Ọdún Àṣeyọrí Rẹ: Ìwúrí Ọjọ́ 5 Láti Bẹ̀rẹ̀ Ọdún Tuntun RẹÀpẹrẹ

ỌJỌ́ KẸTA - Ìtúsílẹ̀
Mo ní àǹfààní láti ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Fílípì àtijó ti Gíríìsì. Ibí yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti dá ìjọ Krìstẹ́nì àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní Yúróòpù. Ibẹ̀ náà sì ni ẹnìkan ti kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Krístì nílẹ̀ Yúróòpù. Orúkọ rẹ̀ ni Lìdíà, a sì gbà á là, ó sì ṣe batisí. Kódà, mo ní àǹfààní láti lọ síbi tí wọ́n ti batisí rẹ̀ nínú odò Gángítísì.
Ó kéré tán, Pọ́ọ̀lù ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Fílípì lẹ́ẹ̀mejì mìíràn. Láti ìlú Róòmù ni ó ti kọ ìwé Fílípì sí ìjọ yìí. Ìwé yìí ní àwọn kan lára àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì tó gbajúmọ̀ jù lọ nínú (1:6, 2:5-11, 3:12-14, 4:13). Ayọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní fún ìjọ tó wà ní Fílípì hàn kedere nínú lẹ́tà rẹ̀ níbití ó ti gbà wọ́n níyànjú láti gbé ìgbésí ayé Kristẹni tí ó jẹ́ aṣẹ́gun.
Fílípì náà ni wọ́n ti lu Pọ́ọ̀lù àti Sílà, tí wọ́n sì ti mú wọn. Mo rí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi wọ́n sí. Pọ́ọ̀lù ti lé ẹ̀mí ìwoṣẹ́ jáde lára ọmọbìnrin kan. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ rí i pé àwọn kò lè lò ó mọ́ láti fi rí owó, wọ́n fà wọ́n lọ síwájú àwọn alákòóso, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń dá wàhálà sílẹ̀.
Ní ọ̀gànjọ́ òru, Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin nígbà tí Ìṣe àwọn Aposteli 16:26 sọ pé, "Lójijì, ìmìtìtì ilẹ̀ ńlá kan wáyé, tí ó fi jẹ́ pé ìpìlẹ̀ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà mì: lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀kùn ṣí sílẹ̀, ìdè gbogbo ènìyàn sì tú." Ìmìtìtì ilẹ̀ kékeré kan ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè yẹn gan-an. Agbára Ọlọ́run ló dá wọn sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n!
Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀, ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fa idà rẹ̀ yọ láti pa ara rẹ̀ nítorí pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà lọ láì ní ìdíwọ́. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù dá lẹ́kun ẹ̀ṣọ́ náà sì bí Pọ́ọ̀lù pé, "Kí ni mo gbọdọ̀ ṣe kí a lè gbà mí là?" Pọ́ọ̀lù dáhùn, "Gba Jésù Olúwa gbọ́, ìwọ yóò sì rí ìgbàlà."
Agbára Ọlọ́run yii kan náà wà ní òní fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́. A ṣì ń gba àwọn ènìyàn tó wà lẹ́wọ̀n là síbẹ̀. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin ló ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n kí wọ́n lè di òjíṣẹ́.
Ọlọ́run ṣì ń dá àwọn èèyàn nídè kúrò lọ́wọ́ onírúurú ìfiniṣẹrú. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé oríṣiríṣi ohun tó ti di bárakú ni wọ́n ń lò. Ó lè jẹ́ ọtí tàbí oògùn olóró. Ó lè jẹ́ wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tàbí kéèyàn máa náwó kọjá bó ṣe yẹ. Ohun yòówù kó jẹ́, Ọlọ́run lè dá ẹ nídè. Mo mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn nípa ìgbà tí ẹnìkan bá gba ìgbàlà Ọlọ́run máa ń dá wọn nídè lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kúrò nínú ìdè wọn.
Agbára Ọlọ́run dájú. Ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn. Kódà bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún lo ti lò nínú ẹ̀wọ̀n, Ọlọ́run lè dá ọ sílẹ̀. Ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Pọ́ọ̀lù àti Sílà yóò ṣe fún ìwọ náà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún tuntun yìí lè jẹ́ ọdún àṣeyọrí rẹ. Àṣeyọrí rẹ wà ní òdì-keji ìdènà tí o d'ojú kọ ní ọdún tí ó kọjá. Èyí lè jẹ́ ọdún tí ó gbẹ̀hìn fún ọ láti ṣe àṣeyọrí tí ó nílò nínú igbesi ayé rẹ. Ètò náà yíò fún ọ ní ìwúrí tí o nílò láti ní ọdún tí ó dára jù lọ.
More