Ọmọ mi, bí o bá gba ọ̀rọ̀ mi,
tí o sì pa òfin mi mọ́,
tí o bá ń tẹ́tí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n,
tí o sì fi ọkàn sí òye,
bí o bá kígbe tí o tọrọ òye tí ó jinlẹ̀,
tí o gbóhùn sókè tí o bèèrè ìmọ̀,
bí o bá wá ọgbọ́n bí ẹni ń wá fadaka,
tí o sì wá a bí ẹni ń wá ìṣúra tí a pamọ́,
nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLUWA yóo yé ọ.
O óo sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.