YouVersion Logo
Search Icon

Gẹn 31

31
Jakọbu Sá kúrò lọ́dọ̀ Labani
1O SI gbọ́ ọ̀rọ awọn ọmọ Labani ti nwọn wipe, Jakobu kó nkan gbogbo ti iṣe ti baba wa; ati ninu ohun ti iṣe ti baba wa li o ti ní gbogbo ọrọ̀ yi.
2Jakobu si wò oju Labani, si kiyesi i, kò ri si i bi ìgba atijọ.
3OLUWA si wi fun Jakobu pe, Pada lọ si ilẹ awọn baba rẹ, ati si ọdọ awọn ara rẹ; emi o si pẹlu rẹ.
4Jakobu si ranṣẹ o si pè Rakeli on Lea si pápa si ibi agbo-ẹran rẹ̀,
5O si wi fun wọn pe, Emi wò oju baba nyin pe, kò ri si mi bi ìgba atijọ; ṣugbọn Ọlọrun baba mi ti wà pẹlu mi.
6Ẹnyin si mọ̀ pe gbogbo agbara mi li emi fi sìn baba nyin.
7Baba nyin si ti tàn mi jẹ, o si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa: ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ ki o pa mi lara.
8Bi o ba si wi bayi pe, Awọn abilà ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí abilà: bi o ba si wi bayi, Awọn oni-tototó ni yio ṣe ọ̀ya rẹ; gbogbo awọn ẹran a si bí oni-tototó.
9Bẹ̃li Ọlọrun si gbà ẹran baba nyin, o si fi wọn fun mi.
10O si ṣe li akokò ti awọn ẹran yún, mo si gbé oju mi soke, mo si ri li oju-alá, si kiyesi i, awọn obukọ ti o ngùn awọn ẹran jẹ́ oni-tototó, abilà, ati alamì.
11Angeli Ọlọrun si sọ fun mi li oju-alá pe, Jakobu: emi si wipe, Emi niyi.
12O si wipe, Gbé oju rẹ soke nisisiyi, ki o si wò, gbogbo awọn obukọ ti ngùn awọn ẹran li o ṣe tototó, abilà, ati alamì: nitori ti emi ti ri ohun gbogbo ti Labani nṣe si ọ.
13Emi li Ọlọrun Beteli, nibiti iwọ gbé ta oróro si ọwọ̀n, nibiti iwọ gbè jẹ́ ẹjẹ́ fun mi: dide nisisiyi, jade kuro ni ilẹ yi, ki o si pada lọ si ilẹ ti a bi ọ.
14Rakeli ati Lea si dahùn nwọn si wi fun u pe, Ipín, tabi ogún kan ha tun kù fun wa mọ́ ni ile baba wa?
15Alejò ki on nkà wa si? nitori ti o ti tà wa; o si ti mù owo wa jẹ gúdu-gudu.
16Nitori ọrọ̀ gbogbo ti Ọlọrun ti gbà lọwọ baba wa, eyinì ni ti wa, ati ti awọn ọmọ wa: njẹ nisisiyi ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun ọ, on ni ki o ṣe.
17Nigbana ni Jakobu dide, o si gbé awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn aya rẹ̀ gùn ibakasiẹ.
18O si kó gbogbo ẹran rẹ̀ lọ, ati gbogbo ẹrù ti o ní, ẹran ti o ní fun ara rẹ̀, ti o ní ni Padan-aramu, lati ma tọ̀ Isaaki baba rẹ̀ lọ ni ilẹ Kenaani.
19Labani si lọ irẹrun agutan rẹ̀: Rakeli si ti jí awọn ere baba rẹ̀ lọ.
20Jakobu si tàn Labani ara Siria jẹ, niti pe kò wi fun u ti o fi salọ.
21Bẹ̃li o kó ohun gbogbo ti o ní salọ: o si dide, o si kọja odò, o si kọju rẹ̀ si oke Gileadi.
