Ọdún Tuntun: Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tunÀpẹrẹ

New Year: A Fresh Start

Ọjọ́ 4 nínú 5

Gbígbé Pẹ̀lú Ìṣesí Ọ̀tun

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí a fi lè gbé ìgbé ayé tí ó dára sí í ní níní ìṣesí tí ó dára sí i. Ní ìgbà tí a bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, a ti di ẹ̀dá titun. Nítorí náà, a lè ṣe ìsọdọ̀tun ìṣesí wa ní gbogbo ìsòrí ayé wa. A tún ń fún wa ní ìtọ́ni nípa irúfẹ́ ìṣesí tí ó yẹ kí a ní. Ó jẹ́ irúfẹ́ ìṣesí tí yíó ṣe àfihàn ọ̀nà titun láti gbé ìgbésí ayé wa tí yíó sì mú ìsọdọ̀tun tí ó ń t'ọ́jọ́ yọ nínú ayé wa.

Nínú Ìwé Fílípì orí kejì, Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ wípé a kò gbọ́dọ̀ ní ìṣesí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti ṣubú, àmọ́ dípò èyí, a níílò láti ní irúfẹ́ ìṣesí tí Jésù ní. A ní láti gbé ìgbésí ayé wa bí Jésù ti gbé tirẹ̀. Ìwà ènìyàn ní láti máa ṣe ìpinnu àti kí a sì gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀-tara-ẹni-nìkan àti ìgbéraga, àti pẹ̀lú ríri dájú wípé ǹkan lọ bí a ti fẹ́, kí á sì rí ara wa gẹ́gẹ́bí ènìyàn pàtàkì ju àwọn mìíràn lọ. Ní ẹnu kan ṣáá, a ní ìṣesí tí máa ń gbéraga tí ó sì mọ ti ara rẹ̀ nìkan, èyí tí má ń sáábà fi àwọn ohun tí ó níílò àti ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ṣáájú. Irúfẹ́ ìwà yí a máa mú àdínkù bá ìdúró déédéé ìgbésí ayé wa nítorí a máa ṣe ìpalára fún àwọn ìbáṣepọ̀ wa yíó sì mú ayé wa kún fún àìní-ìtẹ́lọ́rùn àti wíwá ohun tí kò sọnù kiri. A ti sọ fún wa pé kí a ní irú ìṣesí ti Jésù. Àmọ́, irú ìṣesí yìí yàtọ̀ kedegbe sí èyí tí ó mọ́ wa lára.

Bí Jésù bá fẹ́ Ó lè gbéraga, Ó lè máa wo ara Rẹ̀ bí ǹǹkan pàtàkì, Ó sì lè máa fẹlá nítorí pé Ó jẹ́ Ọlọ́run. Dípò èyí, Ó bọ́ gbogbo ògo Rẹ̀ sílẹ̀. Ó gbé ẹran ara wọ̀ Ó sì wá sí ayé gẹ́gẹ́bí ọmọ-ọwọ́. Ó ní ìṣesí ìrẹ̀lẹ̀, tí ó fi hàn ní àkókò ìbí rẹ̀ ní ibùjẹ́ ẹran. Ibùsùn Rẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ apẹ ìjẹun fún àwọn ẹran ọ̀sìn. Ìbẹ̀rẹ̀ ayé Rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó mú ìrẹ̀lẹ̀ dání àti wípé Ó dàgbà nínú ẹbí kékeré àti ní ìlú tí kò lókìkí.

Jálẹ̀ àkókò Rẹ̀ ní ayé, Ó ṣe àfihàn ọkàn bíi ti ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹni tí “kò wá fún ẹnikẹ́ni láti sìn ín, bí kò ṣe láti sin àwọn mìíràn.” Ní ọ̀nà gbogbo ni Ó fi gbọ́ràn sí Baba lẹ́nu, débi tí O fi jọ̀wọ́ ẹ̀mí Rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn. Kò fi ti ara Rẹ̀ ṣe; Ó gbọ́ràn; kò sì tiraka láti jẹ èrè ohun gbogbo, àmọ́ Ó ṣetán láti jọ̀wọ́ ohun gbogbo lọ́wọ́ lọ.

Jésù yí kannáà tí ó gbé ìgbésí ayé àwòkọ́ṣe ti ìṣesí tí ó dára lójoojúmọ́ ni ó wá ń gbé inú ọkàn àwọn tí wọ́n ti jọ̀wọ́ ayé wọn fún Un. Ẹ̀mí Mímọ́ lè ró wa ní agbára láti máa gbé irúfẹ́ ayé yìí fún gbogbo ojú láti rí.

Ọdún titun ni èyí, àkókò ti tó báyìí láti gbé ìgbe ayé ìṣesí àìmọ-tara-ẹni-nìkan, ìfẹ́ tòótọ́ kí a sì yí wa padà lójoojúmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.

Nípa Ìpèsè yìí

New Year: A Fresh Start

Ọdún tuntun jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Ó jẹ́ àkókò àtúntò, ìsọdọ̀tun àti àtúnṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Níní ọdún tí ó dára jùlọ bẹ̀rẹ̀ nípa mímọ̀ pé a ti sọ ọ́ di ọ̀tun nípasẹ̀ Jésù. Gbé ìgbé-ayé ọ̀tun nínú ọdún tuntun!

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ International Leadership Institute tí wọ́n pèsè ètò yí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://ILIteam.org/