Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́: Atọ́na tí ó rọrùn sí Àwọn Àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́Àpẹrẹ

Dúró Jẹ́ẹ́: sínú àgbáyé
Nígbà gbogbo a má sọ pé bí a ti ń dàgbà si, a ó máà jọ́ àwọn òbí wa!
Bákan náà, bí àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe ń tẹ́ siwaju ní àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ní ibi tí ó dákẹ́rọ́rọ́, yíò ní ipa lórí bí a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa.
Ní àwọn ọ̀nà míràn ẹ̀wẹ̀, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà, kò yẹ kí ó dúró nínú ọgbà— ó yẹ kí ó hàn nínú ìgbésí ayé wa. Bí àkókò tí a bá ń lò pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni a óò túbọ̀ dà bí Rẹ̀; dé bí pé a ó dàbí òjìji Rẹ̀.
Ní àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́ yi, a ó mí ìmí Ọlọ́run sinu; a ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ohun ọ̀run. A máa ń jẹ́ kí ọkàn Rẹ̀ wọ inú ọkàn wa, a ó gbà ọkàn Rẹ̀ l'áyè láti mí sí ọkàn wa àti pé àwa ó sì wá ní ìbámu pẹ̀lú Rẹ̀. Bí a ṣe ńṣe ni ṣísẹ́-ńtẹ́lé pẹ̀lú ọkàn àti ìfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́ náà, ó ń mú kí ìwòye wa gbòòrò ju awa àti àwọn tí ó súnmọ́ wá pẹ́kípẹ́kí lọ.
Lẹ́hìn tí a bá ti mí sínú, a tún gbọdọ̀ mí síta. Ẹ Jẹ́kí a ronú nípa rẹ̀ ní ọ̀nà àdáyébá yi— kò ṣeé ṣe pé kí a máà mí sínú nìkan láì mí sítá. A ó ní ìlera pípé, a ó sì wà láàyè, nígbà tí a bá lè ṣe méjèèjì!
Bob Pierce, tí ó jẹ́ olùdásílè ìran Àgbáyé, sọ nígbà kan pé “Olúwa tú ọkàn mi palẹ̀ pẹ̀lú ohun tí ó fi tú ọkàn Rẹ̀ náà palẹ̀.” Nígbà ti á bá wà ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ọkàn Ọlọ́run ní tòótọ́ ní àwọn àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́ wa, yíò tú ọkàn wa palẹ̀ fún gbogbo àgbáyé Rẹ̀. Bí Ọlọ́run ṣe ń fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wa, ó lè ṣe amọ̀nà wa sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí àwọn ipò tí a kò fi ọkàn si tẹ́lẹ̀.
Àṣẹ tí a pá fún àwọn ọmọ-lẹ̀hìn Jésù ní Mátíù 28 ní láti lọ sọ ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn di ọmọ-lẹ́hìn Jésù. Síbẹ̀, ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí Jésù gòkè lọ sí ọ̀run ni pé kí wọ́n lọ sínú yàrá ìkọ̀kọ̀ kan kí wọ́n sì gbàdúrà. Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé wọn pẹ̀lú agbára, a sì lé wọn jáde kúrò nínú yàrá ìkọ̀kọ̀, láti ibi Ìdákẹ́rọ́rọ́, sínú ogunlọ́gọ̀ ènìyàn níbi tí wọ́n ti ń polongo ìhìn rere Jésù.
Ọjọ́ yen ni a dá ìjọ silẹ
Eléyìí di ohun tí wọn ń ṣe léraléra; wọn kò gbàdúrà làti ṣe alábápàdé Ẹ̀mí Mímọ lẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ ní lemọ́-lemọ́. Èyí jẹ́ ìpè fún wa láti ṣé, pé kí a ṣe ìpín-fúnni ìfẹ́ náà tí a ti rí yí.
Àkúnwọ́sílẹ̀ àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́ tí ó ti mọ́ra yí yíò jasi pé ìwọ yíò wá láti wá ọmọ-lẹ́hìn sí i; dájúdájú ìfẹ́ tí a ní ìrírí rẹ yí kò há pọ̀ jù fún àwa nìkan bi? Eléyìí jẹ ohun tí ó lè fà ìwúrí àti ìdààmú; nígbà míràn a kàn le fẹ́ wà nínú ọgbà, ní ìfọkàn balẹ̀ kí á ma gbádùn níwájú Jésù, gẹ́gẹ́ bí ọmọ-lẹ́hìn Rẹ̀, kí a sì máà kọ̀ ẹ̀kọ́ lábẹ́ ẹsẹ Rẹ̀
Àdúrà ni Àdúrà ńjẹ́; kìí ṣe ohun èlò fún ìṣẹ ipe tàbí pàápàá ìlànà fún ìṣẹ ìpè. Ṣùgbọ́n nígbà gbogbo ní ó jẹ́ ibi tí iṣẹ́ ìpè tí bẹ̀rẹ̀.
Báwo ni o ṣe lè ṣe ìpín-fúnni ìfẹ́ Krístì lónìí?
Báwo ni ó ṣe lè ṣe àfihàn Bàbá rẹ tí mbẹ ni ọrùn fún àwọn ènìyàn?
Láti ra ẹ̀dá ìwé kan tiDúró Jèẹ́láti owó Brian Heasley, tẹNíbí.
