1
Òwe 1:7-8
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́. Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀.
Compare
Explore Òwe 1:7-8
2
Òwe 1:32-33
Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n ìkáwọ́gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run; ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”
Explore Òwe 1:32-33
3
Òwe 1:5
Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà.
Explore Òwe 1:5
4
Òwe 1:10
Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.
Explore Òwe 1:10
5
Òwe 1:1-4
Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́, láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀. Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo, àti ìdájọ́, àti àìṣègbè; láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀, ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe.
Explore Òwe 1:1-4
6
Òwe 1:28-29
“Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi. Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù OLúWA.
Explore Òwe 1:28-29
Home
Bible
Plans
Videos