Kí Ni Ète Mi? Kíkọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Àwọn ẸlòmírànÀpẹrẹ

What Is My Purpose? Learning to Love God and Love Others

Ọjọ́ 7 nínú 7

Ìdájọ́

Àfiyèsí

Ète àti ìpè láti fẹ́ Ọlọ́run àti ẹnìkejì wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òdodo awa tìkaara wa, lọ sí àánú àti iṣẹ́ ìsìn, àti ní ẹ̀yìnọ̀rẹyìn ó kan wíwá ìdájọ́ òdodo nínú àti ní àyíká àwọn àwùjọ wa. Bí o ṣe ń ronú lórí ohun tí èyí túmọ̀ sí fún àjọṣe rẹ pẹ̀lú Krístì, lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí láti inú ìwé Ámósì orí karùn-ún gẹ́gẹ́ bí àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́.

Mí s'ínú: Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ìdájọ́ kí ó ṣàn s'ílẹ̀ bí omi;

Mí s'íta: àti òdodo bí iṣàn omi ńlá.

Tẹ́ ètí s'ílẹ̀

Ìwé Ronald Rolheiser - The Holy Longing: The Search for Christian Spirituality (Ìrètí Mímọ́: Ìwádìí Ẹ̀mí Kristiẹni)

“Àjọ Aláàánú aládàáni a máa ṣe ìtọrẹ fún àwọn aláìrílégbé, àwọn tí ó fi ara pa, àti àwọn òkú, ṣùgbọ́n wọn kò gbìyànjú láti mọ ìdí tí wọ́n fi wà ní ipò náà. Òdodo á gbìyànjú láti ru s'ókè, àti láti ṣe àtúnṣe sí ìdí tí àwọn aláìrílégbé, àwọn tí ó fi ara pa, àti àwọn òkú fi wà.

Múulò

Báwo ni o ṣe rò pé àṣẹ tí ó sọ pé kí a ní ìfẹ́ Ọlọ́run àti ẹnìkejì wa ṣe kan ète ayé wa láti máa ṣiṣẹ́ fún ìdájọ́ òdodo àti òdodo?

Kíni ìdí tí Jésù fi kígbe pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin Farisí,” nítorí tí ẹ̀ ń pá apá kan òfin mọ́ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fi ọ̀ràn tí ó tóbi jù nínú òfin s'ílẹ̀ láìṣe, èyíinì ni ìdájọ́?

Ǹjẹ́ o lè fi ojú inú wo ipa tí o lè kó nínú wíwá àti jíjà fún ìdájọ́ òdodo ti ìgbékalẹ̀ Krístì ní àwùjọ rẹ?

Dáhùn

K'ádìí àkókò yìí n'ílẹ̀ pẹ̀lú àdúrà yìí:

Olúwa Ọlọ́run, jọ̀wọ́ tọ́ mi s'ọ́nà láti fẹ́ràn ẹnìkejì mi nípa.ṣíṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo. Ṣí ojú mi àti etí mi sí àwọn tí à ń ni l'ára àti àwọn tí a pa tì. Tú ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi s'ílẹ̀ láti sìn wọ́n àti láti ní ìfẹ́ wọn.


Kí ìdájọ́ Rẹ kí ó ṣàn s'ílẹ̀ bí omi, àti òdodo Rẹ bí iṣàn omi ńlá ti ayèrayè. Àmín.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

What Is My Purpose? Learning to Love God and Love Others

Ye ète rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù: láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Lórí awọn ọjọ méje, a yoo tu awọn àkórí ti ìjọsìn ti ara ẹni, ìyípadà, aanu, iṣẹ, ati ìdájọ. Ìpàdé kọ̀ọ̀kan máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà kan láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ni ìfòjúsùn sórí ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ náà, àyọkà kan tàbí méjì láti inú ìwé mímọ́, èrò kan láti inú ojú ìwòye ẹ̀kọ́ ìsìn, àti àwọn ọ̀nà láti fi sílò kí o sì dáhùn padà sí kíkà náà.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ TENx10 fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.tenx10.org/