Ọdún Àṣeyọrí Rẹ: Ìwúrí Ọjọ́ 5 Láti Bẹ̀rẹ̀ Ọdún Tuntun RẹÀpẹrẹ

ỌJỌ́ 5 – ÀÌMÚṢẸ ÀLÁ
Melek Sert wà nínú oyún oṣù karùn-ún ní ìgbà tí ó lọ sí ilé ìwòsàn nítorí ìrora tí ó ní agbára pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ tí óń dà ní ara rẹ̀. Ní ìgbà tí ó se, ẹ̀jẹ̀ tí ó ń dà dá wọ́n sì fií sílẹ̀ láti pada lọ sí ilé. Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ kejì òun àti ọkọ rẹ̀ Hasan padà lọ sí ilé ìwòsàn fún ìdí kan náà.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní wò ó tọ̀sán-tòru nítorí oyún náà lè bàjẹ́. Fún ìdí èyí, ó tètè bí ọmọ náà ṣíwájú àkókò rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn oníṣègùn sọ fún-un pé òkú ọmọ ni ó bí. Wọ́n fún-un ní ìwé ẹ̀rí fún òkú àti àpò ìsìnkú kékeré láti ilé ìwòsàn ìjọba Seyhan ní ìlú Turkey.
Hasan gbé ọmọ náà lọ sí ibojì tí ó wà ní àgbègbè Herekli láti sin ọmọ náà. Bí Hasan ṣe ń wa ọkọ̀ lọ sí ibojì, bẹ́ẹ̀ ní ó ń gbọ́ tí ọmọdé yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní ké. Ó dá ọkọ̀ dúró lọ́gán ó sì ṣí àpò. Ó bọ́ aṣọ ìlékè rẹ̀, ó fi bo ọmọ náà bíríkì, bẹ́ẹ̀ ni ó yí afẹ́fẹ́ gbígbóná inú ọkọ̀ náà sókè yanya.
Ọkọ̀-ayára-ilé-ìwòsàn wá wọ́n sì gbé ọmọdé jòjòló yìí lọ sí ibi tí à ń pè ní Adana City Research Hospital wọ́n ṣì ṣe ìtọ́jú rẹ̀ ní ibi tí wọ́n ti ńṣe ìtọ́jú rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Ọmọdé yìí wà ní ipò tí ó ṣe ẹlẹgẹ́ nítorí ìṣàkóso ẹ̀jẹ̀ nínú àgọ́ ara kò pé ojú ìwọ̀n. Ṣùgbọ́n Melek ríi wí pé ọmọ òun wà ní ààyè! Ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ ń gbọ̀n, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ ń sọ kúlúkúlú.
Ìpayà bá tọkọtaya yìí. Ọmọ wọn ọkùnrin tí a bí láì tọ́ ọjọ́ yè, kìí ṣe òkú. Wọ́n fò fẹ̀rẹ̀ láti aláìnírètí sí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀. Ọmọ wọn wà ní ààyè ní báyìí wọ́n ń gba àdúrà pé kí ó máa gbèrú síi: fún ìdàgbàsókè àti àlàáfíà tí ó pé ye.
Lúùkù 15:24 wípé, “Nitori ọmọ mi yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i. Nwọn si bẹ̀re si iṣe ariya.” Nínú ìtàn ọmọ oní ìnákúnná, kìí ṣe pé ó kú, ṣùgbọ́n ó jọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó ṣáko kúrò nílé. Ní ìgbà tí ó sì padà ayọ̀ bàbá rẹ̀ kún pé ọmọ òun ti ó ti “kú” ti padà wá ilé.
Hasan àti Melek rò pé ọmọkùnrin won kékeré ti kú, baba ọmọ oní ìnákúnná náà rò pé ọmọ òun ti kú ó sì ti sọnù pátápátá. A lè ní ìrírí àìmúṣẹ àlá, ó sì lè dà bí ìgbà tí ikú pani.
Ní ìgbà tí a bá ní ìrètí, gba àdúrà, tí a sì ṣiṣẹ́ kí àlá wa wá sí ìmúṣẹ tí kò sì rí bẹ́ẹ̀, ó dà bíi kíkú. A jọ̀wọ́ wa sílẹ̀ ní ìjayà, ìrora, àti ìpọ́njú. Gbogbo rẹ̀ dà bíi pé ó ti bọ́ sọnù. Ó wá dà bíi pé ayé wa kò ní ìtumọ̀ tàbí ibi tí ó da orí kọ.
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ní ọ̀nà tí Ó fi n mú ohun tí ó nù padà, jíjí padà sí ààyè ohun tí ó di òkú. A lè ti múra láti bo àlá yẹn mọ́lẹ̀ ní ìgbà tí Ọlọ́run ṣe tán láti fi ara Rẹ̀ hàn ní ọ̀nà tí kò ṣeé sẹ́. Ìran rẹ̀ kò kú – o wà láàyè digbí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún tuntun yìí lè jẹ́ ọdún àṣeyọrí rẹ. Àṣeyọrí rẹ wà ní òdì-keji ìdènà tí o d'ojú kọ ní ọdún tí ó kọjá. Èyí lè jẹ́ ọdún tí ó gbẹ̀hìn fún ọ láti ṣe àṣeyọrí tí ó nílò nínú igbesi ayé rẹ. Ètò náà yíò fún ọ ní ìwúrí tí o nílò láti ní ọdún tí ó dára jù lọ.
More