà, gégé bíi onígbàgbó, kí ni kí a ṣe ní ìgbà tí ilé ayé bá le?

Ìtàn Dáfídì àti Gòláyátì lè jẹ́ ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn tí ó gbajúmò jù lọ nínú Bíbélì. Dáfídì, ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́-àgùntàn, dojú kọ òmìrán kan tí ì bá ti pá. Síbèsíbè, lòdì sí gbogbo àwọn àìdógba, Dáfídì ṣégun Gòláyátì. Báwo ni ó ṣe ṣe é? Nítori ìgbékèlé rẹ nínu Olúwa. Dáfídì kéré kò sì ní apon tó Gòláyátì, ṣùgbọ́n ó gbẹ́kẹ̀ lé okun àti agbára Ọlọ́run láti wa gbeja re. Ó kéde ìdánilójú yìí fún Gòláyátì pé: “Èmi wá dojú ìjà kọ ọ́ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, Ẹni tí ìwọ kọ ojú sí. Ní ònìí, Olúwa yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́.” Lẹ́yìn náà, ó sinmi lé Ọlọ́run fún ìṣẹ́gun, ó gbé òkúta náà, ó sì sọ ọ́.

Rere ni Ọlórun wa. Ó máa ń lo àkókò búburú fún ohun rere. Rómù 11:36 “Nítorí làti òdò Rẹ̀ àti ní ipasè Rẹ̀ àti fún ara Rẹ̀ ni ohun gbogbo ti wá. Òun ni ó ni ògo títí láé.” Ọlórun nlo wàhálà wa, ìjàkadì wa fún ògo Rè àti ire tiwa. Ọlórun nlo àwọn àìlera wa Ó sì ṣo wón di agbára fún ìjọba Rè. Pàápàá nínu àwọn ipò tí ó burú jù àti tí ó nira jù lọ, Ọlórun ni olùpèsè àti olugbàlà wa, nítorí náà, ó yẹ kí a da ara lé agbára, ọgbón, àti àlááfià Rè.

Ní báyìí, kí ni èyí túmọ̀ sí fún wa? Póòlù kọ ní Filipi 4:6-7 pé kí a má ṣe àníyàn, kí a máa gba àdúrà ní gbogbo ìgbà, kí a sì fi àwọn ìronu wa lé Ọlórun lọ́wọ́, àlàáfia Rè yóò sì bò wá. Fi òní dá ara lé Olórun, lẹ́yìn náà ṣe ní kárakára iṣẹ́ tí Ó ti fi lélẹ̀ fún ọ.

BI ARA RE: Njé o ti n gbé ìgbésí ayé rẹ gégé bí àfihàn ìgbékèlé lóri Bàbá? Àwọn ọ̀nà wo ni ìwọ fi ń gbẹ́kẹ̀ lé agbára ara rẹ, dípò kí o fi í fún Olúwa?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

After God's Own Heart

A ṣe àpèjúwe Ọba Dáfídì nínú Májẹ̀mú Tuntun gẹ́gẹ́ bíi ẹni bí ọkàn Ọlọ́run, tí ó túmọ̀ sí pé ọkàn rẹ ṣe déédé pẹ̀lú ti Ọlọ́run. Bí a ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ̀ nípa ìgbésí ayé Dáfídì, ìlépa wa fún àpilẹ̀kọ yìí ni láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun tí Dáfídì ṣe nínú 1 & 2 Samueli láti lè mú ọkàn wa dà bíi ti Ọlọ́run kí a sì jọ Dáfídì ní ìfarajìn àti ẹ̀mí tí ó fihàn ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Grace Bible Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://www.grace-bible.org/college