Ìdí tí a fi bí JésùÀpẹrẹ

Why Jesus Was Born

Ọjọ́ 2 nínú 5

Ìbí náà

Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrinn. (Lúùkù 2:7)

Fún ẹnikẹ́ni tí ó ti jẹ́ Kristẹni fún ìgbà díẹ̀, ìtàn yìí mọ́ ni lára. Òun ni ìmísí tó wà lẹ́yìn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ilé ìkókó àti àwọn ibi tí wọ́n ti ń sin ẹran àti àwọn àwòrán ìbí Jésù tó wà láàyè ní àwọn Ilé ìjọsìn. Láìka gbogbo ọ̀nà tí á gbà mú kí ìtàn yìí tàn bí wúrà, ìbí rírẹlẹ̀ ni. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀nà ìtìjú láti wá sáyé. Àmọ́, ìyẹn náà ni ohun tó wà nídìí gbogbo rẹ̀. Ọmọ Ọlọ́run rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó lè gbé gbogbo wa ga.

Ó yẹ ká kíyè sí i, báwo ni Lúùkù ṣe ṣàkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé ìhìn rere.Ó sì tún máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ó gbòòrò sí i nínú ìwé Lúùkù orí ìkẹ́ta, Lúùkù ṣàkọsílẹ̀ àwọn tó wà nípò àṣẹ ní ìlú Róòmù nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì ló pe ara rẹ̀ ní “Dominus et Deus” tabi “Olúwa àti Ọlọ́run” ìjọba àpapọ̀. Nígbà tí Késárì bá sọ pé, "Fò!" gbogbo ayé ló dáhùn pé, "Báwo ló ṣe yẹ ká fò lọ sókè tó?" Késárì, Kúírínọ́sì, Hẹ́rọ́dù, Pọ́ńtíù Pílátù: àwọn wọ̀nyí ni àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn, àwọn olóṣèlú tó gbajúmọ̀ nígbà yẹn.

Àmọ́ kì í ṣe torí kí Lúùkù lè jẹ́ òpìtàn lásán ló ṣe kọ orúkọ wọn sílẹ̀. Ohun tí ó ń sọ nípa ìsìn ni. Gbogbo àwọn olórí àgbáyé wọ̀nyẹn lè máa fi ara wọn hàn nínú gbogbo ògo àti ipò tí wọ́n fẹ́, ṣùgbọ́n wọn ò lè fi wọ́n wé Jésù láé. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀rọ̀ nípa Késárì á di ìtàn àròsọ. Àmọ́ ọmọdékùnrin tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù yóò jáde wá gẹ́gẹ́ bí Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa lóòtọ́. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run! 


Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Why Jesus Was Born

Kíni ìdí rẹ̀ tí a fi bí Jésù? Èyí lè jọ́ ìbéèrè tí ó rọrùn, tí ó wọ́pọ́ọ̀ tí à lè r'onú lé lórí. Ṣùgbọ́n bí o ti ń gbáradì fún Kérésìmesì ti ọdún yìí, tẹ ẹsè dúró díẹ̀ láti ṣe àṣàrò lórí ìtumọ̀ tí ó jinlẹ̀ àti ète ìbí Jésù fún ayé rẹ àti gbogbo àgbáyé. A kọ ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí láti ọwọ́ Scott Hoezee, ó sì jẹ́ àyọkà láti inú ẹ̀kọ́-ìfọkànsìn ojoojúmọ́ ti Words of Hope (Ọrọ̀ Ìrètí).

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Words of Hope fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: http://woh.org/youversion