Ọdún Tuntun: Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tunÀpẹrẹ

Gbígbé pẹ̀lú Ọkàn Túntún
Ọ̀kan nínú àwọn ìlọsíwájú ìṣègùn òyìnbó òde òní ni gbígbé ẹ̀yà-ara ẹnìkan fún ẹlòmíràn. Ní pàtó, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi bí ó ti ṣeé ṣe láti gbé ọkàn láti inú ẹnìkan sí inú elòmíràn. Ìmọ̀ wípé ẹnìkan lè gbé ọkàn tí ó ǹ sé àìsàn kúrò nínú ẹnìkan kí ó sì gbé ọkàn tí ó ní ìlera láti ara ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀ jẹ́ àgbààyanu fún mi. Àpẹẹrẹ ẹnì tí ó gba ọkàn túntún tí ó fún-un ní ànfààní láti wà ní ààyè ni èyí.
Bí eléyìí ṣe jẹ́ ohun ìwúrí tó, kì í ṣe irú "pàṣípààrọ̀ ọkàn" bẹ́ẹ̀ ni ó jẹ́ ìyàlẹ́nu jùlọ. Kò sí ìdájulójú pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè di ènìyàn ọ̀tọ̀ ní ìgbà tí ó bá gba ìpààrọ̀ ọkàn tán. Tí ó bá jẹ́ ẹni búburú, onímọ̀tara-ẹni-nikan, àti onígbéraga pẹ̀lú ọkàn rẹ̀ àtijọ́, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹni búburú, onímọtara-ẹni-nikan, àti onígbéraga pẹ̀lú ọkàn rẹ̀ túntún. Ó lè tẹ̀síwájú láti wá láàyè, ṣùgbọ́n ìgbé ayé rẹ̀ lè má yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí láti fún wa ní ọkàn túntún tí yóò yí ìgbé ayé wa padà. Nípasẹ̀ wòlíì Ìsíkíẹ́lì, Ọlọ́run sọ wípé Òun yóò ṣe ìpààrọ̀ ọkàn fún wa. Òun yóò fún wa ní ọkàn túntún, èyí tí yóò dára ju ti àtẹ̀hìnwá lọ. Èyí tí kò tí ì jińgiri nínú ẹ̀ṣẹ̀. Ó jẹ́ èyí tí ó mọ́ tí kò sì ní ẹ̀gbin ẹ̀ṣẹ̀ wá àti ohun tí a gbé ka ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òrìṣà nínú ìgbésí ayé wa. Awa yóò ní irú ọkàn tí ó yàtọ̀ pátápátá sí èyí tí a ní tẹ́lẹ̀, àti wípé kò ní jẹ́ èyí tí yóò mú wa wà láàyè nìkan. Síbẹ̀ yóò mú wa ní ìrírí ìgbé ayé tí a yí padà.
Ó yẹ kí a mọ ìdíyelé tí ó wá nínú ìpaarọ ọkàn. Ní ìgbà tí a bá ṣe ìpààrọ̀ ọkàn ènìyàn ní ilé ìwòsàn, ó túmọ̀ sí wípé ẹnìkan tí kú. Ẹni tí ó fi ọkàn rẹ sílẹ̀ jẹ́ ẹni tí ó ní ìpalára tàbí àìsàn tí ó gba ẹ̀mí rẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti di òkú bí kò bá tilẹ́ jọ̀wọ́ ọkàn rẹ̀ fún ẹlòmíràn láti lò, ṣùgbọ́n òdodo ibẹ̀ ni pé pàṣípààrọ̀ ọkàn kò lè wáyé àfi tí ẹnìkan bá kú.
Irú ìdíyelé kan náà ni ó wà nínú ìpààrọ̀ ọkàn ti ẹ̀mí. Ó ṣeé ṣe nítorí wípé ẹnìkan kú. Ọ̀nà kan ṣoṣo tí a fì lè ní ọkàn túntún ni nípasẹ̀ ìrúbọ Jésù tí ó kú l'órí igi àgbélébùú. Bí Ó ṣe so rẹ ní orí igi àgbélébùú, Ó kó ẹ̀ṣẹ̀ wá sí orí ara Rẹ̀ ó kú kí àwa lè ní ọkàn túntún, tí ó mọ́. Nípasẹ̀ ìdíyelé tí ó gá, ọkàn túntún wá fún wa.
Bí ọdún túntún ṣe bẹ̀rẹ̀ yìí, ṣe ó níílò ọkàn túntún? Ó wá nípasẹ̀ ìbásepọ̀ pẹ̀lú Jésù. Ó fẹ́ kí ó ní ọkàn tí ó mọ́ tí ó sì jẹ ọ̀tun. A ti san ìdíyelé rẹ, ó sì wà fún ọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún tuntun jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Ó jẹ́ àkókò àtúntò, ìsọdọ̀tun àti àtúnṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Níní ọdún tí ó dára jùlọ bẹ̀rẹ̀ nípa mímọ̀ pé a ti sọ ọ́ di ọ̀tun nípasẹ̀ Jésù. Gbé ìgbé-ayé ọ̀tun nínú ọdún tuntun!
More