Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́: Atọ́na tí ó rọrùn sí Àwọn Àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́Àpẹrẹ

Dúró Jẹ́ẹ́: Níbo Ni Ọgbà Rẹ Wà?
Ní inú ẹsẹ Bíbélì tí a kà yìí, a kà nípa ohun tí Ọlọ́run ní ní ọkàn láti dá ayé àti ọ̀run: ní ibi tí ó ti ń rìn, tí ó sì ń bá Ádámù àti Éfà sọ ọ̀rọ̀ déédéé.
Gbólóhùn àgbàyanu kan wà ní inú Sáàmù 46:10 tí ó sọ wípé 'Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run'
Ó jẹ́ ìkésíni sí ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ìmọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó ti wà jákèjádò ìtàn.
Mo sábà máa ń dìde ní àárọ̀, mo máa ń mu kọfí, mo máa ń mú ìwé ìjíròrò mi, Bíbélì mi àti àwọn ìwé mi, mo sì máa ń jókòó sí orí àga kan náà ní igun yàrá ìjókòó mi. Mo máa ń gbé ara mi ró, mo sì máa ń wá ààyè láti wà ní ibì tí ó máa jẹ́ kí n lè bá Ọlọ́run pàdé.
Mo gbà gbọ́ pé àdúrà—ìfọkànsin fún àjọṣe, ìbápàdé àti ìjíròrò pẹ̀lú Ọlọ́run— ni orísun gbogbo ohun tí a bá ń ṣe. Ìgbé ayé tí kò ní ìtumọ̀ kankan á ní ìtumọ̀ nínú àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. A máa ń mú kí àjọṣe yìí ní àgbára sí i ní inú ìjọ àti nínú iṣẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, a tún lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ní àgbára sí i tí a bá ń gbé ìgbésí ayé tẹ̀mí.
Bí Ádámù àti Éfà ṣe ń bá Ọlọ́run rìn ní ojoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe lè túbọ̀ sún mọ́-Ọn tí a bá ń lo àkókò ìdákẹ́jẹ́, ìyẹn ni pé tí a bá ń gba àdúrà, tí a ń ka Bíbélì tí a sì ń ṣe àṣàrò lé orí ohun tí a kà, a yíò túbọ̀ sún mọ́-Ọn. Àkókò ìdákẹ́jẹ́ jẹ́ ìgbà tí a kò bá Ọlọ́run sọ ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n a tún máa ń béèrè ní ọwọ́ Rẹ̀ pé kí ó bá wa sọ ọ̀rọ̀.
Àwọn àkókò ìdákẹ́jẹ́ jẹ́ láti se ìbápàdé Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ ìbápàdé yíì túmọ sí láti 'pàdé pẹ̀lú'.
Ìfọkànsìn ṣe pàtàkì. Ní inú Bíbélì, gbogbo nǹkan bẹ̀ẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpàdé déédéé ní ibi kan pàtó àti ní àkókò kan pàtó.
Gẹ́gẹ́ bí a ti kà ní òní, ibi àkọ́kọ́ tí ènìyàn ti pàdé Ọlọ́run bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní inú ọgbà kan.
Ọlọ́run máa ń rìn ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú Adamu àti Efa nínú ìdùnú! Èyí ni èrò àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run ní ní ìgbà tí Ó dá ayé.
Fi ojú inú bí wọ́n ṣe ń dúró, tí wọ́n ń fi etí sílẹ̀, tí wọ́n ń dákẹ́, tí wọ́n sì ń múra tán láti máa bá Ọlọ́run sọ ọ̀rọ̀. Èyí ni bí ìgbà ìdákẹ́jẹ àkọ́kọ́ ṣe rí.
A nílò láti fi ìfọkànsìn wá ààyè ní inú ayé wa fún ìpàdé pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìgbà gbogbo, ààyè láti rìn, bá a sọ ọ̀rọ̀, àti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀.
Níbo ni ọgbà rẹ wà?
Ọ̀rọ̀ Héébùrù fún ‘ọgbà’ ni ‘gannah’, èyí túmọ̀ sí ‘ibi tí a fi bò tàbí ibi ìkọ̀kọ̀’. Gbogbo wa nílò ibi ìkọ̀kọ̀ láti lè bá Ọlọ́run pàdé.
Àwọn ìgbà máa yí padà, àkókò yóò sì wà ní ìgbà tí èyí yóò rọrùn ju àwọn ìgbà míràn lọ. Ó ṣeé ṣe kí o ní wákàtí kan ní ojoojúmọ́ tàbí díẹ̀ nínú àkókò tí ó wà ní àárín ìrìnàjò ilé-ẹ̀kọ́. Ó yé Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Ó túbọ̀ ń fẹ́ kí o wá sí ọ̀dọ Rẹ̀.
Níbo ni ibi ìdákẹ́jẹ àti ìpàdé rẹ wà?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Dúró Jẹ́ẹ́. Fún àwọn kan, àwọn ọ̀rọ̀ méjì wọ̀nyí jẹ́ ìpè sì àkíyèsí l'áti sinmi díẹ̀. Fún àwọn elòmíràn, wọn ní ìmọ̀lára pé kò ṣeé ṣe rárá ni, tí kò tilẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ bi ariwo ìgbòkègbodò ayé ṣe ń pọ̀ si, tàbí ki a kàn sọ wípé ó nira púpọ̀ l'áti ṣe. Brian Heasley ṣe àpèjúwe pé kí í ṣe pé kí a dúró ní àìmìrá fún àwọn ọkàn wa l'áti wá ní ìdákẹ́-rọ́rọ́, àti bí pàápàá ní àárín-gbungbun ìgbésí ayé tí ọwọ́ wá kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́, a sì lè ni àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
More