JẸNẸSISI 42
BM
42
Àwọn Arakunrin Josẹfu Lọ Ra Ọkà ní Ijipti
1Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ijipti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Kí ni ẹ̀ ń wo ara yín fún? 2Ẹ wò ó, mo gbọ́ pé ọkà wà ní Ijipti, ẹ lọ ra ọkà wá níbẹ̀ kí ebi má baà pa wá kú.”#A. Apo 7:12 3Àwọn arakunrin Josẹfu mẹ́wàá bá lọ sí Ijipti, wọ́n lọ ra ọkà. 4Ṣugbọn Jakọbu kò jẹ́ kí Bẹnjamini, arakunrin Josẹfu bá àwọn arakunrin rẹ̀ lọ, nítorí ẹ̀rù ń bà á kí nǹkankan má tún lọ ṣẹlẹ̀ sí òun náà.
5Àwọn ọmọ Israẹli lọ ra ọkà pẹlu àwọn mìíràn tí wọ́n wá ra ọkà, nítorí kò sí ibi tí ìyàn náà kò dé ní ilẹ̀ Kenaani. 6Ní gbogbo àkókò yìí, Josẹfu ni gomina ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó ń ta ọkà fún àwọn eniyan láti gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ dé, wọ́n kí i, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 7Josẹfu rí àwọn arakunrin rẹ̀, ó sì mọ̀ wọ́n, ṣugbọn ó bá wọn sọ̀rọ̀ pẹlu ohùn líle bí ẹni pé kò mọ̀ wọ́n rí, ó ní, “Níbo ni ẹ ti wá?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni, oúnjẹ ni a wá rà.”
8Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Josẹfu mọ̀ dájú pé àwọn arakunrin òun ni wọ́n, wọn kò mọ̀ ọ́n. 9Josẹfu wá ranti àlá rẹ̀ tí ó lá nípa wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí ni yín, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.”#Jẹn 37:5-10 10Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o, oluwa mi, oúnjẹ ni àwa iranṣẹ rẹ wá rà. 11Ọmọ baba kan náà ni gbogbo wa, olóòótọ́ eniyan sì ni wá, a kì í ṣe amí.”
12Josẹfu tún sọ fún wọn pé, “N kò gbà, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.”
13Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Ọkunrin mejila ni àwa iranṣẹ rẹ, tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa wà lọ́dọ̀ baba wa nílé, ọ̀kan yòókù ti kú.”
14Ṣugbọn Josẹfu tẹnumọ́ ọn pé, “Bí mo ti wí gan-an ni ọ̀rọ̀ rí, amí ni yín. 15Ohun tí n óo fi mọ̀ pé olóòótọ́ ni yín nìyí: mo fi orúkọ Farao búra, ẹ kò ní jáde níhìn-ín àfi bí ẹ bá mú àbíkẹ́yìn baba yín wá. 16Ẹ rán ọ̀kan ninu yín kí ó lọ mú àbíkẹ́yìn yín wá, ẹ̀yin yòókù ẹ óo wà ninu ẹ̀wọ̀n títí a óo fi mọ̀ bóyá òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo tún fi orúkọ Farao búra, amí ni yín.” 17Ó bá da gbogbo wọn sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọjọ́ mẹta.
18Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Mo bẹ̀rù Ọlọrun, nítorí náà, bí ẹ bá ṣe ohun tí n óo sọ fun yín yìí, n óo dá ẹ̀mí yín sí. 19Tí ó bá jẹ́ pé olóòótọ́ eniyan ni yín, kí ọ̀kan ninu yín wà ninu ẹ̀wọ̀n, kí ẹ̀yin yòókù ru ọkà lọ sí ilé fún ìdílé yín tí ebi ń pa, 20kí ẹ wá mú àbíkẹ́yìn yín tí ẹ̀ ń wí wá, kí n rí i, kí á lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, ẹ óo sì wà láàyè.”
