1
Isa 9:6
Bibeli Mimọ
YBCV
Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia.
Compare
Explore Isa 9:6
2
Isa 9:2
Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ́ si.
Explore Isa 9:2
3
Isa 9:7
Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.
Explore Isa 9:7
4
Isa 9:5
Nitori gbogbo ihamọra awọn ologun ninu irọkẹ̀kẹ, ati aṣọ ti a yi ninu ẹ̀jẹ, yio jẹ fun ijoná ati igi iná.
Explore Isa 9:5
5
Isa 9:1
ṢUGBỌN iṣuju na kì yio wà nibiti wahalà mbẹ nisisiyi, gẹgẹ bi ìgba iṣãju ti mu itìju wá si ilẹ Sebuloni ati ilẹ Naftali, bẹ̃ni ìgba ikẹhin yio mu ọla wá si ọ̀na okun, niha ẹkùn Jordani, Galili awọn orilẹ-ède.
Explore Isa 9:1
6
Isa 9:3
Iwọ ti mu orilẹ-ède nì bi si i pupọ̀pupọ̀, iwọ si sọ ayọ̀ di pupọ̀ fun u: nwọn nyọ̀ niwaju rẹ gẹgẹ bi ayọ̀ ikore, ati gẹgẹ bi enia iti yọ̀ nigbati nwọn npin ikogun.
Explore Isa 9:3
7
Isa 9:4
Nitori iwọ ṣẹ́ ajàga-irú rẹ̀, ati ọpá ejika rẹ̀, ọgọ aninilara rẹ̀, gẹgẹ bi li ọjọ Midiani.
Explore Isa 9:4