YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 114

114
Orin Ìrékọjá
1Nígbà tí Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti,
tí àwọn ọmọ Jakọbu jáde kúrò láàrin àwọn tí ń sọ èdè àjèjì,
2Juda di ilé mímọ́ rẹ̀,
Israẹli sì di ìjọba rẹ̀.#Eks 12:51
3Òkun rí i, ó sá,
Jọdani rí i, ó pada sẹ́yìn.#(a) Eks 114:21 (b) Joṣ 3:16
4Àwọn òkè ńláńlá ń fò bí àgbò,
àwọn òkè kéékèèké ń fò bí ọmọ aguntan.
5Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun?
Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani?
6Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò?
Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan?
7Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀,
wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu.
8Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi,
tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.#Eks 17:1-7; Nọm 20:2-13

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 114: YCE

Highlight

Copy

Compare

Share

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in