Wọ́n bá gbà bẹ́ẹ̀. 21Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ pé, “Dájúdájú, a jẹ̀bi arakunrin wa, nítorí pé a rí ìdààmú ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá, ṣugbọn a kò dá a lóhùn, ohun tí ó fà á nìyí tí ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
22Reubẹni bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Mo sọ fun yín àbí n kò sọ, pé kí ẹ má fi ohunkohun ṣe ọmọ náà? Ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́, òun nìyí nisinsinyii, ẹ̀san ni ó dé yìí.”#Jẹn 37:21-22. 23Wọn kò mọ̀ pé Josẹfu gbọ́ gbogbo ohun tí wọn ń wí, nítorí pé ògbufọ̀ ni wọ́n fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. 24Josẹfu bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ sọkún, ó tún pada wá láti bá wọn sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni láàrin wọn, ó dè é lókùn.
Àwọn Arakunrin Josẹfu Pada sí Kenaani
25Josẹfu pàṣẹ pé kí wọ́n di ọkà sinu àpò olukuluku wọn, kí ó kún, kí wọ́n dá owó olukuluku pada sinu àpò rẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo jẹ lójú ọ̀nà. Wọ́n ṣe fún wọn bí Josẹfu ti wí. 26Wọ́n di ẹrù wọn ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì gbọ̀nà ilé. 27Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn yóo sùn lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀kan ninu wọn tú àpò rẹ̀ láti fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ, ó bá rí owó rẹ̀ tí wọ́n dì sí ẹnu àpò rẹ̀. 28Ó wí fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Wọ́n dá owó mi pada, òun nìyí lẹ́nu àpò mi yìí.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ń wo ara wọn lójú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n, wọ́n ní, “Irú kí ni Ọlọrun ṣe sí wa yìí?”
29Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n kó gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n rò fún un, wọ́n ní, 30“Ọkunrin tíí ṣe alákòóso ilẹ̀ náà sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó ṣebí a wá ṣe amí ilẹ̀ náà ni. 31Ṣugbọn a wí fún un pé, ‘Olóòótọ́ ni wá, a kì í ṣe eniyankeniyan, ati pé a kì í ṣe amí rárá. 32Ọkunrin mejila ni àwa tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ninu wa ti kú, èyí tí ó kéré jù sì wà lọ́dọ̀ baba wa ní ilẹ̀ Kenaani.’ 33Ọkunrin náà bá dáhùn pé, ohun tí yóo jẹ́ kí òun mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni wá ni pé kí á fi ọ̀kan ninu wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ òun, kí á gbé ọkà lọ sílé, kí ebi má baà pa ìdílé wa. 34Kí á mú àbúrò wa patapata wá fún òun, nígbà náà ni òun yóo tó mọ̀ pé a kì í ṣe amí, ati pé olóòótọ́ eniyan ni wá, òun óo sì dá arakunrin wa pada fún wa, a óo sì ní anfaani láti máa ṣòwò ní ilẹ̀ Kenaani.”
35Bí wọ́n ti tú àpò wọn, olukuluku bá owó rẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀. Nígbà tí àwọn ati baba wọn rí èyí, àyà wọn já. 36Jakọbu baba wọn bá sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ ti jẹ́ kí n ṣòfò àwọn ọmọ mi: Josẹfu ti kú, Simeoni kò sí mọ́, ẹ tún fẹ́ mú Bẹnjamini lọ. Èmi nìkan ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí tán!”
37Reubẹni bá wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi mejeeji, bí n kò bá mú Bẹnjamini pada wá fún ọ. Fi lé mi lọ́wọ́, n óo sì mú un pada wá fún ọ.”
38Ṣugbọn Jakọbu dáhùn, ó ní, “Ọmọ tèmi kò ní bá yín lọ, nítorí pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó kù. Bí ohunkohun bá ṣẹlẹ̀ sí i ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, mo ti darúgbó, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo rán mi sọ́run.”

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Learn More About Yoruba Bible