Ìdí tí a fi bí JésùÀpẹrẹ

Why Jesus Was Born

Ọjọ́ 1 nínú 5

Àtètèkọ́ṣe

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìhìnrere Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run. (Máàkù 1:1)

Ìwásáyé Jésù jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Ìwásáyé Jésù jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún àgbáláayé. Ní òní, Máàkù mú wa padà sí àtètèkọ́ṣe. Ẹsẹ àkọ́kọ́ yìi ni agbára gidi. Ní ìlànà ìsọ̀rọ̀ ní kúkúrú gbòngbò rẹ̀—Máàkù kì í fi ọ̀rọ̀ ṣ'òfò—Máàkù sọ fún wa wípé èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere náà, ìròyìn ayọ̀. Lẹ́yìn náà ni ó wá se àfihàn ọkùnrin ará Násárẹ́tì náà tí à ń pè ní Jésù, ó sì sọ fún wa ní ojú ẹsẹ̀ pé òun ni Krístì, Mèsáyà tí a ti ṣe ìlérí rẹ láti ìgbà láíláí. Lẹ́yìn náà ni ó tún wá sọ fún wa wípé kò sé ní Ọmọ Ọlọ́run tìkaararẹ̀. Ènìyàn lè lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ láti hú ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan yìí jáde.

Kò sí ẹni tí ó mọ pàtó bí “àtètèkọ́ṣe” yìí ṣe gbòòrò tó ní inú Máàkù. Ǹjẹ́ àtètèkọ́ṣe yìí mọ ní orí kìnní? Ǹjẹ́ apá kan orí kìnní ni? Tàbí gbogbo ìwé Máàkù fúnraarẹ̀ jẹ́ àtètèkọ́ṣe? Ohun yòówù kó jẹ́, a bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjẹ́wọ́ tààrà pé Jésù ni Àyànfẹ́ Ọlọ́run àti Krístì tí a fi òróró yàn. Jésù ni Ẹni náà! Ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni, a mọ̀ pé ọ̀kan nínú Mẹ́talọ́kan tí ó wá ní àwòràn ènìyàn, tí à ń pè ní Jésù, ti wà láti ayérayé.

Ìròyìn ayọ́ ni èyí náà nítorí ó sọ fún wa wípé ẹni tí ó wá sí ayé ní òru ọjọ́ tí ìràwọ̀ gba ojú-ọ̀run kan ní Bẹtílẹ́ẹ́mù ní agbára àtọ̀runwá tí ó yẹ́ láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. Gbígbà tí Ọlọ́run gba ẹnìkọ̀ọ̀kan wa là ni òpin ìtàn náà. Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run tìkaararẹ̀!

Ọjọ́ kìnníí

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Why Jesus Was Born

Kíni ìdí rẹ̀ tí a fi bí Jésù? Èyí lè jọ́ ìbéèrè tí ó rọrùn, tí ó wọ́pọ́ọ̀ tí à lè r'onú lé lórí. Ṣùgbọ́n bí o ti ń gbáradì fún Kérésìmesì ti ọdún yìí, tẹ ẹsè dúró díẹ̀ láti ṣe àṣàrò lórí ìtumọ̀ tí ó jinlẹ̀ àti ète ìbí Jésù fún ayé rẹ àti gbogbo àgbáyé. A kọ ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí láti ọwọ́ Scott Hoezee, ó sì jẹ́ àyọkà láti inú ẹ̀kọ́-ìfọkànsìn ojoojúmọ́ ti Words of Hope (Ọrọ̀ Ìrètí).

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Words of Hope fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://woh.org/youversion