Ọdún Àṣeyọrí Rẹ: Ìwúrí Ọjọ́ 5 Láti Bẹ̀rẹ̀ Ọdún Tuntun RẹÀpẹrẹ

ỌJỌ́ Kejì – ÌṢẸ̀LẸ̀ TÍ KÒ WỌ́PỌ̀
Obìnrin kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lóyún nígbà tó ti lóyún tẹ́lẹ̀, ó sì bí ìbejì tí kò wọ́pọ̀, tí wọ́n bí láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta! Lọ́pọ̀ ìgbà, tí obìnrin bá lóyún, ara rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan bíi mélòó kan láti dènà oyún míì tó lè wáyé lẹ́ẹ̀kan náà, lára rẹ̀ ni pípèsè àwọn èròjà tó ń jẹ́ hormone láti dá oyún ṣíṣẹ́ dúró.
Àmọ́ láwọn ìgbà tí kò wọ́pọ̀, ó lè ṣẹlẹ̀ pé kí obìnrin kan tó lóyún ṣì tún máa da ẹyin inú rẹ̀, nígbàtí àtọ̀ bá sì tún dàpọ̀ mọ́ yóò wá di ọlẹ̀, nínú ilé ọmọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ yìí, tí ẹyin méjì tí wọ́n ti di ọlẹ̀ wọnú ilé ọmọ ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń pè ní superfetation (oyún-àrà-ọ̀tọ̀).
Nígbà tí oyún náà pé ọ̀sẹ̀ méjìlá, àwọn dókítà kẹ́fín ọmọ kejì tí ẹ̀rọ àwọn gbé jáde tí ó sì ní ìyàtọ̀ ìdàgbàsókẹ̀ ọlọ́sẹ̀ mẹ́ta sí ti àkọ́kọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé oyún-àrà-ọ̀tọ̀ báyìí kò wọ́pọ̀, àwọn dókítà kò lè kọ́kọ́ ṣàlàyé ìyàtọ̀ tí wọ́n rí nínú bí wọ́n ṣe tóbi sìara wọn. Àwọn dókítà wá sọ pé Superfetation (oyún-àrà-ọ̀tọ̀) ni.
Àwọn ọmọ náà, Nóà àti Rosalíì, ni a bí kí oṣù wọn tó pé. Nóà lo ọ̀sẹ̀ mẹ́ta nílé ìwòsàn, Rosalíì sì lo ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá. Àmọ́ àwọn ọmọ méjèèjì ti wá nílé báyìí, ara wọn sì le.
Ohun tó mú kí Superfetation (oyún-àrà-ọ̀tọ̀) jẹ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ ni pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ó fẹ́ ẹ̀ má ṣeéṣe ló gbọ́dọ̀ wáyé kí ó tó lè ṣeéṣe. Dída ẹyin, èyí tí àwọn ohun tó ń mú oyún dàgbà ni kété tí ó bá ti gbọ́ ìró máa dá dúró, ìdàpọ̀ ẹyin àti àtọ̀, èyí tí kò yẹ kó wáyé mọ́ tí ọlẹ̀ bá ti sọ nítorí oyún á ti ta bíi ikun láti fi dínà àtọ̀ kó máà ba kọjá lọ òpópónà ilé ọmọ, bákannáà dídúró ṣírímú nílé ọmọ, gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyè nílé ọmọ tó bẹ́ẹ̀ tí kò le sí ààyè fún ọlẹ̀ míràn mọ́, àti àwọn èròjà ara (hormones) tí kò yẹ kí ó jáde mọ́ tí oyún bá ti dé lẹ̀.
Àmọ́, gbogbo nǹkan wọ̀n yẹn ló ṣẹlẹ̀, Rebecca Roberts tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógójì padà lóyún, ó sì bí ìbejì.
Àwọn ìgbà kan wà tí Ọlọ́run máa ń darí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ètò láti ṣe ohun kan lọ́nà ìyanu. A lè máà rí ọ̀nà tí a lè gbà yanjú ọ̀ràn náà, a lè máa rò pé kò sí ọ̀nà àbáyọ, a sì lè fi ọwọ́ sọ àyà pé kò sí ọ̀nà àbáyọ.
Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run Á wá ṣe ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó sì ṣàjèjì. Ó ń mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé lọ́nà tó pé pérépéré, kí ohun tí kò ṣeé ṣe tẹ́lẹ̀ lè ṣeé ṣe. Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́.
Nígbà tí a bá fi ara wa sílẹ̀ fún Ọlọ́run, Ẹ̀mí yóò ṣiṣẹ́ nínú wa pẹ̀lú agbára a ó sì rí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Rẹ̀. Yóò darí ìgbésí ayé wa; a lè sinmi lábẹ́ ìdarí rẹ̀. A ó sì rí àwọn ohun àgbàyanu tí Yóò ṣe.
Jesu sọ ninu Jòhánù 14:26 "Ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Mímọ́ yóò wá, yóò sì ràn yín lọ́wọ́ nítorí pé Baba ni yóò rán Ẹ̀mí láti gba ipò mi." Nípasẹ̀ iṣẹ́ ti Ẹ̀mí, a ó ní ìrírí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò ràn wá lọ́wọ́ tí a ó sì lè lóye wọn bí èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún tuntun yìí lè jẹ́ ọdún àṣeyọrí rẹ. Àṣeyọrí rẹ wà ní òdì-keji ìdènà tí o d'ojú kọ ní ọdún tí ó kọjá. Èyí lè jẹ́ ọdún tí ó gbẹ̀hìn fún ọ láti ṣe àṣeyọrí tí ó nílò nínú igbesi ayé rẹ. Ètò náà yíò fún ọ ní ìwúrí tí o nílò láti ní ọdún tí ó dára jù lọ.
More