YouVersion Logo
Search Icon

JẸNẸSISI 31

31
Jakọbu Sá kúrò lọ́dọ̀ Labani
1Jakọbu gbọ́ pé àwọn ọmọ Labani ń sọ pé òun ti gba gbogbo ohun tíí ṣe ti baba wọn, ninu ohun ìní baba wọn ni òun sì ti kó gbogbo ọrọ̀ òun jọ. 2Jakọbu pàápàá kíyèsí i pé Labani kò fi ojurere wo òun mọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá. 3Nígbà náà ni OLUWA sọ fún Jakọbu pé, “Pada lọ sí ilẹ̀ baba rẹ ati ti àwọn ìbátan rẹ, n óo sì wà pẹlu rẹ.”
4Jakọbu bá ranṣẹ pe Rakẹli ati Lea sinu pápá níbi tí agbo ẹran rẹ̀ wà. 5Ó wí fún wọn pé, “Mo ṣàkíyèsí pé baba yín kò fi ojurere wò mí bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ́, ṣugbọn Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi. 6Ẹ̀yin náà mọ̀ pé gbogbo agbára mi ni mo ti fi sin baba yín, 7sibẹ, baba yín rẹ́ mi jẹ, ó sì yí owó ọ̀yà mi pada nígbà mẹ́wàá, ṣugbọn Ọlọrun kò gbà fún un láti pa mí lára. 8Bí ó bá wí pé àwọn ẹran tí ó ní funfun tóótòòtóó ni yóo jẹ́ owó ọ̀yà mi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí onífunfun tóótòòtóó. Bí ó bá sì wí pé, àwọn ẹran tí ó bá ní àwọ̀ tí ó dàbí adíkálà ni yóo jẹ́ tèmi, gbogbo ẹran inú agbo a sì bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà. 9Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gba gbogbo ẹran baba yín tí ó sì fi wọ́n fún mi.
10“Ní àkókò tí àwọn ẹran náà ń gùn, mo rí i lójú àlá pé àwọn òbúkọ tí wọn ń gun àwọn ẹran jẹ́ àwọn tí àwọ̀ wọn dàbí ti adíkálà ati àwọn onífunfun tóótòòtóó ati àwọn abilà. 11Angẹli Ọlọrun bá sọ fún mi ní ojú àlá náà, ó ní, ‘Jakọbu.’ Mo dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ 12Angẹli Ọlọrun bá sọ pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò ó pé gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran inú agbo jẹ́ aláwọ̀ adíkálà ati onífunfun tóótòòtóó ati abilà, nítorí mo ti rí gbogbo ohun tí Labani ń ṣe sí ọ. 13Èmi ni Ọlọrun Bẹtẹli, níbi tí o ti ta òróró sórí òkúta tí o sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún mi. Dìde nisinsinyii, kí o jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, kí o sì pada sí ilẹ̀ tí wọ́n gbé bí ọ.’ ”#Jẹn 28:18-22
14Ni Rakẹli ati Lea bá dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ogún kan tilẹ̀ tún kù fún wa ní ilé baba wa mọ́? 15Ǹjẹ́ kò ti kà wá kún àjèjì? Nítorí pé ó ti tà wá, ó sì ti ná owó tí ó gbà lórí wa tán. 16Ti àwa ati àwọn ọmọ wa ni ohun ìní gbogbo tí Ọlọrun gbà lọ́wọ́ baba wa jẹ́, nítorí náà, gbogbo ohun tí Ọlọrun bá sọ fún ọ láti ṣe, ṣe é.”
17Jakọbu bá dìde, ó gbé àwọn ọmọ ati àwọn aya rẹ̀ gun ràkúnmí. 18Ó bẹ̀rẹ̀ sí da gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí ó ti kó jọ ní Padani-aramu siwaju, ó ń pada lọ sọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ní ilẹ̀ Kenaani. 19Ní àkókò yìí, Labani wà níbi tí ó ti ń gé irun àwọn aguntan rẹ̀, Rakẹli bá jí àwọn ère oriṣa ilé baba rẹ̀ kó. 20Ọgbọ́n ni Jakọbu lò fún Labani ará Aramea, nítorí pé Jakọbu kò sọ fún un pé òun fẹ́ sálọ. 21Ó dìde, ó kó gbogbo ohun tí ó ní, ó sá gòkè odò Yufurate, ó doríkọ ọ̀nà agbègbè olókè Gileadi.
