Ọdún Àṣeyọrí Rẹ: Ìwúrí Ọjọ́ 5 Láti Bẹ̀rẹ̀ Ọdún Tuntun RẹÀpẹrẹ

ỌJỌ́ KẸRIN – OJÚ ÀWO KEJÌ AYÉ
Ẹ̀rọ etí a gbóhun síta ni ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ń gbọ́ orin lóde òní láti inú ẹ̀rọ ìléwọ́ ìbánisọ̀rọ̀ wọn. Ohun gbogbo ti di ẹlẹ́rọ. Àwọn ohun tí ó wà tẹ́lẹ̀ ni kásẹ́ẹ̀tì ìgbohùn, ìgbohùn sí olórin mẹ́jọ, àti àwọn àwo orin. Àmọ́ àwo orin nìkan ni ó ọ̀nà kan láti fií gba ohùn sílẹ̀.
Bóyá o kò tilẹ̀ dàgbà débi tí o máa mọ̀ ìgbà tí a máa ń tẹ orin sórí àwọn àwo tí à ń pè ní 45. Lóde òní tí ohun gbogbo ti yàtọ̀, ó lè nira fún ọ láti gbàgbọ́ wípé ìgbà kan wà tí o lè ra àwọn àwo kékeré tí kò ní ju orin méjì lórí wọn. Orin kan máa wà ní apá A bẹ́ẹ̀ni ìkejì ma wà ní apá B.
Àwo orin ńlá kan ma ní orin mẹ́wàá tàbí méjìlá ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé àmọ́ nígbà tí wọ́n bá jẹ́ orin kan ṣoṣo wọ́n á tẹ̀ sórí àwo orin kékeré 45. Àwo orin 45 yìí àti àwọn èyí tí ó tóbi jù ú lọ ni a lè gbé sí orí èrọ ayíbírí tí wọ́n fi ń gbọ́ àwo, ṣùgbọ́n àwo 45 nílò ohun àmúbá-dọ́gba nítorí ihò àárín rẹ tóbi ju ti àwo ńlá lọ.
Orin ti ilé iṣẹ́ tó gbé orin náà jáde lérò wípé ó dùn jù ni wọn máa fi sí apá òdì A èyí tí wọ́n sì ma ń fi sí apá odi B ma ń jẹ́ àfikún lásán. Àmọ́ nígbà mìíràn àwọn èèyàn ma padà jẹ dòdò orin tó wà ní apá B.
Púpọ̀ nínú àwọn orin tó lókìkí jùlo nígbà yẹn jẹ́ orin tí a tẹ̀ sí "apá òdì B." "I Saw Her Standing There” látọwọ́ àwọn Beatles, “We Will Rock You” látọwọ́ Queen, “Hound Dog” látọwọ́ Elvis Presley, “Super Freak” látọwọ́ Rick James, àti “You Can’t Always Get What You Want” látọwọ́ àwọn Rolling Stones.
Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 16: 6-7 sọ fún wa, “Wọ́n sì la agbègbè Frigia já, àti Galatia, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Asia. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn.”
Ọlọ́run dá apá òdì A Pọ́ọ̀lù dúró- èyí tí ó lérò wípé ó máa ní àṣeyọrí ṣùgbọ́n ní apá òdì B ní Makedóníà ni ó ti padà bá ara rẹ̀. Àmọ́ èyí yí ìtàn àgbáyé padà. Ìhìn Rere Kristi sì tàn láti Éṣíà títí dé Yúróòpù. A fi ẹsẹ̀ Ìjọ náà múlẹ̀ ní Yúróòpù kí ó tó tàn jákèjádò àgbáyé.
Èyí ìbá má ṣẹlẹ̀ ká ní Pọ́ọ̀lù kò fi inú dídùn àti ọ̀yàyà gba àwọn ìyípadà tí a mú dé bá ètò rẹ̀. Kò bá ti bínú sí Ọlọ́run tàbí kí ó máa kárí sọ. Pọ́ọ̀lù ò bá ti lọ sí Yúróòpù pẹ̀lú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn kí ó sì padà fi ìlọ́wọ́wọ́ ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́ dípò èyí, ó fi ọ̀yàyà dá Ìjọ náà kalẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú.
O lè dà bíi Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn ìrírí tí kò sí nínú ètò rẹ tẹ́lẹ̀. Tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ǹkan wá yàtọ̀ gedegbe sí bí o ti pèrò rẹ̀. Àmọ́ Ọlọ́run lè lò ó láti mú àṣeyọrí tí ó ta yọ èyí tí o lérò àti ipa tí ó ga ju èyí tí o ti lá ní àlá lọ.
O kò lè mọ láéláé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ gbé ṣe ní apá òdì B tìrẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún tuntun yìí lè jẹ́ ọdún àṣeyọrí rẹ. Àṣeyọrí rẹ wà ní òdì-keji ìdènà tí o d'ojú kọ ní ọdún tí ó kọjá. Èyí lè jẹ́ ọdún tí ó gbẹ̀hìn fún ọ láti ṣe àṣeyọrí tí ó nílò nínú igbesi ayé rẹ. Ètò náà yíò fún ọ ní ìwúrí tí o nílò láti ní ọdún tí ó dára jù lọ.
More