Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́: Atọ́na tí ó rọrùn sí Àwọn Àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́Àpẹrẹ

Dúró Jẹ́: Agbára Ìwé Mímọ́
Agbára tí Bíbélì ní ṣàrà ọ̀tọ̀: ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún ẹsẹ̀ wa, ó sì ń tọ́ wa sọ́nà (Ps 119:105)
Bíbélì ṣe pàtàkì gan-an fún àkókò ìdákẹ́ rọ́rọ́ tó múná dóko.
O kò lè ya àwọn méjèèjì sọ́tọ̀. O gbọ́dọ̀ fi ọkàn àdúrà ka Bíbélì, o sì gbọ́dọ̀ fi Bíbélì ṣe atọ́kùn àdúrà bákannáà. Èwo ló ṣáájú kọ́ ló ṣe pàtàkì; o lè kọ́kọ́ kàá kó o tó gbàdúrà, nígbà míràn ẹ̀wẹ̀ o lè kà á lẹ́yìn tí o bá ti gbàdúrà tán. Àmọ́ kí Bíbélì wà nítòsí nígbàkigbà tí o bá ń gbàdúrà.
A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Bíbélì ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa, ká jẹ́ kó máa pè wá níjà, kó máa fún wa ní ìṣírí, kó sì máa darí ìgbé ayé wa.
Ilé Ìkàwé gbogbogbò ti New York, jẹ́ ibùgbé fún Bíbélì Gutenberg kan ìwé àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ gbòógì tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ìlú alawo funfun, ó jẹ́ ìwé àgbàyanu kan tí kò ṣeé díye lé. Wọ́n sọ pé nígbà tí ìwé náà dé ìlú New York lọ́dún 1847, nígbà tí wọ́n gbé e gba body ẹrù kọjá, gbogbo èèyàn ló dìde dúró tí wọ́n sì bọ́ fìlà ní ìbọ̀wọ̀ fún ìwé àgbàyanu yìí.
Ní sínágọ́gù àwọn Júù, àwọn rábì máa ń jókòó láti wàásù àmọ́ wọ́n máa ń dìde láti ka Ìwé Mímọ́. Jésù náà sì ṣe bẹ́ẹ̀; a kà á nínú Lúùkù 4:16, “Ó dìde láti kàwé.” Àṣà Hébérù jẹ́ èyítí ó gbé Ìwé Mímọ́—Ìwé Tórà—gẹ́gẹ́ pẹ̀lú Ìbọ̀wọ̀fún tíkò lẹ́gbẹ́.
Nígbà tí mo bá ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ńṣe ni mo máa ń ṣí fìlà kúrò, tí màá sì dúró láti fi ọ̀wọ̀ hàn fún ohun tó wà lórí ẹsẹ̀ mi, lẹ́bàá kọfí mi!
Nínú Sáàmù 1, onísáàmù náà gbà wá níyànjú láti máa ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà tọ̀sán tòru. Kí ni ọ̀rọ̀ náà "àṣàrò" túmọ̀ sí fún ọ?
Fún àwọn kan, kó yàtọ̀ sí ti jinlẹ̀ àwọn tí wọ́n oní ẹ̀kọ́ àṣàrò ti Ìlà-Oòrùn tí wọ́n kà sí ohun tí ó léwu, àwọn kan sì ri bí èyí tí kò ní ìtumọ̀ sí wọn. Ní tòótọ́, ṣíṣe àṣàrò fi ìdí múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ Kristẹni.
Ọ̀rọ̀ náà, "ṣàṣàrò" tí a lò nínú sáàmù yìí túmọ̀ sí "jí jẹ ẹnu wúyẹ́", ó sì dà bí ìgbà tí àdàbà bá ń dún, tí ó ńhu pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́. Ọ̀rọ̀ kan náà yìí ni wọ́n tún máa ń lò láti fi ṣàpèjúwe bí ẹran ṣe máa ń jẹun— bí màálù ti í ma jẹ koríko kúnná kí ó bàa lè rí gbogbo èròjà aṣaralóore tó wà nínú rẹ̀.
Àbí, bóyá, ó ní ìtumọ̀ síi láti rò ó bíi mímu àdídùn líle dípò ká rúun jẹ; bí a bá ń mu àdídùn líle, yóò mú kí gbogbo ohun dídùn rẹ̀ bọ́ sí ẹnu wa, a ó sì wá gbádùn rẹ̀ déibitó ní àpẹẹrẹ. Nígbà míì, tí mo bá ń ka Bíbélì mi ójoojúmọ́, mo lè ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ní gburu dípò kí n mú sùúrù láti ṣàṣàrò lórí ohun tí mò ń kà kí n sì lóye rẹ̀ dáadáa.
Àṣàrò Bíbélì kò ní ṣe pẹ̀lú kí á fá èrò inú dànù, ṣùgbọ́n fífi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún inú ọkàn àti èrò inú ẹni.
Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ láti ṣàṣàrò lórí Bíbélì ni pé ká há a sórí.
Bíbélì yóò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ọkàn, tí a bá fi ṣe àkọ́sórí. A sábà máa ń rí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lórí àwọn ẹ̀rọ tó sún mọ́ wa jù lọ bótilẹ̀jẹ́pé pé ohun tó yẹ kí a ṣe ni pé ká fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa mọ́ sínú ọkàn wa, a lè ṣe èyí nípa kíkọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí. Mímọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sórí máa ń jẹ́ ká lóye rẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ ká lóye rẹ̀ láti ọkàn wá.
Àwọn ẹsẹ̀ kan wà tí ó yẹ kí a ní láti ràn wá lọ́wọ́ nígbàtí a kò bá rí oorun sùn lálẹ́ nígbàtí a bá dojú kọ àwọn ìṣòro nígbàtí a bá ń gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíràn nígbàtí a bá dá wà nígbàtí a bá wà nínú àdánwò, àwọn ẹsẹ̀ tí a ti há sórí yóò gbé wa ró, yóò sì fún wa lókun ní gbogbo ìgbésí ayé wa.
Yan ẹsẹ Bíbélì kan lónìí kí o sì pinnu pé wàá há a sórí lọ́sẹ̀ yìí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Dúró Jẹ́ẹ́. Fún àwọn kan, àwọn ọ̀rọ̀ méjì wọ̀nyí jẹ́ ìpè sì àkíyèsí l'áti sinmi díẹ̀. Fún àwọn elòmíràn, wọn ní ìmọ̀lára pé kò ṣeé ṣe rárá ni, tí kò tilẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ bi ariwo ìgbòkègbodò ayé ṣe ń pọ̀ si, tàbí ki a kàn sọ wípé ó nira púpọ̀ l'áti ṣe. Brian Heasley ṣe àpèjúwe pé kí í ṣe pé kí a dúró ní àìmìrá fún àwọn ọkàn wa l'áti wá ní ìdákẹ́-rọ́rọ́, àti bí pàápàá ní àárín-gbungbun ìgbésí ayé tí ọwọ́ wá kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́, a sì lè ni àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
More