YouVersion Logo
Search Icon

JẸNẸSISI 48

48
Jakọbu Súre fún Efuraimu ati Manase
1Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún Josẹfu pé ara baba rẹ̀ kò yá, Josẹfu bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Manase ati Efuraimu, lọ́wọ́ lọ bẹ baba rẹ̀ wò. 2Nígbà tí wọ́n sọ fún Jakọbu pé Josẹfu ọmọ rẹ̀ dé, ó ṣe ara gírí, ó jókòó lórí ibùsùn rẹ̀. 3Jakọbu sọ fún Josẹfu pé, “Ọlọrun Olodumare farahàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì súre fún mi. 4Ó ní, ‘N óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ ẹ̀yà, ati pé àwọn ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ náà fún, yóo sì jẹ́ tiwọn títí ayé.’#Jẹn 28:13-14.
5“Tèmi ni àwọn ọmọkunrin mejeeji tí o bí ní ilẹ̀ Ijipti kí n tó dé, bí Reubẹni ati Simeoni ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ náà ni Manase ati Efuraimu jẹ́ tèmi. 6Àwọn ọmọ tí o bá tún bí lẹ́yìn wọn, ìwọ ni o ni wọ́n, ninu ogún tí ó bá kan Manase ati Efuraimu ni wọn yóo ti pín. 7Ìbànújẹ́ ni ó jẹ́ fún mi pé nígbà tí mò ń ti Padani-aramu bọ̀, Rakẹli kú lọ́nà, ní ilẹ̀ Kenaani, ibi tí ó dákẹ́ sí kò jìnnà pupọ sí Efurati. Lójú ọ̀nà Efurati náà ni mo sì sin ín sí.” (Efurati yìí ni wọ́n ń pè ní Bẹtilẹhẹmu.)#Jẹn 45:16-19
8Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó bèèrè pé, “Àwọn wo nìyí?”
9Josẹfu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ mi, tí Ọlọrun pèsè fún mi níhìn-ín ni wọ́n.”
Jakọbu bá wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí wọ́n súnmọ́ mi kí n lè súre fún wọn.” 10Ogbó ti mú kí ojú Israẹli di bàìbàì ní àkókò yìí, kò sì ríran dáradára mọ́. Josẹfu bá kó wọn súnmọ́ baba rẹ̀, baba rẹ̀ dì mọ́ wọn, ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu. 11Ó wí fún Josẹfu pé, “N kò lérò pé mo tún lè fi ojú kàn ọ́ mọ́, ṣugbọn Ọlọrun mú kí ó ṣeéṣe fún mi láti rí àwọn ọmọ rẹ.” 12Josẹfu bá kó wọn kúrò lẹ́sẹ̀ baba rẹ̀, òun gan-an náà wá dojúbolẹ̀ níwájú baba rẹ̀.
13Ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú Efuraimu, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ òsì baba rẹ̀, ó fi ọwọ́ òsì mú Manase, ó fà á súnmọ́ ẹ̀gbẹ́ ọwọ́ ọ̀tún baba rẹ̀. 14Ṣugbọn nígbà tí Israẹli na ọwọ́ rẹ̀ láti súre fún wọn, ó dábùú ọwọ́ rẹ̀ lórí ara wọn, ó gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efuraimu lórí, ó sì gbé ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bẹ́ẹ̀ ni Efuraimu ni àbúrò, Manase sì ni àkọ́bí.
15Ó bá súre fún Josẹfu, ó ní,
“Kí Ọlọrun tí Abrahamu ati Isaaki, baba mi, ń sìn bukun àwọn ọmọ wọnyi,
kí Ọlọrun náà tí ó ti ń tọ́ mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní yìí bukun wọn,
16kí angẹli tí ó yọ mí ninu gbogbo ewu bukun wọn;
kí ìrántí orúkọ mi, ati ti Abrahamu, ati ti Isaaki, àwọn baba mi, wà ní ìran wọn títí ayé,
kí atọmọdọmọ wọn pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”
17Nígbà tí Josẹfu rí i pé ọwọ́ ọ̀tún ni baba òun gbé lé Efuraimu lórí, kò dùn mọ́ ọn. Ó bá di ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé e kúrò lórí Efuraimu kí ó sì gbé e lórí Manase. 18Ó wí fún baba rẹ̀ pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, baba, eléyìí ni àkọ́bí, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé e lórí.”
19Ṣugbọn baba rẹ̀ kọ̀, ó ní, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀, òun náà yóo di eniyan, yóo sì di alágbára, ṣugbọn sibẹsibẹ àbúrò rẹ̀ yóo jù ú lọ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ yóo sì di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.”
20Ó bá súre fún wọn ní ọjọ́ náà, ó ní,#Heb 11:21.
“Orúkọ yín ni Israẹli yóo fi máa súre fún eniyan,
wọn yóo máa súre pé,
‘Kí Ọlọrun kẹ́ ọ bí ó ti kẹ́ Efuraimu ati Manase.’ ”
Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi Efuraimu ṣáájú Manase.
21Nígbà náà ni Israẹli sọ fún Josẹfu pé, “Àkókò ikú mi súnmọ́ etílé, ṣugbọn Ọlọrun yóo wà pẹlu rẹ, yóo sì mú ọ pada sí ilẹ̀ baba rẹ. 22Dípò kí n fún àwọn arakunrin rẹ ní Ṣekemu, tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkè, níbi tí mo jagun gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori, ìwọ ni mo fún.”

Currently Selected:

JẸNẸSISI 48: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy