Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́: Atọ́na tí ó rọrùn sí Àwọn Àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́Àpẹrẹ

Dúró Jẹ́ẹ́: Ìfaradà Tí ó Farasin
Àṣà ìkéde wà nítòótọ́.
A ń gbé nínú ayé ìlàkàkà láti jẹ́ ẹni tí àrayé rí; a máa ń wo àwọn àwòrán ara-ẹni tí a gbà sílẹ̀ tí àwọn ènìyàn fi sórí afẹ́fẹ́, èyí a sì máa ti'ni gbọ̀ọ́gbọ̀ọ́ láti kéde ti ara wa náà ní ona tí a fi ọgbọ́n gbé kalẹ̀.
Ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àkókò ìdákẹ́ jẹ́ ni pé a máa ń ṣe é ní ìkọ̀kọ̀. Ó farasin.
Nínú ìwé 1 Àwọn Ọba 17, Èlíjà fara hàn ní ipò ìlúmọ́ọ́ká, ní ààfin Ọba Áhábù, níbi tí ó ti kéde ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí yóò ní ipa tó jinlẹ̀ lórí orílẹ̀-èdè náà, ó wípé “Kò ní sí òjò tàbí ìrì àyàfi bí mo bá sọ.”
Ìkéde tí ó ní agbára ni èyí.
Ní ésẹ tí ó tẹ̀ lé e Ọlọ́run sọ fún Èlíjà pé, "Lọ kúrò níhìn-ín, kí o sì yíjú sí ìlà-oòrùn, kí o sì fara pa mọ́." Èlíjà yára lọ láti ipò ìlúmọ́ọ́ká lo sí ibi tí ó farasin.
Fi Ara Rẹ Pa Mọ́!
Níbi tí Èlíjà fi ara pamọ́ sí, Ọlọ́run fún un ní ìpèsè tí ó ṣe àrà ọ̀tọ̀, nínu ibi tí ó pamọ́ ní ẹ̀bá odò kékeré kan, àwọn ẹyẹ àkọ̀ fún un ní oúnjẹ lójoojúmó ̣.
Èyí ti kúrò ní ibi ìrọ̀rùn fún un. Ó jìnnà pátápátá sí ààfin ọba; ó wà ní ibi àdádó, níbi tó ti gbára lé Ọlọ́run pátápátá fún oúnjẹ àti ìtùnú. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, odò náà gbẹ, Èlíjà sì rìnrìn àjò lọ sí àgbègbè àwọn ọ̀tá, níbi tí opó kan ti pèsè oúnjẹ fún un lọ́nà ìyanu. Èyí tún jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ nira fún Èlíjà.
Ohun tí ó ta àbùkù báni ní àwùjọ, tí ó sì rẹ ni sílẹ̀ ni kí ọkùnrin, ènìyàn Ọlọ́run wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ opó ti óun fúnra rẹ̀ gbé ara lé ọrẹ àánú. Síbẹ̀, ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ ni Ọlọ́run ma Ń ṣe iṣẹ́ ìyanu; Ó pèsè ìyẹ̀fun àti òróró tí kò lópin fún Èlíjà àti ìdílé opó náà láti máa jẹ.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí Ọlọ́run kọ́kọ́ pàṣẹ fún Èlíjà pé kó lọ fara pa mọ́, Ọlọ́run sọ fún un pé, "Lọ, fi ara rẹ hàn." (1 Àwọn Ọba 18:1) Èlíjà sì tún padà lọ, ó sì kéde pé òjò máa rọ̀.
Fojú inú wo bí ìdúró ṣe máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ni nígbà míràn?
Nínú àṣà tó dà bíi pé wọ́n ka òkìkí, ipò ọlá, ìtẹ́wọ́gbà, àti ìtẹ́wọ́gbà láwùjọ kun, báwo ni a ṣe ń fi èrò sì pípa ara ẹni mọ́?
Ní ibi ìpamọ́ ni a ti ń kọ́ nípa Ọlọ́run, níbi tí a ti di ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé e, tí a ń tu ara wa nínú, tí a sì ń jẹun lọ́wọ́ rẹ̀, níbi tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ó mọ ohun tí ó ń ṣe, níbi tí àwọn ẹ̀kọ́ tí a ń kọ́ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún wa, tí ó sì máa ń túmọ̀ sí pé àwọn ẹyẹ àdàbà ń bọ́ wa, tí àwọn opó sì ń tọ́jú wa. Ìkọ̀kọ̀ máa ń múra wa sílẹ̀ fún àwọn àkókò tí a ó fi wá hàn.
A tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìfaradà nínú ìkọ̀kọ̀: Ìwé 1 Àwọn Ọba orí kẹtàdínlógún kó ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún mẹ́ta já: àkókò tí a fà gùn fún ìfarasin.
Róòmù 12:2 kọ́ wa pé: "Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin.”
Bí a bá fẹ́ ní àkókò tí ó dákẹ́ rọ́rọ́, tí a kò sì fẹ́ bá ayé dọ́gba, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó ń darí àṣà wa, ni ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní wàràwàrà.
A ní láti kọ́ bí a ṣe lè ní ìfaradà nínú àṣà kíákíá yìí.
Ṣe àkọsílẹ̀ lónìí, kí ó sì fi sínú Bíbélì rẹ tàbí ibì kan tí o máa ń wò déédéé. Múra láti ma gbàdúrà déédéé, kí o sì máa gbàdúrà dáadáa fún àwọn ènìyàn àti ìlàkọjá wọn tí o kọ sílẹ̀, kódà bí ó bá gba ọ̀pọ̀ ọdún kí ọ̀rọ̀ náà tó yanjú.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Dúró Jẹ́ẹ́. Fún àwọn kan, àwọn ọ̀rọ̀ méjì wọ̀nyí jẹ́ ìpè sì àkíyèsí l'áti sinmi díẹ̀. Fún àwọn elòmíràn, wọn ní ìmọ̀lára pé kò ṣeé ṣe rárá ni, tí kò tilẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ bi ariwo ìgbòkègbodò ayé ṣe ń pọ̀ si, tàbí ki a kàn sọ wípé ó nira púpọ̀ l'áti ṣe. Brian Heasley ṣe àpèjúwe pé kí í ṣe pé kí a dúró ní àìmìrá fún àwọn ọkàn wa l'áti wá ní ìdákẹ́-rọ́rọ́, àti bí pàápàá ní àárín-gbungbun ìgbésí ayé tí ọwọ́ wá kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́, a sì lè ni àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
More