YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 93

93
Ọlọrun Ọba
1OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù;
OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀,
ó sì di agbára ni àmùrè.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
kò sì ní yẹ̀ laelae.
2A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae;
láti ayérayé ni o ti wà.
3Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA,
ibú omi gbé ohùn wọn sókè,
ó sì ń sán bí ààrá.
4OLUWA lágbára lókè!
Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ,
ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ.
5Àwọn òfin rẹ kìí yipada,
ìwà mímọ́ ni ó yẹ ilé rẹ títí lae, OLUWA.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 93: YCE

Highlight

Copy

Compare

Share

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in