Ọdún Àṣeyọrí Rẹ: Ìwúrí Ọjọ́ 5 Láti Bẹ̀rẹ̀ Ọdún Tuntun RẹÀpẹrẹ

Your Breakthrough Year: 5 Days of Inspiration to Kickstart Your New Year

Ọjọ́ 1 nínú 5

ỌJỌ́ KINNI– ÀLÙYỌ

Mo dá Ìjọ kan sílẹ̀ àti pé kìíṣe fún aláàárẹ̀ ọkàn. A lọ sí ìpínlẹ̀ tuntun, àwa ìdílé mẹ́wàá sì bẹ̀rẹ̀ Ìjọsìn ní ìsàlẹ̀ gbùngbùn ilé kan. A fi ọwọ́ kọ àpòòwé tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin tí a fi pe àwọn ènìyàn sí ìsìn àkọ́kọ́ níbẹ̀.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, mo jẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ ni àwọn Àgọ́ tí a tín kọ́ nípa Ìjọ gbíngbìn. Ọ̀rọ̀ ìmísí mi ni “Àwọn Péréte, Àwọn Agbéraga, Àwọn Olùgbìn Ìjo.” Wọ́n jẹ́ àwọn ológun pàtàkì ti àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run. Gbígba ilẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tá nnì kò rọrùn ṣùgbọ́n ó jẹ́ dandan fún Ìjọba Ọlọ́run kí ó tẹ̀síwájú.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpèníjà ló wà nínu dídá ìjọ sílẹ̀ ní ìgbà ìbèrẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run bá bùkún fún ọ pẹ̀lú ìdàgbàsókè àwọn ìpèníjà tuntun yóò wà. Ibi tí a ó lò fún ilé Ìjọsìn jẹ́ ìdojúkọ ńlá. A kò leè yalò títí láé ní agbègbè wa, àti pé nígbàtí ó di ìgbà kan àti ní ilé wá di dandan.

A kówó jọ láti ra ohun ìní a sì bẹ̀rẹ̀ láti wá ibi tí ó tọ́. Ìlànà tí a tẹ̀lé jẹ́ ọ̀kan tí ó pẹ́ àti eléyi tí ó mú ìrẹ̀wẹ̀sì wá. A wo àwọn ààyè oríṣiríṣi tí ó tó árùndínlọ́gbọ̀n a sì ríi pé kò sí ọ̀kan nínu wọn tí ó tọ́ fún ilé ìjọsìn wa.

A nílò àlùyọ - nǹkan ìyanu ní láti ṣẹlẹ̀ fún wa láti rí ilẹ̀-ìní pípé. Ní ti ọ̀rọ̀ ilé ìjọsìn, kìí ṣe nípa agbègbè, agbègbè, agbègbè ṣùgbọ́n bí ó se wà ní àrọ́wọ́tó, àrọ́wọ́tó, àrọ́wọ́tó sí.

Ní ọjọ́ kan ọkùnrin kan nínu ilé ìjọsìn tí ó jẹ́ abániṣe- ètò-ilé sọ fún mi pé òhun lè ṣètò ìpàdé pẹ̀lú Alákóso àwọn abánikọ́lé tí ó tóbi jùlọ ní agbègbè wa. Ní ibi ìpàdé náà, mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ilẹ̀-ìní kan tí wọ́n ní. Ó jẹ́ ibi tí mo ńpòùngbẹ fún ní gbogbo ìgbà.

Ilẹ̀ náà wà lóri ọ̀nà òpópónà oríta-mẹ́rin kan tí ó wà ní ìjáde láti inú ìpínlẹ̀ kan bọ́ sí òmíràn. Iwájú rẹ̀ ní ààyè ẹgbẹ̀rún kan ẹsẹ àti pé ó wà ní ibi agbègbè tí ó ní ìdàgbàsókè jùlọ. Fún ìyàlẹ́nu ńlá ó sọ fún mi pé wọn yóò ta ilẹ̀ náà fún ilé ìjọsìn wa. Àti pé ó sọ fún mi pé ọdúnrún àti èjìdínládọ́ta ẹgbẹ̀rún dọ́là ni wọ́n fẹ́ tàá ní ibi tí iye rẹ̀ ju mílíonù kan dọ́là lọ!

A lu àlùyọ àti pé ó yí ilé ìjọsìn wa padà láíláí. Ní ọdún àkọ́kọ́ lẹ́hìn tí a ti kọ́ ilé ìjọsìn náà tán, a fẹ́rẹ̀ lé ní ìlọ́po méjì ní ìwọ̀n. Króníkà kìńní orí kẹ́rìnlá ẹsẹ kọkànlá sọ fún wa pé, “Dáfídì sọ pé, ‘Ọlọ́run ti lò mí láti kọlu àwọn ọ̀tá mi bí ìkún omi.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní ‘Olúwa Là Lùyọ.’”

Ọlọ́run lè fún ìwọ náà ní àlùyọ. Nígbàtí ó bá ṣẹlẹ̀, yóò dàbí ìkún omi ọ̀pọ̀ ìbùkún àgbàyanu. O gbọ̀dọ́ wá Ọlọ́run pẹ̀lú ìtara láti gbàá... àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, yóò pẹ́ ju bí ati fẹ́ kó tètè ṣẹlẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ṣeé, àluyọ yóò dé àti pé ìgbésí ayé rẹ kìí yóò sì rí bákannáà mọ́.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Your Breakthrough Year: 5 Days of Inspiration to Kickstart Your New Year

Ọdún tuntun yìí lè jẹ́ ọdún àṣeyọrí rẹ. Àṣeyọrí rẹ wà ní òdì-keji ìdènà tí o d'ojú kọ ní ọdún tí ó kọjá. Èyí lè jẹ́ ọdún tí ó gbẹ̀hìn fún ọ láti ṣe àṣeyọrí tí ó nílò nínú igbesi ayé rẹ. Ètò náà yíò fún ọ ní ìwúrí tí o nílò láti ní ọdún tí ó dára jù lọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Fedd Agency fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.rickmcdaniel.com/thiisliving.html