Labani Lépa Jakọbu
22Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí wọ́n sọ fún Labani pé Jakọbu ti sálọ, 23ó kó àwọn ìbátan rẹ̀, ó sì tọpa rẹ̀ fún ọjọ́ meje, ó bá a ní agbègbè olókè Gileadi. 24Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún Labani ará Aramea lóru lójú àlá, ó ní, “Ṣọ́ra, má bá Jakọbu sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu.” 25Labani lé Jakọbu bá níbi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní orí òkè náà, Labani ati àwọn ìbátan rẹ̀ sì pàgọ́ tiwọn sí agbègbè olókè Gileadi.
26Labani pe Jakọbu, ó ní, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí? O tàn mí jẹ, o sì kó àwọn ọmọbinrin mi sá bí ẹrú tí wọ́n kó lójú ogun. 27Èéṣe tí o fi tàn mí jẹ, tí o yọ́ lọ láìsọ fún mi? Ṣebí ǹ bá fi ayọ̀, ati orin ati ìlù ati hapu sìn ọ́. 28Èéṣe tí o kò fún mi ní anfaani láti fi ẹnu ko àwọn ọmọ mi lẹ́nu kí n fi dágbére fún wọn? Ìwà òmùgọ̀ ni o hù yìí. 29Mo ní agbára láti ṣe ọ́ níbi, ṣugbọn Ọlọrun baba rẹ bá mi sọ̀rọ̀ ní òru àná pé kí n ṣọ́ra, kí n má bá ọ sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu. 30Mo mọ̀ pé ọkàn rẹ fà sí ilé ni o fi sá, ṣugbọn, èéṣe tí o fi jí àwọn ère oriṣa mi kó?”
31Jakọbu bá dá Labani lóhùn, ó ní, “Ẹ̀rù ni ó bà mí, mo rò pé o óo fi ipá gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ mi. 32Ní ti àwọn ère oriṣa rẹ, bí o bá bá a lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀. Níwájú gbogbo ìbátan wa, tọ́ka sí ohunkohun tí ó bá jẹ́ tìrẹ ninu gbogbo ohun tí ó wà lọ́dọ̀ mi, kí o sì mú un.” Jakọbu kò mọ̀ rárá pé Rakẹli ni ó jí àwọn ère oriṣa Labani kó.
33Labani bá wá inú àgọ́ Jakọbu, ati ti Lea ati ti àwọn iranṣẹbinrin mejeeji, ṣugbọn kò rí àwọn ère oriṣa rẹ̀. Bí ó ti jáde ninu àgọ́ Lea ni ó lọ sí ti Rakẹli. 34Rakẹli ni ó kó àwọn ère oriṣa náà, ó dì wọ́n sinu àpò gàárì ràkúnmí, ó sì jókòó lé e mọ́lẹ̀. Labani tú gbogbo inú àgọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò rí wọn. 35Rakẹli wí fún baba rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, má bínú pé n kò dìde lójú kan tí mo jókòó sí, mò ń ṣe nǹkan oṣù mi lọ́wọ́ ni.” Bẹ́ẹ̀ ni Labani ṣe wá àwọn ère oriṣa rẹ̀ títí, ṣugbọn kò rí wọn.
