Ìdí tí a fi bí JésùÀpẹrẹ

Ó ń tàn
Ìmọ́lẹ̀ náà tàn nínú òkùnkùn. ( Jòhánù 1:5 )
A rí i tẹ́lẹ̀ bí Máàkù ṣe fí “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìhìnrere” hàn wá. Lónìí Jòhánù mú wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ pátápátá nípa ṣíṣílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ kàn tó jọra láti inú ìwé Gẹ́nẹ́sísì: “Ní ìbẹ̀rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jòhánù kò ní ìtàn kankan nínú nípa ìbí Jésù, ó fún wa ní àyíká ọ̀rọ̀ tó dára jù lọ fún ìbí yẹn nípa fífi ojú ìwòye wa síbi tó jìnnà bí òfuurufú.
Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa “Ọ̀rọ̀” Ọlọ́run. Ní èdè gíríìkì ọ̀rọ̀ náà jẹ́ “logos”. Ní èdè àwọn Gíríìkì, "logos" náà ló jé ìlànà tó ṣe pàtàkì jù lọ. Níbi, Jòhánù lò èrò yẹn, pẹ̀lú ìyípadà pàtàkì kàn. Ọ̀rọ̀ náà "logos" to je òotọ́ kì í ṣe agbára ayé kan lásánlàsàn. Ọmọ Ọlọ́run yìí ló wá di èèyàn níkẹyìn gẹ́gẹ́ bí Jésù tí Násárétì.
Nínú Gẹ́nẹ́sísì Orí Kínní tí a kàá “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ sì wa . . . Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó ju ọ̀gbìn. . . Jẹ́ kí omi kí o kún fún àwọn ohun alààyè . . .” èyí ni Ọmọ Ọlọ́run tí ó ń sọ̀rọ̀. Bàbá, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́, gbogbo wọn ló ń ṣiṣẹ́ nínú ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, ṣùgbọ́n —"Ọ̀rọ̀"—Ọlọ́run ní ẹni tí ó ń pàṣẹ.
Òun ni ìyè òun ọ̀run. Òun sì ni ìmọ́lẹ̀ tí ó ń tàn. Nínú àlàyé rẹ̀ Ìhìnrere tí Jòhánù, Frederick Dale Bruner tẹnu mọ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà ní àkókò ìsinsìnyí: Ìmọ́lẹ̀ náà tàn. Èyí ti ń lọ lọ́wọ́. Kò sí ní dáwọ́ dúró. Òkùnkùn ibi kò sì ní pa á. Nígbà mìíràn òkùnkùn ayé yìí dàbí pé o lágbára. Ṣùgbọ́n ìhìnrere sọ fún wa pé kò lè fi ẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Kíni ìdí rẹ̀ tí a fi bí Jésù? Èyí lè jọ́ ìbéèrè tí ó rọrùn, tí ó wọ́pọ́ọ̀ tí à lè r'onú lé lórí. Ṣùgbọ́n bí o ti ń gbáradì fún Kérésìmesì ti ọdún yìí, tẹ ẹsè dúró díẹ̀ láti ṣe àṣàrò lórí ìtumọ̀ tí ó jinlẹ̀ àti ète ìbí Jésù fún ayé rẹ àti gbogbo àgbáyé. A kọ ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí láti ọwọ́ Scott Hoezee, ó sì jẹ́ àyọkà láti inú ẹ̀kọ́-ìfọkànsìn ojoojúmọ́ ti Words of Hope (Ọrọ̀ Ìrètí).
More