Ọdún Tuntun: Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tunÀpẹrẹ

Gbígbé Pẹ̀lú Ọ̀nà Tààrà Titún Sí Ọlọ́run
Ni àkókò ikú Jésù, Ọlọ́run ṣe ohún kàn ti o yi ohun gbogbo padà. aṣọ-ìkèle ti o wà nínú Tẹ́mpílì ti o ya Ibi Mímọ Jùlọ s'ọ́tọ̀ "ya si méjì, láti oke dé ìsàlẹ̀."
Bi o tilẹ̀ jẹ pe èyí jẹ́ ìṣẹlẹ ojúkoojú ti o ṣeé rí, pàtàkì ibẹ̀ ni ohun tí ó ṣe àpẹẹrẹ rẹ̀. Ibi Mímọ́ Júlọ jẹ́ èèwọ̀ fún àwọn ènìyàn Hébérù. Olórí Àlùfáà nìkan ni ó lè wọ inú Ibi Mímọ́ Júlọ. Pàápàá lẹ́yìn náà, àwọn ìlànà ti o muná wà láti tẹlé. Ibi Mímọ́ jùlọ yìí jẹ́ àkànṣe nítorí pé ó jẹ́ ibi tí Ọlọ́run n gbé ní ọ̀nà tí a lè fi ojú rí.
Ibi Mímọ́ Jùlọ ní Àpótí Ẹ̀rí ǹ gbé, ìbòrí Àpótí náà ni à ń pè ní "Ìtẹ́ Àánú." Ní iwájú Ìtẹ́ Àánú yíi ni "Ìfarahàn Ògo Olúwa" ti ń ràbàbà. Wíwọ inú Ibí Mímọ Jùlọ túmọ si wípé o wà ní iwájú Ọlọ́run gán-an. Kò sí ẹni tí ó ní ààyè sí Ibí Mímọ Jùlọ. Kódà Olórí Àlùfa yío fi ẹ̀yin wọlé kàkà ki o da oju kọ "Ìfarahàn Ògo."
Ikú Jésù lóri àgbélèbú yi gbogbo èléyìí padà. Dípò àwọn ẹbọ ẹran aláìpé tí yíó ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, Jésù jẹ́ odindi ẹbọ, tí ó dára jù, tí ó sì pé tí a rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Nípa bẹ́ẹ̀, Òun ni Olórí Àlùfáà wa pípé, tí ó ti pèsè ìrúbọ pípé, tí ó jẹ́ kí á lè ní ààyè lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìgbà gbogbo. Kò si aṣọ-ìkèle ti o yà wa s'ọ́tọ kúrò ní iwájú Ọlọ́run mọ́. Nípasẹ̀ Jésù, a ní àǹfààní kíkún si Ọlọ́run.
Hébérù 4 sọ fún wa wípé àǹfààní titún yìí sí Ọlọ́run ń yí ayé ẹni padà. A ní àǹfààní si àánú Ọlọ́run àti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. A lè fi ìgboyà, pẹ̀lú ìdánilójú, súnmọ ìtẹ Ọlọ́run, pẹ̀lú òye wípe àánú àti oore-ọ̀fẹ́ yíó wà fún wa. A kò ní láti fi ẹ̀yin wọlé bí àwọn olórí àlùfá Hébérù ti ṣe. A tí ní ọ̀nà tààrà titún ti o sì yàtọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
Pọ́ọ̀lù sọ nínú ìwé Róòmù wípé a ti sọ wá di ìdílé Ọlọ́run, Jòhánù sì ṣe amúdáju wípé àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Krístì jẹ́ “àwọn ọmọ Ọlọ́run.”
Àwọn àyọkà wọ̀nyìí fún wa ní ìrètí púpọ̀. A kò ni láti fi ara pamọ́ fún Ọlọ́run bi Ádámù àti Éfà ti ṣe lẹyìn ti wọn ṣẹ̀. Ṣíṣe àwari ọ̀nà tààrà si àánú tuntun Ọlọ́run lé fún wa ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun si ìgbésí ayé titún kárí ọdún!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún tuntun jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Ó jẹ́ àkókò àtúntò, ìsọdọ̀tun àti àtúnṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Níní ọdún tí ó dára jùlọ bẹ̀rẹ̀ nípa mímọ̀ pé a ti sọ ọ́ di ọ̀tun nípasẹ̀ Jésù. Gbé ìgbé-ayé ọ̀tun nínú ọdún tuntun!
More