36Inú wá bí Jakọbu, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Labani, ó ní, “Kí ni mo ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ tí o fi ń tọpa mi kíkankíkan bẹ́ẹ̀? 37Nígbà tí o tú gbogbo ẹrù mi palẹ̀, àwọn nǹkan rẹ wo ni o rí níbẹ̀? Kó o kalẹ̀ níwájú àwọn ìbátan mi ati àwọn ìbátan rẹ, kí wọ́n lè dájọ́ láàrin wa. 38Fún ogún ọdún tí mo fi bá ọ gbé, ewúrẹ́ rẹ kan tabi aguntan kan kò sọnù rí, bẹ́ẹ̀ ni n kò jí àgbò rẹ kan pajẹ rí. 39Èyí tí ẹranko burúkú bá pajẹ tí n kò bá gbé òkú rẹ̀ wá fún ọ, èmi ni mò ń fara mọ́ ọn. O máa ń gba ààrọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ mi, ìbáà jẹ́ ní òru ni ó sọnù tabi ní ọ̀sán. 40Bẹ́ẹ̀ ni mò ń wà ninu oòrùn lọ́sàn-án ati ninu òtútù lóru, oorun kò sì sí lójú mi. 41Ó di ogún ọdún tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ, mo fi ọdún mẹrinla sìn ọ́ nítorí àwọn ọmọbinrin rẹ, ati ọdún mẹfa fún agbo ẹran rẹ. Ìgbà mẹ́wàá ni o sì pa owó ọ̀yà mi dà. 42Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun baba mi wà pẹlu mi, àní, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun tí Isaaki ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù, láìsí àní àní, ìwọ ìbá ti lé mi lọ lọ́wọ́ òfo kó tó di àkókò yìí. Ọlọrun rí ìyà mi ati iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó fi kìlọ̀ fún ọ ní alẹ́ àná.”
Labani ati Jakọbu Dá Majẹmu
43Labani bá dá Jakọbu lóhùn, ó ní, “Èmi ni mo ni àwọn ọmọbinrin wọnyi, tèmi sì ni àwọn ọmọ wọnyi pẹlu, èmi náà ni mo ni àwọn agbo ẹran, àní gbogbo ohun tí ò ń wò wọnyi, èmi tí mo ni wọ́n nìyí. Ṣugbọn kí ni mo lè ṣe lónìí sí àwọn ọmọbinrin mi wọnyi ati sí àwọn ọmọ tí wọ́n bí? 44Ó dára, jẹ́ kí èmi pẹlu rẹ dá majẹmu, kí majẹmu náà sì jẹ́ ẹ̀rí láàrin àwa mejeeji.”
45Jakọbu bá gbé òkúta kan, ó fi sọlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n. 46Ó sì sọ fún àwọn ìbátan rẹ̀ kí wọ́n kó òkúta jọ. Wọ́n sì kó òkúta jọ, wọ́n fi ṣe òkítì ńlá kan, gbogbo wọn bá jọ jẹun níbi òkítì náà. 47Labani sọ ibẹ̀ ní Jegari Sahaduta, ṣugbọn Jakọbu pè é ní Galeedi. 48Labani wí pé, “Òkítì yìí ni ohun ẹ̀rí láàrin èmi pẹlu rẹ lónìí.” Nítorí náà ó sọ ọ́ ní Galeedi. 49Ó sì sọ ọ̀wọ̀n náà ní Misipa, nítorí ó wí pé, “Kí OLUWA ṣọ́ wa nígbà tí a bá pínyà lọ́dọ̀ ara wa. 50Bí o bá fi ìyà jẹ àwọn ọmọbinrin mi, tabi o tún fẹ́ obinrin mìíràn kún àwọn ọmọbinrin mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnìkan pẹlu wa, ranti o, Ọlọrun ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa mejeeji.” 51Labani bá sọ fún Jakọbu pé, “Wo òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí, tí mo ti gbé kalẹ̀ láàrin àwa mejeeji. 52Òkítì yìí ati ọ̀wọ̀n yìí sì ni ẹ̀rí pẹlu pé n kò ní kọjá òkítì yìí láti wá gbógun tì ọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ náà kò ní kọjá òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí láti wá gbógun tì mí. 53Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Nahori, àní, Ọlọrun baba wọn ni onídàájọ́ láàrin wa.” Jakọbu náà bá búra ní orúkọ Ọlọrun tí Isaaki baba rẹ̀ ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. 54Jakọbu bá rúbọ lórí òkè náà, ó pe àwọn ìbátan rẹ̀ láti jẹun, wọ́n sì wà lórí òkè náà ní gbogbo òru ọjọ́ náà. 55Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọbinrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu láti dágbére fún wọn, ó súre fún wọn, ó sì pada sílé.

Currently Selected:

JẸNẸSISI 31: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy