Ìdí tí a fi bí JésùÀpẹrẹ

Fún yín
Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa. (Lúùkù 2:11)
Bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ni a bí ọmọbìnrin wa. Àlùfáà ni mí nígbà yẹn àti nítorí pé a bí ọmọ náà ní òwúrọ̀ Ọjọ́ Àìkú kan, Àlùfáà kan tí ó ti fẹ̀yìn tì ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù dípò mi. Ní orí ẹ̀ka náà, ṣe ìkéde kan: “Rev. Hoezee àti Rosemary bí ọmọbìnrin kan láàárọ̀ òní.” Àmọ́, ǹjẹ́ kò ní ṣàjèjì tó bá sọ fún ìjọ pé:, “Òwúrọ̀ yìí ni a bí ọmọ kan fún yín”? A bí ọmọbìnrin kan fún èmi àti ìyàwó mi. Ṣùgbọ́n a kò bí i fún gbogbo ìjọ, tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn.
Ohun tí áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ẹ̀rù ba: A ti bí Olùgbàlà kan “fún yín.” Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe lè yé ẹ? Ọmọ Màríà àti ti Jósẹ́fù ni (Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní ìtumọ̀ tí a mọ̀). Àmọ́ kì í ṣe ọmọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn. Wọn ò ní yí aṣọ ìnura padà. Wọn ò ní fi oúnjẹ bọ́ ọmọ náà, wọn ò sì ní tọ́ ọ dàgbà. Wọ́n á lọ wo ọmọ náà, lẹ́yìn náà, wọ́n á pa dà sí ọ́dọ̀ àwọn àgùntàn wọn.
Yàtọ̀ sí pé Jésù kì í ṣe ọmọdé lásánlàsàn. Ó wá fún gbogbo wa. A bí i fún gbogbo wa. Kì í ṣe ọmọ tí áwọn olùṣọ́ àgùntàn bí, àmọ́ Olùgbàlà wọn ni. Ó wá fún wọn, Wọ́n jẹ́ ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ àti tí a fojú kéré, wọ́n sì yọ wọ́n lẹ́gbẹ̀ẹ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. “Fún yín.” A máa ń gbójú fo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn dá. Ṣùgbọ́n wọ́n ní èrò inú ìwé ìhìn rere náà nínú!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Kíni ìdí rẹ̀ tí a fi bí Jésù? Èyí lè jọ́ ìbéèrè tí ó rọrùn, tí ó wọ́pọ́ọ̀ tí à lè r'onú lé lórí. Ṣùgbọ́n bí o ti ń gbáradì fún Kérésìmesì ti ọdún yìí, tẹ ẹsè dúró díẹ̀ láti ṣe àṣàrò lórí ìtumọ̀ tí ó jinlẹ̀ àti ète ìbí Jésù fún ayé rẹ àti gbogbo àgbáyé. A kọ ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí láti ọwọ́ Scott Hoezee, ó sì jẹ́ àyọkà láti inú ẹ̀kọ́-ìfọkànsìn ojoojúmọ́ ti Words of Hope (Ọrọ̀ Ìrètí).
More