Labani Lépa Jakọbu
22A si wi fun Labani ni ijọ́ kẹta pe, Jakobu salọ.
23O si mú awọn arakunrin rẹ̀ pẹlu rẹ̀, o si lepa rẹ̀ ni ìrin ijọ́ meje: o si bá a li oke Gileadi.
24Ọlọrun si tọ̀ Labani, ara Siria wá li oru li oju-alá, o si wi fun u pe, Kiyesi ara rẹ, ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu.
25Nigbana ni Labani bá Jakobu. Jakobu ti pa agọ́ rẹ̀ li oke na: ati Labani pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ dó li oke Gileadi.
26Labani si wi fun Jakobu pe, Kini iwọ ṣe nì, ti iwọ tàn mi jẹ ti iwọ si kó awọn ọmọbinrin mi lọ bi ìgbẹsin ti a fi idà mú?
27Ẽṣe ti iwọ fi salọ li aṣíri, ti iwọ si tàn mi jẹ; ti iwọ kò si wi fun mi ki emi ki o le fi ayọ̀ ati orin, ati ìlu, ati dùru, sìn ọ;
28Ti iwọ kò si jẹ ki emi fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin mi li ẹnu? iwọ ṣiwere li eyiti iwọ ṣe yi.
29O wà ni ipa mi lati ṣe nyin ni ibi: ṣugbọn Ọlọrun baba nyin ti sọ fun mi li oru aná pe, Kiyesi ara rẹ ki iwọ ki o máṣe bá Jakobu sọ rere tabi buburu.
30Ati nisisiyi, iwọ kò le ṣe ailọ, nitori ti ọkàn rẹ fà gidigidi si ile baba rẹ, ṣugbọn ẽhaṣe ti iwọ fi jí awọn oriṣa mi lọ?
31Jakobu si dahùn o si wi fun Labani pe, Nitori ti mo bẹ̀ru ni: nitori ti mo wipe, iwọ le fi agbara gbà awọn ọmọbinrin rẹ lọwọ mi.
32Lọwọ ẹnikẹni ti iwọ ba ri awọn oriṣa rẹ ki o máṣe wà lãye: li oju awọn arakunrin wa wọnyi, wá ohun ti iṣe tirẹ lọdọ mi, ki o si mú u si ọdọ rẹ. Jakobu kò sa mọ̀ pe Rakeli ti jí wọn.
33Labani si wọ̀ inu agọ́ Jakobu lọ, ati inu agọ́ Lea, ati inu agọ́ awọn iranṣẹbinrin mejeji; ṣugbọn kò ri wọn. Nigbana li o jade kuro ninu agọ́ Lea, o si wọ̀ inu agọ́ Rakeli lọ.
34Rakeli si gbé awọn ere na, o si fi wọn sinu gãri ibakasiẹ, o si joko le wọn. Labani si wá gbogbo agọ́ ṣugbọn kò ri wọn.
35O si wi fun baba rẹ̀ pe, Oluwa mi, máṣe jẹ ki o bi ọ ninu nitori ti emi kò le dide niwaju rẹ; nitori ti iṣe obinrin mbẹ lara mi. O si wá agọ́ kiri, ṣugbọn kò ri awọn ere na.
36Inu si bi Jakobu, o si bá Labani sọ̀: Jakobu si dahùn o wi fun Labani pe, Kini irekọja mi? kili ẹ̀ṣẹ mi ti iwọ fi lepa mi wìriwiri bẹ̃?
37Njẹ bi iwọ ti tú ẹrù mi gbogbo, kili iwọ ri ninu gbogbo nkan ile rẹ? gbé e kalẹ nihinyi niwaju awọn arakunrin rẹ, ki nwọn ki o le ṣe idajọ rẹ̀ fun awa mejeji.
38Ogún ọdún yi ni mo ti wà lọdọ rẹ; agutan rẹ ati ewurẹ rẹ kò sọnù, agbo ọwọ́-ẹran rẹ li emi kò si pajẹ.
