Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́: Atọ́na tí ó rọrùn sí Àwọn Àkókò Ìdákẹ́rọ́rọ́Àpẹrẹ

Dúró Jẹ́: Kọ́ bí A ti ń wo ǹkan ní Àwòyanu
Nínú àyọkà ti òní, a ka ìtàn nípa ìbápàdé tí Jákọ́bù ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Lẹ́yìn rẹ, ó sọ wípé: “Dájúdájú Ọlọ́run wà ní ibí yìí, èmi kò sì mọ̀.”(Jẹ́nẹ́sísì 28:10–17)
“Dájúdájú Ọlọ́run wà ní ibí yìí, èmi kò sì mọ̀.” N kò ní fẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí mi, láti wo àwọn ọjọ́, oṣù, tàbí ọdún ọjọ́ ayé mi tó ti kọjá sẹ́yìn, kí n wá máa ronú wípé dájúdájú Ọlọ́run wà níbẹ̀, àmọ́ n kò ṣe àkíyèsí.
Èròńgbà wa, àǹfààní tí a ní láti wo ǹkan ní àwòyanu àti níní sùúrù láti ṣe àròjinlẹ̀ lórí ǹkan tí a rí, tàbí ṣiṣẹ́ àkíyèsí rẹ̀, yóò túbọ̀ mú wa mọ ìwàláàyè Ọlọ́run ní ọjọ́ ayé wa gbogbo.
Ọ̀rọ̀ yẹn 'èròńgbà' wá láti inú ọ̀rọ̀-ìṣe kan nínú èdè Látìn imaginari tó túmọ̀ sí ‘ya àwòrán lọ́kàn rẹ’. Yóò mú ǹkan rọrùn tí o bá fi àwòrán ara rẹ̀ sínú ìtàn tí Ọlọ́run tí kòlẹ́gbẹ́.
A lè mú èròńgbà wa ṣiṣẹ́ nípa mímọ rírì gbogbo ǹkan tí ó yí wa ká, gbogbo ǹkan tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá. Èyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkíyèsí Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn ǹkan tí a kò kà sí, ó lè mú ọ gbé ìgbé ayé àwòyanu.
A lè wá mú èyí wá si ibi àkókò ìdákẹ́jẹ́ wa, a lè ṣe àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, a lè ronú nípa rẹ̀, a sì lè ṣe ìdúpẹ́ fún un.
Láti inú àwòyanu ni a ti bí ìjọsìn.
Ní Jẹ́nẹ́sísì, a kà wípé Ọlọ́run rí gbogbo ǹkan tí Ó dá, wípé dáradára ni.
Ọlọ́run ṣẹ́ àròjinlẹ̀ lórí ìṣẹ̀dá Ó sì wá rí i wípé dáradára ni.
Àròjinlẹ̀ wa kò gbọdọ́ dáwọ́ dúró lórí Bíbélì nìkan ó yẹ kí ó tún dá lórí àwọn ìṣẹ̀dá tó yí wa ká. Ìtọpinpin ojojúmọ́ yí lè ran àkókò ìdákẹ́jẹ́ wa lọ́wọ́.
Ṣé àwòrán tó gún régé láì ní àbùkù ló fẹ́ ma jà wá ní olè láti wo àwọn ǹkan tí a kò kà sí ní àwòyanu, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ìṣẹ̀dá kò wá dùn ún wò mọ́ àyàfi tí a bá wòó èyí tí ẹ̀rọ-ìléwọ́ wa ti dán mọ́rán?
Àwọn àwòrán tó rẹwà lórí ẹ̀rọ-ìléwọ́ yìí lè dí wa lọ́wọ́ láti ṣe àwòyanu: bí a kò sì ṣọ́ra, bí a ṣe mọ rírì ohun tó lẹ́'wà sí lè padà mẹ́hẹ.
Ẹwà wà nínú oúnjẹ tí a gbọ́ nílé, nínú ara tó ti hun jọ, nínú ojú sánmọ̀ tí a fi èéfín ẹ̀rọ ilé iṣẹ́ ńláńlá bàjẹ́. Ẹwà wà ní aṣálẹ̀ tí kò mú èso wá. Ẹwà wà ní àwọn ilé ìwòsàn. Ẹwà wá nínú irin tóti dóògún.
A ní láti tẹ'sẹ̀ dúró, ká bojú wo ẹwà náà, ká sì ṣe àwòyanu.
Ó yẹ kí àkókò ìdákẹ́jẹ́ wa ré kọjá ìhùwàsí òde ara wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Ó jẹ́ ibi tí a ti ń ṣe àròjinlẹ̀ pẹ̀lú àwòyanu, pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìyanu nípa ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti sọ, ṣe àti èyí tí Ó ṣẹ̀dá.
Ṣe àṣàrò ọjọ́ òní kí o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìṣẹ̀dá Rẹ̀. Ó lè wù ọ́ láti ṣe àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ tó bá ṣeé ṣe.
Kíni ǹkan tí o ti rí lónìí tó mú ọ wo àwòyanu? Ibo ni o ti ṣe àbápàdé ẹwà nínú ìṣẹ̀dá?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Dúró Jẹ́ẹ́. Fún àwọn kan, àwọn ọ̀rọ̀ méjì wọ̀nyí jẹ́ ìpè sì àkíyèsí l'áti sinmi díẹ̀. Fún àwọn elòmíràn, wọn ní ìmọ̀lára pé kò ṣeé ṣe rárá ni, tí kò tilẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ bi ariwo ìgbòkègbodò ayé ṣe ń pọ̀ si, tàbí ki a kàn sọ wípé ó nira púpọ̀ l'áti ṣe. Brian Heasley ṣe àpèjúwe pé kí í ṣe pé kí a dúró ní àìmìrá fún àwọn ọkàn wa l'áti wá ní ìdákẹ́-rọ́rọ́, àti bí pàápàá ní àárín-gbungbun ìgbésí ayé tí ọwọ́ wá kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́, a sì lè ni àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
More