ẸKISODU 1
BM

ẸKISODU 1

1
Àwọn Ará Ijipti Fipá Kó Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣiṣẹ́
1Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu wá sí Ijipti nìwọ̀nyí, olukuluku pẹlu ìdílé rẹ̀: 2Reubẹni, Simeoni, Lefi, Juda, 3Isakari, Sebuluni, Bẹnjamini, 4Dani, Nafutali, Gadi ati Aṣeri.#Jẹn 46:8-27 5Gbogbo àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Jakọbu jẹ́ aadọrin, Josẹfu ti wà ní Ijipti ní tirẹ̀. 6Nígbà tí ó yá, Josẹfu kú, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ náà kú ní ọ̀kọ̀ọ̀kan títí tí gbogbo ìran náà fi kú tán. 7Ṣugbọn àwọn arọmọdọmọ Israẹli pọ̀ sí i, wọ́n di alágbára gidigidi, wọ́n sì pọ̀ káàkiri ní ilẹ̀ Ijipti.#A. Apo 7:17
8Nígbà tí ó yá, ọba titun kan tí kò mọ Josẹfu gorí oyè, ní ilẹ̀ Ijipti.#A. Apo 7:18 9Ọba yìí sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ wò bí àwọn ọmọ Israẹli wọnyi ti pọ̀ tó, tí wọ́n sì lágbára jù wá lọ. 10Ẹ jẹ́ kí á fi ọgbọ́n bá wọn lò, nítorí bí wọ́n bá ń pọ̀ lọ báyìí, bí ogun bá bẹ́ sílẹ̀, wọn yóo darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti bá wa jà, wọn yóo sì sá kúrò ní ilẹ̀ yìí.”#A. Apo 7:19 11Nítorí náà, wọ́n yan àwọn akóniṣiṣẹ́ láti ni wọ́n lára pẹlu iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n lò wọ́n láti kọ́ ìlú Pitomi ati Ramesesi tíí ṣe àwọn ìlú ìṣúra fún Farao. 12Ṣugbọn bí wọ́n ti ń da àwọn ọmọ Israẹli láàmú tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí ba àwọn ará Ijipti. 13Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi iṣẹ́ àṣekára ni àwọn ọmọ Israẹli lára, 14wọ́n sì ń fòòró ẹ̀mí wọn pẹlu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ líle. Wọ́n ń po yẹ̀ẹ̀pẹ̀, wọ́n ń mọ bíríkì, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ninu oko. Pẹlu ìnira ni wọ́n sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe.
15Nígbà tí ó yá, ọba Ijipti pe àwọn obinrin Heberu tí wọ́n ń gbẹ̀bí, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣifira ati Pua, ó sọ fún wọn pé, 16“Nígbà tí ẹ bá ń gbẹ̀bí fún àwọn obinrin Israẹli, tí ẹ sì rí i pé ọmọ tí wọ́n fẹ́ bí jẹ́ ọkunrin, ẹ pa á, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹ dá a sí.” 17Ṣugbọn àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun; wọn kò tẹ̀lé àṣẹ tí ọba Ijipti pa fún wọn, pé kí wọn máa pa àwọn ọmọkunrin tí àwọn obinrin Heberu bá ń bí. 18Ọba Ijipti bá pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dá àwọn ọmọkunrin tí àwọn Heberu bí sí?”
19Wọ́n dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obinrin Heberu yàtọ̀ sí àwọn obinrin Ijipti. Wọ́n lágbára, wọn a sì ti máa bímọ kí á tó dé ọ̀dọ̀ wọn.” 20Nítorí náà, Ọlọrun ṣe àwọn agbẹ̀bí náà dáradára; àwọn eniyan Israẹli ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń lágbára sí i. 21Nítorí pé àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọrun, ìdílé tiwọn náà pọ̀ síi. 22Farao bá pàṣẹ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Gbogbo ọmọkunrin tí àwọn Heberu bá bí, ẹ máa gbé wọn sọ sinu odò Naili, ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọmọbinrin wọn sí.”#A. Apo 7:19

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Learn More About Yoruba Bible