Johanu 6:61, 62, 63, 64, 65, 66, 67, 68, 69, 70, 71
Johanu 6:61 YCB
Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí?
Johanu 6:62 YCB
Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí ọmọ ènìyàn ń gòkè lọ sí ibi tí ó gbé ti wà rí ńkọ́?
Johanu 6:63 YCB
Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú.
Johanu 6:64 YCB
Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́.” Nítorí Jesu mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn.
Johanu 6:65 YCB
Ó sì wí pé, “Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.”
Johanu 6:66 YCB
Nítorí èyí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ padà sẹ́yìn, wọn kò sì bá a rìn mọ́.
Johanu 6:67 YCB
Nítorí náà Jesu wí fún àwọn méjìlá pé, “Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ lọ bí?”
Johanu 6:68 YCB
Nígbà náà ni Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ? Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.
Johanu 6:69 YCB
Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”
Johanu 6:70 YCB
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya èṣù?”
Johanu 6:71 YCB
(Ó ń sọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni ọ̀kan nínú àwọn méjìlá: nítorí pé òun ni ẹni tí yóò fi í hàn.)