39Eyiti ẹranko fàya emi kò mú u fun ọ wá; emi li o gbà òfo rẹ̀; li ọwọ́ mi ni iwọ bère rẹ̀, a ba jí i li ọsán, a ba jí i li oru.
40Bayi ni mo wà; ongbẹ ngbẹ mi li ọsán, otutù si nmu mi li oru: orun mi si dá kuro li oju mi.
41Bayi li o ri fun mi li ogún ọdún ni ile rẹ; mo sìn ọ li ọdún mẹrinla nitori awọn ọmọbinrin rẹ mejeji, ati li ọdún mẹfa nitori ohun-ọ̀sin rẹ: iwọ si pa ọ̀ya mi dà nigba mẹwa.
42Bikoṣe bi Ọlọrun baba mi, Ọlọrun Abrahamu, ati ẹ̀ru Isaaki ti wà pẹlu mi, nitõtọ ofo ni iwọ iba rán mi jade lọ. Ọlọrun ri ipọnju mi, ati lãla ọwọ́ mi, o si ba ọ wi li oru aná.
Labani ati Jakọbu Dá Majẹmu
43Labani si dahùn o si wi fun Jakobu pe, Awọn ọmọbinrin wọnyi, awọn ọmọbinrin mi ni, ati awọn ọmọ wọnyi, awọn ọmọ mi ni, ati awọn ọwọ́-ẹran wọnyi ọwọ́-ẹran mi ni, ati ohun gbogbo ti o ri ti emi ni: kili emi iba si ṣe si awọn ọmọbinrin mi wọnyi loni, tabi si awọn ọmọ wọn ti nwọn bí?
44Njẹ nisisiyi, wá, jẹ ki a bá ara wa dá majẹmu, temi tirẹ; ki o si ṣe ẹrí lãrin temi tirẹ.
45Jakobu si mú okuta kan, o si gbé e ró ṣe ọwọ̀n.
46Jakobu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ẹ ma kó okuta jọ; nwọn si kó okuta jọ, nwọn si ṣe òkiti: nwọn si jẹun nibẹ̀ lori òkiti na.
47Labani si sọ orukọ rẹ̀ ni Jegari-Sahaduta: ṣugbọn Jakobu sọ ọ ni Galeedi.
48Labani si wipe, Òkiti yi li ẹri lãrin temi tirẹ loni. Nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Galeedi:
49Ati Mispa; nitori ti o wipe, Ki OLUWA ki o ma ṣọ́ temi tirẹ nigbati a o yà kuro lọdọ ara wa.
50Bi iwọ ba pọ́n awọn ọmọbinrin mi li oju, tabi bi iwọ ba fẹ́ aya miran pẹlu awọn ọmọbinrin mi, kò sí ẹnikan pẹlu wa; wò o, Ọlọrun li ẹlẹri lãrin temi tirẹ.
51Labani si wi fun Jakobu pe, Wò òkiti yi, si wò ọwọ̀n yi, ti mo gbé ró lãrin temi tirẹ.
52Òkiti yi li ẹri, ọwọ̀n yi li ẹri, pe emi ki yio rekọja òkiti yi sọdọ rẹ; ati pe iwọ ki yio si rekọja òkiti yi ati ọwọ̀n yi sọdọ mi fun ibi.
53Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Nahori, Ọlọrun baba wọn, ni ki o ṣe idajọ lãrin wa. Jakobu si fi ẹ̀ru Isaaki baba rẹ̀ bura.
54Nigbana ni Jakobu rubọ lori oke na, o si pè awọn arakunrin rẹ̀ wá ijẹun: nwọn si jẹun, nwọn si fi gbogbo oru ijọ́ na sùn lori oke na.
55Ni kutukutu owurọ̀ Labani si dide, o si fi ẹnu kò awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀ li ẹnu, o si sure fun wọn: Labani si dide, o si pada lọ si ipò rẹ̀.

Currently Selected:

Gẹn 31: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy