Ìdí tí a fi bí JésùÀpẹrẹ

Why Jesus Was Born

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ìdí Tí Jésù Fi Wá

Kristi Jesu wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là. (1 Tímótì 1:15)

Àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì àti Títù ni wọ́n ń pè ní "Awọn Epistles Pastoral" nítorí pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyí ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí nígbà tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ pásítọ̀ ní Éfésù àti erékùṣù Kírétè. Tímótì àti Títù ló ṣojú fún ìran kejì àwọn oníwàásù, bí Pọ́ọ̀lù sì ṣe ń múra láti gbé ọ̀pá àṣẹ ìhìn rere lé wọn lọ́wọ́, ó fún wọn ní ọ̀rọ̀ ìṣírí.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ àwọn lẹ́tà tó kẹ́yìn wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ lára "àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣeé gbíyè lé" ti bẹ̀rẹ̀ sí tàn kálẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò sẹ́ni tó ní Bíbélì tàbí ìwé èyíkéyìí, àwọn èèyàn ní láti há àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàkópọ̀ ìhìn rere náà ní ọ̀rọ̀ díẹ̀ sórí. Nínú gbogbo àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ nípa iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, ó sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tó gbajúmọ̀ wọ̀nyẹn, ó sì fi èdìdì ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì sí wọn. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Tímótì Kìíní yìí, Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ kan tó gbajúmọ̀ yọ, ó ní: "Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là".

Ẹ jẹ́ kí a gbádùn àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìhìn rere jẹ́ gan-an. A kì í sábà ronú nípa bí a ṣe jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó nígbà Kérésìmesì. A máa ń fẹ́ kí nǹkan máa lọ bó ṣe yẹ. Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ló mú kí wọ́n bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. A bí Jésù láti gbà wá lọ́wọ́ gbogbo ìyẹn. Ohun tí ọdún Kérésìmesì wà fún gan-an nìyẹn.

Àwọn kan lára wa mọ "Àdúrà Jésù" wọ́n sì máa ń gbà á déédéé. Ó rọrùn: "Olúwa Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, ẹlẹ́ṣẹ̀." A mọ̀ pé irú àánú bẹ́ẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Nítorí pé "Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là."


******

Àwọn ìwé ìfọkànsìn yìí jẹ́ apá kan ìwé ìfọkànsìn Ọ̀rọ̀ Ìrètí tó wà fún oṣù kan. Láti kà síi,ṣe alabapin sí ọ̀rọ̀ ìrètí ìfọkànsìn lónìí !


Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Why Jesus Was Born

Kíni ìdí rẹ̀ tí a fi bí Jésù? Èyí lè jọ́ ìbéèrè tí ó rọrùn, tí ó wọ́pọ́ọ̀ tí à lè r'onú lé lórí. Ṣùgbọ́n bí o ti ń gbáradì fún Kérésìmesì ti ọdún yìí, tẹ ẹsè dúró díẹ̀ láti ṣe àṣàrò lórí ìtumọ̀ tí ó jinlẹ̀ àti ète ìbí Jésù fún ayé rẹ àti gbogbo àgbáyé. A kọ ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí láti ọwọ́ Scott Hoezee, ó sì jẹ́ àyọkà láti inú ẹ̀kọ́-ìfọkànsìn ojoojúmọ́ ti Words of Hope (Ọrọ̀ Ìrètí).

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Words of Hope fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://woh.org/youversion