AISAYA 15
15
OLUWA yóo Pa Moabu Run
1Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa ilẹ̀ Moabu nìyí:#Ais 25:10-12; Jer 48: 1-47; Isi 25:8-11; Amo 2:1-3; Sef 2:8-11
Nítorí tí a wó ìlú Ari ati Kiri lulẹ̀ ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo,
ó parí fún Moabu.
2Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún.
Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba.
Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn.
3Wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora ní ìta gbangba.
Gbogbo wọn dúró lórí òrùlé ilé wọn,
ati ní gbogbo gbàgede, wọ́n ń pohùnréré ẹkún,
omijé sì ń dà lójú wọn.
4Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara,
àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn;
nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún,
ọkàn rẹ̀ sì wárìrì.
5Ọkàn mi sọkún fún Moabu;
àwọn ìsáǹsá rẹ̀ sá lọ sí Soari ati Egilati Ṣeliṣiya.
Ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Luhiti, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ,
wọ́n sì ń kígbe arò bí wọ́n tí ń lọ sí Horonaimu.
6Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀,
koríko ibẹ̀ gbẹ;
àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́.
7Nítorí náà àwọn ohun tí wọ́n ní lọpọlọpọ
ati ohun ìní tí wọn ti kó jọ,
ni wọ́n kó lọ sí ìkọjá odò Wilo.
8Nítorí ariwo kan ti gba gbogbo ilẹ̀ Moabu kan,
ẹkún náà dé Egilaimu,
ìpohùnréré náà sì dé Beerelimu.
9Nítorí odò Diboni kún fún ẹ̀jẹ̀,
sibẹsibẹ n óo jẹ́ kí ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dé bá a.
Kinniun ni yóo pa àwọn ará Moabu tí ó bá ń sá lọ
ati àwọn eniyan tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà.
Currently Selected:
AISAYA 15: YCE
Highlight
Share
Copy

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Highlight
Share
Copy

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010