1
Joṣua 10:13
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn náà sì dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró, títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jaṣari. Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan.
Compare
Explore Joṣua 10:13
2
Joṣua 10:12
Ní ọjọ́ tí OLúWA fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún OLúWA níwájú àwọn ará Israẹli, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Aijaloni.”
Explore Joṣua 10:12
3
Joṣua 10:14
Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣáájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí OLúWA gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú OLúWA jà fún Israẹli!
Explore Joṣua 10:14
4
Joṣua 10:8
OLúWA sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.”
Explore Joṣua 10:8
5
Joṣua 10:25
Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni OLúWA yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”
Explore Joṣua 10:25
Home
Bible
Plans
Videos