YouVersion Logo
Search Icon

Gẹn 7

7
Ìkún Omi
1OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi.
2Ninu onirũru ẹran ti o mọ́ meje meje ni ki iwọ ki o mu wọn, ati akọ ati abo rẹ̀; ati ninu ẹran ti kò mọ́ meji meji, ati akọ ati abo rẹ̀.
3Ninu ẹiyẹ oju-ọrun pẹlu ni meje meje, ati akọ ati abo; lati dá irú si lãye lori ilẹ gbogbo.
4Nitori ijọ́ meje si i, emi o mu òjo rọ̀ si ilẹ li ogoji ọsán ati li ogoji oru; ohun alãye gbogbo ti mo dá li emi o parun kuro lori ilẹ.
5Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u.
6Noa si jẹ ẹni ẹgbẹta ọdún nigbati kíkun-omi de si aiye.
7Noa si wọle, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati aya awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, sinu ọkọ̀, nitori kíkun-omi.
8Ninu ẹranko mimọ́, ati ninu ẹranko ti kò mọ́, ati ninu ẹiyẹ, ati ninu ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ,
9Nwọn wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀ ni meji meji, ati akọ ati abo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun Noa.
10O si ṣe ni ijọ́ keje, bẹ̃ni kíkun-omi de si aiye.
11Li ẹgbẹta ọdún ọjọ́ aiye Noa, li oṣù keji, ni ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù, li ọjọ́ na ni gbogbo isun ibú nla ya, ati ferese iṣàn omi ọrun si ṣí silẹ.
12Òjo na si wà lori ilẹ li ogoji ọsán on ogoji oru.
13Li ọjọ́ na gan ni Noa wọ̀ inu ọkọ̀, ati Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti, awọn ọmọ Noa, ati aya Noa, (ati awọn aya ọmọ rẹ̀ mẹta pẹlu wọn).
14Awọn, ati gbogbo ẹranko ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin gbogbo ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ nla ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ abiyẹ.
15Nwọn si wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀, meji meji ninu ẹda gbogbo, ninu eyiti ẹmi ìye wà.
16Awọn ti o si wọle lọ, nwọn wọle ti akọ ti abo ninu ẹdá gbogbo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. OLUWA si sé e mọ́ ile.
17Ikún-omi si wà li ogoji ọjọ́ lori ilẹ; omi si nwú si i, o si mu ọkọ̀ fó soke, o si gbera kuro lori ilẹ.
18Omi si gbilẹ, o si nwú si i gidigidi lori ilẹ; ọkọ̀ na si fó soke loju omi.
19Omi si gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti o wà ni gbogbo abẹ ọrun, li a bò mọlẹ.
20Omi gbilẹ soke ni igbọ́nwọ mẹ̃dogun; a si bò gbogbo okenla mọlẹ.
21Gbogbo ẹdá ti nrìn lori ilẹ si kú, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ti ẹranko, ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ati gbogbo enia:
22Gbogbo ohun ti ẹmi ìye wà ni ihò imu rẹ̀, gbogbo ohun ti o wà ni iyangbẹ ilẹ si kú.
23Ohun alãye gbogbo ti o wà lori ilẹ li a si parun, ati enia, ati ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun, nwọn si run kuro lori ilẹ. Noa nikan li o kù, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀.
24Omi si gbilẹ li aiye li ãdọjọ ọjọ́.

Currently Selected:

Gẹn 7: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy