YouVersion Logo
Search Icon

SAMUẸLI KINNI 31

31
Ikú Saulu ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀
(1Kron 10:1-12)
1Àwọn ará Filistia bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní orí òkè Giliboa. Ọpọlọpọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli kú, àwọn yòókù sì sá. Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pàápàá sá lójú ogun. 2Ṣugbọn àwọn ará Filistia lé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n pa Jonatani ati Abinadabu ati Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu. 3Ogun náà le fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà ta á ní ọfà, ó sì farapa lọpọlọpọ. 4Ó sọ fún ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o pa mí, kí àwọn aláìkọlà wọnyi má baà pa mí, kí wọ́n sì fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ẹ̀rù ba ọmọkunrin náà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, Saulu fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí, ó sì kú. 5Nígbà tí ọmọkunrin náà rí i pé Saulu kú, òun náà fa idà rẹ̀ yọ, ó ṣubú lé e lórí ó sì kú. 6Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe kú ní ọjọ́ kan náà. 7Nígbà tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli tí wọn ń gbé òdìkejì àfonífojì Jesireeli ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá lójú ogun, ati pé Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú; wọ́n sá kúrò ní ìlú wọn. Àwọn ará Filistia bá lọ tẹ̀dó sibẹ.
8Ní ọjọ́ keji tí àwọn ará Filistia wá láti bọ́ àwọn nǹkan tí ó wà lára àwọn tí wọ́n kú, wọ́n rí òkú Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹta ní òkè Giliboa. 9Wọ́n gé orí Saulu, wọ́n sì bọ́ ihamọra rẹ̀, wọ́n ranṣẹ lọ sí gbogbo ilẹ̀ Filistini, pé kí wọ́n kéde ìròyìn ayọ̀ náà fún gbogbo eniyan ati ní gbogbo ilé oriṣa wọn. 10Wọ́n kó ihamọra Saulu sílé Aṣitarotu, oriṣa wọn, wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ ara odi Beti Ṣani.
11Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ ohun tí àwọn ará Filistia ṣe sí Saulu, 12àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ninu wọ́n lọ sí Beti Ṣani lóru, wọ́n sì gbé òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára odi Beti Ṣani, wá sí Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì sin wọ́n sibẹ. 13Wọ́n sin egungun wọn sí abẹ́ igi tamarisiki, ní Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje.

Currently Selected:

SAMUẸLI KINNI 31: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy