Ọdún Tuntun: Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tunÀpẹrẹ

New Year: A Fresh Start

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ìgbé Ayé Ìbáṣepọ̀ Ọ̀tun

Ọ̀kan nínú àwọn ohun tí ó ṣe gbòógì ní ilé ayé ni wípé a dá wa láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ní ìgbà tí Ọlọ́run sọ pé, "Kò dára kí ọkùnrin náà nìkan máa gbé," ni ìjìnlẹ̀ ìṣe-pàtàkì ìbáṣepọ̀ ọmọ ènìyàn ti fi ara han. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe àpèjúwe onígbàgbọ́ Krìstíẹ́nì gẹ́gẹ́ bíi "Ara Krístì." Ó sọ pé a so wá pọ̀ mọ́ ara wa, a sì gbé ara lé ara wa ní àìlè dá wà láìsí ẹnìkejì. A dá wa láti wà ní àwùjọ kí á sì máa ṣe ojúṣe wa bí ó ti yẹ ní kíkún ní ìgbà tí ìbáṣepọ̀ wa bá gùn régé. Nítorí pé ìbáṣepọ̀ jẹ́ gbòǹgbò ìgbé áyé wa, bí ìbáṣepọ̀ yìí bá se ni òòrìn tó ní yíó ṣe kó ipa pàtàkì lóríi bí ayé wa yíó ṣe ní ìtumọ̀ tó

Bí àjọṣepọ̀ wa bá dára, ayé wa yíó dára, láì bìkítà nípa àwọn ìṣòro tí ó bá wá ní ipò tí a bá ara wa ní ìgbàkúùgbà. Èyí ni agbára àti ìṣe-pàtàkì ìbáṣepọ̀ tí ó dán mọ́rán nínú ayé wa.

Ohun tí ó báni lọ́kàn jẹ́ níbẹ̀ ni wípé, ìkóríta yîí ni a ti sáábà maá ń tiraka ni ìgbà pupọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ni ó ní àjọṣepọ̀ ti ó ti kúnà ní ìgbésí ayé wa. Èyí ń fa ìrora bá wà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn èrò-ára tí ó jẹ́ mọ́ àwọn àjọṣepọ̀ yí máa ń kóbá gbogbo igun ayé wa. A máa ṣòro láti gbádùn àwọn ohun tí ó dára tí ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọnènìyàn bá ti bàjẹ́. Àwọn akitiyan wa láti "ṣe àtúnṣe" àwọn àjọṣepọ̀ tí ó ti dàrú yìí wáá di ohun tí à ń fi sí orí àtòjọ ìpinnu ọdún tuntun, lọ́dọọdún.

Àwọn ìbáṣepọ̀ wa le yàtọ̀. A ní ìdánilójú ìbáṣepọ̀ ọ̀tun nítorí pé, láti ipasẹ̀ Krístì, a ní ọkàn tuntun. Nínú Jésù, a ní ìgbé ayé ọ̀tun, ìhùwàsí ọ̀tun, àti ọ̀nà tààrà ọ̀tun sí Ẹni náà tí Ó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìbáṣepọ̀ wa. A pè wá láti máa gbé nínú ìfẹ́ pẹ̀lú ara wa, Ọlọ́run sì ǹ fi oore-ọ̀fẹ́ àti agbára fún wa ní ìgbà gbogbo láti ṣe ohun tí Ó pè wá sí láti ṣe.

Jésù sọ pé òfin tí ó ga jùlọ ni kí á "fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo àyà, ọ̀kan, inú, àti agbára wa." Ó tún tẹ̀síwájú láti sọ pé òmíràn tún dàbíi rẹ̀: "Kí á fẹ́ ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bíi ara wa." Jésù so àwọn ǹǹkan méjì yí pọ tí ó nííṣe pẹ̀lú Ìbáṣepọ̀; kí a sì fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ohun gbogbo tí a jẹ́ kí á sì fẹ́ ọmọnìkejì pèlú ìfẹ́ tí ó fí wọ́n àti àìní wọ́n sí ipò kan náà pèlú ti wa. Àsopọ̀ yí ṣe kókó nítorí nínú ṣíse èkínní ní a ó ti mú èkejì ṣẹ.

Gẹ́gẹ́ bíi Krìstíẹ́nì tí ó fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ohun gbogbo tí a jẹ́, a wà ní ipò láti gbé nínú ìfẹ́ àti itèwogbá tí a ti rí gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì wípé, "A fẹ́ẹ, nítorí Óun kọ́kọ́ fẹ́ wa." A leè fẹ́ àwọn ẹlọ̀míràn ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀ láì sí Krístì.

Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé Òun fún wọn ní àṣẹ tuntun pé ẹ "Fẹ́ ara yín gẹ́gẹ́ bí Mo ṣe fẹ́ yín." Nítorí a ti ní ìrírí ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìfẹ́, tí kò lópin láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a ní ibú ìfẹ́ tí a ó fi fún àwọn míràn pẹ̀lú. A lè fi ìfẹ́ lọ àwọn tí ó ṣòro láti fẹ́ràn, kódà bí wọ́n bá jẹ́ ọ̀tá wa, tàbí àwọn tí kò ní ìfẹ́ rárá.

Kò sí nínú ìṣe wa, ṣùgbọ́n nínú Krístì, a leè ṣe alábàápín ìfẹ́ tí a ti rí gbà. Èyí yíó mú kí ìyípadà dé bá àwọn àjọṣepọ̀ wa, kódà bí ẹnìkejì bá kọ ìfẹ́ tí à ń fihàn sí i. Ní ìgbà tí a bá dáríjì, tí a fì ìfẹ́ han, tí a sì wà ní àlàáfíà, àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn yíó ní ìyípadà, láì bìkítà ìhà tí wọ́n kọ sí wa. Fífi ìfẹ́ han fún ni yìí ni ìrètí ìlàjà tí ó dára jùlọ. Síbẹ̀, bóyá eléyìí ṣẹlẹ̀ tàbí kò ṣẹlẹ̀, a ó ní ìrírí òmìnira tí ó ń fún ni ní ìyè.

Jẹ́kí ọdún yìí jẹ́ ọdún tí ó dára jùlọ. Ọdún tí ó yẹ kí a rìn nínú ìfẹ́ nípa fifi ìfẹ́ hàn sí àwọn ènìyàn bíi èyí tí a rí gbà lọ́dọ̀ Jésù!

Tí o bá gbádùn kíka ẹ̀kọ́ kíkà yi, a ń pè ọ́ pé kí o kàn sì ILI kí o sì ṣe àwárí bí a ṣe ń dàgbà síi bíi ádarí kí o sì mú ìtànkalẹ̀ ìhìnrere yára ní kíá. Fún àlàyé síwájú síi, ṣe àbẹ̀wò síhttps://iliteam.org/connect.

Nípa Ìpèsè yìí

New Year: A Fresh Start

Ọdún tuntun jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Ó jẹ́ àkókò àtúntò, ìsọdọ̀tun àti àtúnṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Níní ọdún tí ó dára jùlọ bẹ̀rẹ̀ nípa mímọ̀ pé a ti sọ ọ́ di ọ̀tun nípasẹ̀ Jésù. Gbé ìgbé-ayé ọ̀tun nínú ọdún tuntun!

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ International Leadership Institute tí wọ́n pèsè ètò yí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://ILIteam.org/