Dákẹ́ Jèẹ́ :nínú àgbáyé
Nígbà gbogbo a má sọ pé bí a ti ń dàgbà si, a bẹ̀rẹ̀ láti dàbí àwọn òbí wa!
Lọ́nà kan náà, bí àjọṣe pọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe ún tí a ń dàgbà ní àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ní ibi tí ó dákẹ́, yóò ní ipa lórí bí a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa.
Ní àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà, kò yẹ kí ó dúró nínú ọgbà- ó yẹ kí ó hàn nínú ìgbésíayé wa. Bí àkókò tí a bá ń lò pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni a óò túbọ̀ dà bí rẹ̀; dé ìwọ̀n àyè kan a di ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀..
Ní àkókò ìdákẹ́jẹ́, a simi níwájú Ọlọ́run; a ní àso pọ̀ pẹ̀lú oun ọ̀run. A máa ń jẹ́ kí ọkàn Rẹ̀ wọ inú ọkàn wa, a sì máa ń tẹ̀ lé e. Bí a ṣe ń mon àti tẹ́lẹ̀ ọkàn àti ìfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ó ń mú kí àfojúsùn wa gbòòrò ju tiwa lọ àti àwọn tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú wa ní tààràtà.
Lẹéhìnná tí a bá ti mí sínú, a tún gbọdọ̀ mí jáde. Ronú nípa rẹ̀ ní ọ̀nà àdáyébá - a kọ̀ le kàn ma mí sínú nìkan láìsí tún mí jáde. A ní ìlera, a wà láàyè, nígbà tí a bá ṣe méjèèjì!!
Bob Pierce, olùdásílè ìran Àgbáyé, sọ nígbà kan, “Olúwa tún ọkàn palẹ̀ pẹ̀lú ohun tí ó tún ọkàn rẹ náà.” Nígbà ti á bá n sopọ̀ mọ́ ọkàn Ọlọ́run ní tootọ ní àwọn àkókò ìdákẹ́jẹ́ wa, yóò fọ ọkàn wa fún gbogbo àgbáyé rẹ̀. Bí Ọlọ́run ṣe ń fi ọwọ́ tọ́ ọkàn wa, ó lè ṣamọ̀nà wa sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tàbí àwọn ipò tá a ò lè fojú sọ́nà fún
Àṣẹ tí a fún àwọn ọmọ- ẹ̀hìn Jésù ní Mattew 28 ní láti lọ sọ ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn di ọmọ lẹ́yìn Jésù. Síbẹ̀, ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí Jésù gòkè re ọ̀run ni pé kí wọ́n lọ sínú yàrá àdádó kan kí wọ́n sì gbàdúrà. Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà lé agbára, a sì lé wọn jáde kúrò nínú yàrá ìkọ̀kọ̀, láti ibi ìdákẹ́jẹ́ẹ́, sínú ìjọ ènìyàn níbi tí wọ́n ti ń waasu ìyìn rere Jésù.
A bí ìjọ lọ́jọ́ náà.
Eléyìí di oun gbogbo ìgbà; wọn kò gbàdúrà àti pàdé Ẹ̀mí Mímọ ní ẹ̀ẹ̀kan, ó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà gbogbo. Èyí jẹ́ ìṣẹ láti ṣé, pé ká wàásù ìfẹ́ tí a ti rí.
Àkúnwọ́sílẹ̀ àdánidá ti àkókò ìdákẹ́jẹ́ yóò jẹ́ pé ìwọ yóò wá láti sọni di ọmọ lẹ́yìn sí i; dájúdájú pé ìfẹ́ tí a nírìírí yìí ti pọ̀ jù láti pa á mọ́? Eléyìí jẹ́ oun tí ó pín sí ọ̀nà méjì èyí tí ó móríwú àti pé ó ní agbára; nígbà mìíràn a má fẹ́ wà nínú ọgbà, ní ìfọkàn balẹ̀ kí á ma gbádùn níwájú Jésù, gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Rẹ̀, tí a sì kọ̀ ọ̀nà rẹ̀
Àdúrà ni Àdúrà; kìí ṣe epo fún ìṣẹ ìyìn rere tàbí pàápàá ìlànà fún ìṣẹ ìyìn rere. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ nígbà gbogbo ibi tí ìṣẹ náà ti béèrè.
Báwo ni o ṣe le pín ìfẹ́ Krístì lónìí?
Báwo lo ṣe lè máa fi Baba rẹ ọ̀run hàn sáwọn èèyàn?
Láti ra ẹ̀dá kan tiDákẹ́ Jèẹ́láti owó Brian Heasley, tẹNíbí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Dúró Jẹ́ẹ́. Fún àwọn kan, àwọn ọ̀rọ̀ méjì wọ̀nyí jẹ́ ìpè sì àkíyèsí l'áti sinmi díẹ̀. Fún àwọn elòmíràn, wọn ní ìmọ̀lára pé kò ṣeé ṣe rárá ni, tí kò tilẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ bi ariwo ìgbòkègbodò ayé ṣe ń pọ̀ si, tàbí ki a kàn sọ wípé ó nira púpọ̀ l'áti ṣe. Brian Heasley ṣe àpèjúwe pé kí í ṣe pé kí a dúró ní àìmìrá fún àwọn ọkàn wa l'áti wá ní ìdákẹ́-rọ́rọ́, àti bí pàápàá ní àárín-gbungbun ìgbésí ayé tí ọwọ́ wá kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́, a sì lè ni àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
More