Ọdún Tuntun: Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀tunÀpẹrẹ

Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tun
Nípasẹ̀ wòlíì Ìsíkíẹ́lì, a kọ́ pé Ọlọ́run pèsè ọkàn tuntun fún wa. Yàtọ̀ sí ìpààrọ̀ ọkàn ti ara tí ó yíó mú kí ẹ̀mí ẹni gùn, ìpààrọ̀ ọkàn ti ẹ̀mí tí Ọlọ́run ń fún wa ń yí ayé wa padà pátápátá. Jésù kọ́ wa pé láti inú ọkàn ni ìṣúra ayé tí ń wá. Nípa bèẹ̀ bí Jésù bá fún wa ní ọkàn tuntun, gbogbo agbọn ìgbésí ayé wa ni yíó ni ipa lórí wọn. Nípasẹ̀ Kristi, a jẹ́ ẹ̀dá tuntun, àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, àwọn ohun tuntun sì ti dé. A ní ìgbésí ayé tuntun.
A ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ẹ̀bi àti ìtìjú wa ti di èyí tí kò sí mọ́. Nísinsìnyí, àwọn ìdojúkọ wa tilẹ̀ ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé a ti dáríjì wá, a lè dáríji àwon mìíràn. A ti rí àánú gbà kí àwa náà lè jẹ́ aláàánú. Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo kà wá sí pàtàkì. Nítorí náà, kò sí ìdí fún wa láti fi ẹ̀rí hàn fún ẹnikẹ́ni pé a ní iye lórí, kódà kò sí ìdí fún wa láti fi ẹ̀rí hàn fún ara wa pàápàá!
Èrò tí a ní nípa ara wa yíó yí padà bí a ṣe ń fi ojú Ẹni tí ó mọ̀ wá jùlọ wò ara wá, tí Ó sì kà wá sí ẹni tí ó yẹ fún ìrúbọ Rẹ̀. A ní ìrètí ayérayé tí kì í yí padà, bí ipò nǹkan tilẹ̀ yí padà. A ní ayọ̀ àtinúwá tí ó ju gbogbo àdánwò àti ìpọ́njú ayé yíí lọ. A ní ìgbésí ayé tuntun.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ di ẹni tí ó ní iyì ní ojú Ọlọ́run, ìyẹn kò wá túmọ̀ sí pé ipò wa yíó kàn ṣààdédé yí padà. Bákan náà, kò túmọ̀ sí pé àwọn ẹlòmíràn náà ti yí padà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gá wa tí ó jẹ́ aláìṣòótọ́ àti onígbèéraga ṣì lè jẹ́ aláìláàánú àti aláìlóye síbẹ̀.
Àmọ́ àwa yàtọ̀ sí èyí. A lè rí ǹǹkan ní ọ̀nà ọ̀tọ̀, a lẹ ní òye ní ọ̀nà ọ̀tọ̀, kí a sì dáhùn sí àwọn ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ní ọ̀nà ọ̀tọ̀. Ìdí ni pé a jẹ́ "ẹ̀dá tuntun nínú Krístì". Irú ìgbékalẹ̀ tí ó ń yí ẹni ní èrò padà tí ó sì ń mú ìyípadà bá 'ni ni Jésù fi àkàwé "dídi àtúnbí" ṣe. A lè gbé ìgbéayé tuntun nítorí pé a di tuntun. A ní ìgbé ayé tuntun nípasẹ̀ Jésù Krístì.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún tuntun jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Ó jẹ́ àkókò àtúntò, ìsọdọ̀tun àti àtúnṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Níní ọdún tí ó dára jùlọ bẹ̀rẹ̀ nípa mímọ̀ pé a ti sọ ọ́ di ọ̀tun nípasẹ̀ Jésù. Gbé ìgbé-ayé ọ̀tun nínú ọdún tuntun!
More